orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Jòṣíàyà Sọ Májẹ̀mú Dọ̀tún.

1. Nígbà náà ọba pe gbogbo àwọn àgbààgbà Júdà àti Jérúsálẹ́mù jọ.

2. Ó gòkè lọ sí ilé Olúwa pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Júdà, àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù, àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì—gbogbo àwọn ènìyàn láti ibi kéékèèkéé sí ńlá. Ó kàá sí etí igbọ́ ọ wọn, gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé májẹ̀mú, tí a ti rí nínú ilé Olúwa.

3. Ọba sì dúró lẹ́bà òpó, ó sì sọ májẹ̀mú di titun níwájú Olúwa láti tẹ̀lé Olúwa àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, ìlànà àti òfin pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ àti gbogbo ẹ̀mí rẹ̀, àti láti ṣe ìwádìí àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí a kọ sínú ìwé yìí. Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn sì ṣèlérí fúnra wọn sí májẹ̀mú náà.

4. Ọba sì pàṣẹ fún Hílíkíáyà olórí àlùfáà àti àwọn, àlùfáà tí ó tẹ̀lée ní ipò àti àwọn olùsọ́nà láti yọ kúrò nínú ilé Olúwa gbogbo ohun èlò tí a ṣe fún Báálì àti Áṣérà àti gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run. Ó sì sun wọ́n ní ìta Jérúsálẹ́mù ní pápá pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì. Ó sì kó eérú wọn jọ sí Bétélì.

5. Ó sì kúrò pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà tí a yàn láti ọwọ́ ọba Júdà láti ṣun tùràrí ní ibi gíga ti ìlú Júdà àti àwọn tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká. Àwọn tí ó ń sun tùràrí sí Báálì, sí oòrùn àti òṣùpá, sí àwọn àmì ìràwọ̀ àti sí gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run.

6. Ó mú ère òrìṣà láti ilé Olúwa sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì ní ìta Jérúsálẹ́mù, ó sì ṣun wọ́n níbẹ̀. Ó lọ̀ ọ́ bí atíkè ó sì fọ́n ekuru náà sórí iṣà òkú àwọn ènìyàn tí ó wọ́pọ̀.

7. Ó sì wó ibùgbé àwọn tí ń ṣe panṣágà lọ́kùnrin o tí ojúbọ wọn lulẹ̀. Tí ó wà nínú ilé Olúwa àti ibi tí àwọn obìnrin tí ń ṣe iṣẹ́ aṣọ híhun fún Áṣérà (òriṣà).

8. Jòṣíáyà kó gbogbo àwọn àlùfáà láti àwọn ìlú Júdà ó sì ba ibi mímọ́ wọ̀n-ọn-nì jẹ́ láti Gébà sí Béríṣébà, níbi tí àwọn àlùfáà ti ṣun tùràrí. Ó wó àwọn ojúbọ lulẹ̀ ní ẹnu ìlẹ̀kùn—ní ẹnu ọ̀nà à bá wọlé ti Jóṣúà, baálẹ̀ ìlú ńlá tí ó wà ní apá òsì ẹnu ìlẹ̀kùn ìlú ńlá.

9. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, àwọn àlùfáà ibi gíga kò jọ́sìn ní ibi pẹpẹ Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, wọ́n jẹ nínú àkàrà aláìwú pẹ̀lú àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn.

10. Ó sì ba ohun mímọ́ Tófẹ́tì jẹ́, tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Beni-Hínómì, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkan tí ó lè lò ó fún ẹbọ rírú fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin nínú iná sí Mólékì.

11. Ó sì kúrò láti ẹnu ọ̀nà àbáwọlé sí ilé Olúwa, àwọn ẹṣin tí àwọn ọba Júdà ti yà sọ́tọ̀ sí oòrùn náà. Wọ́n wà nínú ilé ẹjọ́ lẹ́bàá yàrá oníṣẹ́ tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Nátanì-Mélékì. Jòṣíáyà sì ṣun àwọn kẹ̀kẹ́ tí a yà sọ́tọ̀ fún oòrùn.

