orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

A Rí Ìwé Òfin

1. Jòsáyà jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jédídà ọmọbìnrin Ádáyà; ó wá láti Bósíkátì.

2. Ó sì ṣe èyí tí ó dára lójú Olúwa, ó sì rìn ní ọ̀nà Dáfídì bàbá a rẹ̀, kò sì yípadà sí apá ọ̀tún tàbí sí apá òsì.

3. Ní ọdún kejìdínlógún tí ó fi jọba. Ọba Jòsáyà rán akọ̀wé, Ṣáfánì ọmọ Ásálíà, ọmọ Mésúlámù, sí ilé Olúwa. Ó wí pé;

4. “Gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Hílíkíyà olórí àlùfáà, kí o sì jẹ́ kí ó sírò iye owó tí a mú wá sí ilé Olúwa, tí àwọn olùṣọ́nà ti gbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn.

5. Ẹ sì jẹ́ kí wọn ó fi lé àwọn ọkùnrin tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé Olúwa. Kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn ọkùnrin san án fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń tún ilé Olúwa ṣe.

6. Àwọn gbẹ́nà-gbẹ́nà, àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn akọ́lé. Bákan náà ni wọ́n ra igi àti òkúta ọlọ́ṣọ̀ọ́ láti fi tún tẹ́ḿpìlì ṣe.

7. Ṣùgbọ́n wọn kò ní láti ṣe ìṣirò fún owó náà tí a fi fún wọn, nítorí wọ́n ṣe òtítọ́.”

8. Hílíkíyà olórí àlùfáà sọ fún Ṣáfánì akọ̀wé pé, “Èmi rí ìwé òfin nílé Olúwa.” Ó fi fún Ṣáfánì, ẹni tí ó kà á.

9. Nígbà náà, Ṣáfánì akọ̀wé lọ sí ọ̀dọ̀ ọba. Ó sì sọ fún un pé: “Àwọn ìjòyè rẹ ti san owó náà tí ó wà nínú ilé Olúwa. Èmi sì ti fi lé ọwọ́ àwọn tí ó ń ṣe iṣẹ́ náà àti àwọn alábojútó nílé Olúwa.”

10. Nígbà náà Ṣáfánì akọ̀wé sọ fún ọba pé, “Hílíkíyà àlùfáà ti fún un ní ìwé kan.” Ṣáfánì kà lára rẹ̀ níwájú ọba.

11. Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé òfin, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya.

12. Ó pa àsẹ yìí fún Áhíkámù àlùfáà, Hílíkíyà ọmọ Ṣáfánì, Ákíbórì ọmọ Míkáyà, àti Ṣáfánì akọ̀wé àti Aṣahíáyà ìránṣẹ́ ọba.

13. “Lọ, ẹ béèrè lọ́wọ́ Olúwa fún mi àti fún àwọn ènìyàn àti fún gbogbo Júdà nípa ohun tí a kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Gíga ni ìbínú Olúwa tí ó ń jó sí wa nítorí àwọn baba wa kò tẹ̀lé ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí; wọn kò ṣe ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ níbẹ̀ nípa wa.”

14. Hílíkíyà àlùfáà, Áhíkámù àti Ákíbórì pẹ̀lú Ṣáfánì, lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì obìnrin Húlídà láti lọ bá a sọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ aya Ṣálúmù ọmọ Tíkífà ọmọ Háríhásì alábojútó ibi ìpa aṣọ mọ́ sí. Ó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù ní ìdà kejì.

15. Ó wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Sọ fún ọkùnrin tí ó rán an yín sími,

16. ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò mú ibi wá sí ibí àti àwọn ènìyàn rẹ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé tí ọba Júdà ti kà.

17. Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì tún ṣun tùràrí fún ọlọ́run mìíràn. Wọ́n sì mú mi bínú nípa gbogbo àwọn òrìṣà tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn dá. Ìbínú mi yóò ru sí ibí yìí, kì yóò sì rọlẹ̀’

18. Sọ fún ọba Júdà tí ó rán yín láti bèrè lọ́wọ́ Olúwa, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí nípa ọ̀rọ̀ wọ̀n-ọn-nì tí ìwọ ti gbọ́.

19. Nítorí tí ọkàn rẹ rọ̀, tí ìwọ sì ti rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Olúwa, nígbà tí ìwọ gbọ́ èyí tí mo sọ sí ibí yìí àti sí àwọn ènìyàn rẹ pé wọn yóò di ahoro àti ẹni ègún tí ìwọ sì fa aṣọ ọ̀ rẹ ya pẹ̀lú níwájú mi. Èmi ti gbọ́ tìrẹ, ni Olúwa wí.

20. Nítorí náà èmi yóò kó ọ jọ sí ọ̀dọ̀ àwọn baba à rẹ, a ó sì sin ọ́ ní àlàáfíà. Ojú rẹ kì yóò rí gbogbo àwọn ibi tí èmi yóò mú wá bá ibí yìí.’ ”Bẹ́ẹ̀ wọ́n mú èsì rẹ̀ padà tọ ọba wá.