12. Ó wó o palẹ̀ pẹpẹ tí àwọn ọba Júdà ti wọ́n gbé dúró ní ori òrùlé lẹ́bá yàrá òkè ti Áhásì pẹ̀lú àwọn pẹpẹ tí Mánásè ti kọ́ nínú ilé ẹjọ́ méjèèjì sí ilé Olúwa. Ó sí wọn kúrò níbẹ̀, ó fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́. Ó sì da ekuru wọn sínú pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì.

13. Ọba pẹ̀lú ba ohun mímọ́ àwọn ibi gíga jẹ́ tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Jérúsálẹ́mù ní ìhà gúṣù ti òkè ìbàjẹ́—èyí tí Ṣólómónì ọba Ísírẹ́lì ti kọ́ fún Ásítórétì ọlọ́run ìríra àwọn ará Ṣídónì, fún Kémóṣì ọlọ́run ìríra àwọn ará Móábù àti fún Mólékì, ọlọ́run ìríra àwọn ènìyàn Ámónì.

14. Jòṣíàh fọ́ òkúta yíyà sọ́tọ̀, ó sì gé òpó Áṣérà lulẹ̀. Ó sì bo ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ ẹ rẹ̀ pẹ̀lú egungun ènìyàn.

15. Àní pẹpẹ tí ó wà ní Bétélì ibi gíga tí Jéróbóámù ọmọ Nébátí dá. Tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti ṣẹ̀—Àní pẹpẹ náà àti ibi gíga tí ó fọ́ túútúú. Ó jó àwọn ibi gíga, ó sì lọ̀ ọ́ sí ẹ̀tù, ó sì ṣun òpó Áṣérà pẹ̀lú.

16. Nígbà náà, Jòṣíà wò yíká, nígbà tí ó sì rí àwọn iṣà òkú tí ó wà níbẹ̀ ní ẹ̀bá òkè, ó yọ egungun kúrò lára wọn, ó sì jó wọn lórí pẹpẹ láti sọ ọ́ di èérí ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa tí a ti kéde láti ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀.

17. Ọba sì béèrè, pé “Kí ni ọwọ́n iṣà òkú yẹn tí mo rí?”Àwọn ọkùnrin ìlú ńlá wí pé, “Ó sàmì sí iṣà òkú ènìyàn Ọlọ́run tí ó wá láti Júdà, tí ó sì kéde ìdojúkọ pẹpẹ Bétélì, ohun kan wọ̀nyí tí ìwọ ti ṣe sí wọn.”

18. “Fi sílẹ̀ nìkan,” Ó wí pé. “Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ó da àwọn egungun rẹ̀ láàmú.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dá egungun rẹ̀ sí àti ti àwọn wòlíì tí ó wá láti Ṣamáríà.

19. Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Bétélì, Jòṣíàh sì kúrò, ó sì ba gbogbo ojúbọ òrìṣà ti ibi gíga jẹ́, tí àwọn ọba Ísírẹ́lì ti kọ́ sí àwọn ìlú ní Ṣamáríà, tí ó ti mú Olúwa bínú.

20. Jòṣíáyà dúńbú gbogbo àwọn àlùfáà ibi gíga lórí pẹpẹ. Ó sì ṣun egungun ènìyàn lórí wọn. Nígbà náà, ó padà lọ sí Jérúsálẹ́mù.

21. Ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé: “Ẹ ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá sí Olúwa Ọlọ́run yín, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sí inú ìwé májẹ̀mú yìí.”

22. Kì í ṣe láti ọjọ́ àwọn Júdà tí ó tọ́ Ísírẹ́lì, ní gbogbo àwọn ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì àti àwọn ọba Júdà. Ṣé wọ́n ti ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá rí.

23. Ṣùgbọ́n ní ọdún kejìdínlógún tí ọba Jòṣíà, àjọ ìrékọjá yìí ni a ṣe ìrántí sí Olúwa ní Jérúsálẹ́mù.

24. Síwájú sí, Jòsíáyà sì lé àwọn oṣó àti àwọn ẹ̀mí ní àwọn ìdílé, àti àwọn òrìṣà àti gbogbo àwọn nǹkan ìríra tí a rí ní Júdà àti ní Jérúsálẹ́mù. Èyí ni ó ṣe kí ó le è mú ọ̀rọ̀ òfin náà ṣe ní ti òfin tí a kọ sínú ìwé tí Hílíkíyà àlùfáà ti rí nínú ilé Olúwa.

25. Kò sì sí ọba kankan níwájú tàbí lẹ́yìn Jóṣíáyà tí ó dàbí rẹ̀, tí ó yí padà sí olúwa tinútinú àti gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe tọkàntọkàn pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí i rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin Móṣè.

26. Bí ó ti wù kí ó rí Olúwa kò yípadà kúrò nínú ìmúná ìbínú ńlá rẹ̀ tí ó jó sí Júdà, nítorí gbogbo èyí tí Mánásè ti ṣe láti mú un bínú.

27. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí pé, “Èmi yóò mú Júdà kúrò pẹ̀lú níwájú mi, bí mo ti mú Ísírẹ́lì, èmi yóò sì kó Jérúsálẹ́mù, ìlú ńlá tí mo yàn àti ilé Olúwa yìí, nípa èyí tí mo sọ, ‘Níbẹ̀ ni orúkọ mi yóò wà?’ ”

28. Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jòṣíà, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Júdà?

29. Nígbà tí Jòṣíà jẹ́ ọba, Fáráò Nékò ọba Éjíbítì gòkè lọ sí odò Yúfúrátè láti lọ ran ọba Ásíríà lọ́wọ́. Ọba Jòṣíáyà jáde lọ láti lọ bá a pàdé lójú ogun ṣùgbọ́n Nékò dojúkọ ọ́, ó sì pa á ní Mégídò.

30. Ìránṣẹ́ Jòṣíáyà gbé ara rẹ̀ wá nínú kẹ̀kẹ́ láti Mègídò sí Jérúsálẹ́mù ó sì sin ín sínú iṣà òkú rẹ̀. Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú Jéhóáhásì ọmọ Jòṣíáyà. Ó fi àmì òróró yàn án, ó sì ṣe é ní ọba ní ipò bàbá a rẹ̀.

Jehóáhásì Ọba Júdà.

31. Jéhóáhásì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́talélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Hámútalì ọmọbìnrin Jeremíáyà; ó wá láti Líbínánì.

32. Ó ṣe búburú lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ ti ṣe.

33. Fáráò Nékó sì fi sí inú ìdè ní Ríbílà ní ilẹ̀ Hámátì, kí ó má ba à lè jọba ní Jérúsálẹ́mù. Ó sì tan Júdà jẹ fun iye ìwọ̀n ẹgbẹ̀rin talẹ́ntì wúrà kan.

34. Fáráò Nékò ṣe Élíákímù ọmọ Jòṣíàh ní ọba ní ipò baba rẹ̀ Jòsáyà. Ó sì yí orúkọ Élíákímù padà sí Jéhóíákímù. Ṣùgbọ́n ó mú Jéhóáhásì, ó sì gbéé lọ sí Éjíbítì, níbẹ̀ ni ó sì kú.

35. Jéhóíákímù sì san fún Fáráò Nékónì fàdákà àti wúrà tí ó béèrè. Lati ṣe bẹ́ẹ̀, ó bu owó òde fún ilẹ̀ náà láti san, ó fi agbára gba fàdákà àti wúrà láti ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà ní ìbámu pẹ̀lú iye tí a pín.

Jéhóíákímù Ọba Júdà.

36. Jéhóíákímù jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kànlá orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣébídà ọmọbìnrin Pédáíáyà ó wá láti Rúmà.

37. Ó sì ṣe búburú lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ ti ṣe.