orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Hóséà Ọba Tí Ó Gbẹ̀yìn Ní Ísírẹ́lì.

1. Ní ọdún kejìlá ọba Áhásì ará Júdà, Hóséà ọmọ Élà jẹ ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà, ó sì jẹ fún ọdún mẹsàn án.

2. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i ti ọba Ísírẹ́lì ẹni tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀.

3. Ṣálámánesérì ọba Áṣíríà wá sókè láti mú Hóséà, ẹni tí ó ti jẹ fún Ṣálámánésérì ó sì ti san owó òde fún un.

4. Ṣùgbọ́n ọba Ásíríà ríi wí pé Hóséà jẹ́ ọlọ́tẹ̀, nítorí ó ti rán ońsẹ́ sọ́dọ̀ ọba Éjíbítì, kò sì san owó òde mọ́ fún ọba Áṣíríà, gẹ́gẹ́ bí o ti máa ń ṣe ní ọdọdún. Nígbà náà ọba Áṣírìa fi agbára mú-ún, ó sì fi sínú túbú.

5. Ọba Ásíríà gòkè wá sí gbogbo ibi ilé náà, ó sì lọ sí Samáríà, ó sì dúró tìí fún ọdún mẹ́ta.

6. Ní ọdún kẹsàn-án ti Hóṣéà, ọba Áṣíríà mú Ṣamáríà ó sì kó Ísírẹ́lì lọ sí Áṣíríà. Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ní Hálà, ní Gósánì ní ọ̀dọ̀ Hábónì àti ní ìlú àwọn ará Médáì.

Ísírẹ́lì Sá Kúrò Ní Ìlú Nítorí Ẹ̀ṣẹ̀

7. Gbogbo eléyìí ṣẹlẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti dẹ́sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde ní Éjíbítì lábẹ́ agbára Fáráò ọba Éjíbítì. Wọ́n sin ọlọ́run mìíràn

8. Wọn si tẹ̀lé ìwà orílẹ èdè tí Olúwa ti gbá kúrò níwájú wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà ti ọba Ísírẹ́lì tí ó ti paláṣẹ

9. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun ìríra sí Olúwa Ọlọ́run wọn kọ́ láti ilé ìsọ́ sí ìlú tí a dábòbò, wọ́n kọ́ ilé gíga fún ara wọn ní gbogbo ìlú wọn.

10. Wọ́n sì gbé àwọn òkúta tí a yà sọ́tọ sókè àti ère òrìṣà lórí gbogbo igi túútúú

11. Ní gbogbo ibi gíga, wọ́n ṣun tùràrí gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀èdè tí Olúwa ti lé jáde níwájú wọn. Wọ́n ṣe ohun búrubú tí ó rú ìbínú Olúwa sókè.

12. Wọ́n sìn òrìsà, èyí tí Olúwa ti sọ pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí.”

13. Olúwa kìlọ̀ fún Ísírẹ́lì àti Júdà nípa gbogbo àwọn wòlíì wọn àti aríran: “Ẹ yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú yín. Kí ẹ ṣe òfin mi àti ìlànà mi, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin tí Èmi palaṣẹ fún àwọn baba yín láti tẹ̀lé àti èyí tí mo rán síi yín nípa ìránṣẹ́ àwọn wòlíì mi.”

14. Ṣùgbọ́n wọn kò ní gbọ́, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́rùn lile gẹ́gẹ́ bí i ti baba wọn, ẹni tí kò gbà Olúwa Ọlọ́run wọn gbọ́.

15. Wọ́n kọ̀ ìlànà rẹ̀ àti májẹ̀mú tí ó ti ṣe pẹ̀lú baba wọn àti ìkìlọ̀ tí ó ti fi fún wọn. Wọ́n tẹ̀lé òrìṣà aláìníláárí, àwọn fún rara wọn sì jẹ́ aláìníláárí. Wọ́n tẹ̀lé orílẹ̀ èdè tí ó yí wọn ká bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa ti kìlọ̀ fún wọn pé, “Má ṣe ṣe gẹ́gẹ́ bí wọn tí ń ṣe,” wọ́n sì ṣe ohun tí Olúwa ti kà léèwọ̀ fún wọn láti ṣe.

16. Wọ́n kọ̀ gbogbo òfin Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀ wọ́n sì ṣe òrìṣà méjì fún ara wọn, wọ́n sì gbée sí ọkàn ẹ̀gbọ̀rọ̀ màlúù, àti ère òrìṣà sí ọkàn. Wọ́n sì tẹrí wọn ba sí gbogbo ogun ọ̀run, wọ́n sì sin Báálì.

17. Wọ́n sì fi àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn rúbọ nínú iná. Wọ́n sì n fọ̀ àfọ̀sẹ, wọ́n sì ń ṣe àlùpàyídà wọ́n sì ta ara wọn láti ṣe ohun búburú níwájú Olúwa, wọ́n sì mú-un bínú.

18. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì bínú gídígídí pẹ̀lú Ísírẹ́lì ó sì mú wọn kúrò níwájú rẹ̀. Èyà Júdà nìkan ṣoṣo ni ó kù,

19. Àti pẹ̀lú, Júdà kò pa òfin Olúwa Ọlọ́run wọn mọ́. Wọ́n tẹ̀lé ìhùwàsí àwọn Ísírẹ́lì tí wọ́n ṣe.

20. Nítorí náà Olúwa kọ gbogbo àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì; ó sì jẹ wọ́n níyà. Ó sì fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn olè tí tí tí ó fi ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀.

21. Nígbà tí ó ta Ísírẹ́lì kúrò láti ìdílé Dáfídì, wọ́n sì mú Jéróbámù ọmọ Nébátì jẹ ọba wọn. Jéróbóámù sì mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yípadà kúrò ní tí tẹ̀lé Olúwa, ó sí mú kí wọn dẹ́sẹ̀ ńlá.

22. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì forítìí nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbámù kò sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ wọn

23. Títí tí Olúwa fi mú wọn kúrò níwájú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti paláṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ wòlíì. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì mú wọn kúrò ní ilẹ̀ wọn lọ sí Iṣánṣà ni Ásíríà.

Ṣamáríà tún fìdí kalẹ̀.

24. Ọba Ásíríà mú àwọn ènìyàn láti Bábílónì, Kútà, Áfà, Hámátì àti Ṣéfáfáímù wọ́n sì dúró ní ìlú Ṣamáríà láti rọ́pò àwọn ará Ísírẹ́lì. Wọ́n sì ń gbé ní ìlú náà.

25. Nígbà tí wọ́n gbé bẹ́ ẹ ní àkọ́kọ́, wọn kò sì bẹ̀rù Olúwa, Bẹ́ẹ̀ ni ó rán kìnnìún sí àárin wọn. Wọ́n sì pa nínú wọn.

26. Wọ́n sì sọ fún ọba Ásíríà pé: “Àwọn ènìyàn tí ìwọ lé kúrò tí o sì fi sínú ìlú Ṣamáríà kò mọ ohun tí Olúwa ìlú náà béèrè. Ó sì ti rán kìnnìún sí àárin wọn, tí ó sì ń pa wọ́n run, nítorí ènìyàn wọn kò mọ ohun tí ó béèrè.”

27. Nígbà náà ọba Ásíríà pàṣẹ yìí wí pé, “Mú ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó mú láti Ṣamáríà lọ padà gbé níbẹ̀ kí ó sì kọ́ àwọn ènìyàn ní, ohun tí Olúwa ilẹ̀ náà béèrè.”

28. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó ti kúrò ní Samáríà wá gbé ní Bétélì ó sì kọ́ wọn bí a ti ń sin Olúwa.

29. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, olúkúlùkù orílẹ̀ èdè ṣe òrìṣà tirẹ̀ ní gbogbo ìlú níbi tí wọ́n gbé wà, wọ́n sì gbé wọn nínú ilé òrìṣà àti àwọn ènìyàn Ṣamáríà ó sì ṣe wọ́n sí ibi gíga wọ̀n-ọn-nì.

30. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin láti Bábílónì ṣe àgọ́ àwọn wúndíá, àwọn ọkùnrin láti Kútì ṣe Négálì, àti àwọn ènìyàn láti Hámátì ṣe Áṣímà;

31. Àti àwọn ará Áfà ṣe Nébíhásì àti Tárítakì, àti àwọn ará Ṣéfárífáímù ṣun àwọn ọmọ wọn níná gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí Adiramélékì àti Anamélékì, àwọn òrìṣà Ṣéfárfáímù.

32. Wọ́n sin Olúwa, ṣùgbọ́n wọ́n sì tún yan gbogbo ẹgbẹ́ tí ènìyàn wọn láti ṣe iṣẹ́ oyè fún wọn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà ní ibi gíga.

33. Wọ́n sin Olúwa ṣùgbọ́n wọ́n sin òrìṣà wọn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àṣà orílẹ̀ èdè wọn láti ibi tí wọ́n ti gbé wọn wá.

34. Láti ìgbà náà wá àwọn àlùfáà wọn ṣe bí ti àtẹ̀yìnwá. Wọn kò sin Olúwa tàbí kí wọ́n fi ara mọ́ ìlànà àti àṣẹ àti òfin tí Olúwa fi fún ìránṣẹ́ Jákọ́bù, tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ísírẹ́lì.

35. Nígbà tí Olúwa ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe sin òrìṣà mìíràn tàbí tẹríba fún wọn, sìn wọ́n tàbí kí ẹ rúbọ sí wọn.

36. Ṣùgbọ́n Olúwa, ẹni tí ó mú yín gòkè jáde wá láti ilẹ̀ Éjíbítì pẹ̀lú agbára ńlá àti nínà apá, òun ni ẹni náà tí ó yẹ kí ẹ sìn. Òun ni ẹni tí ó yẹ kí ẹ tẹríba fún àti sí òun ni kí ẹ rúbọ fún.

37. Ó yẹ kí ẹ̀yin kí ó máa kíyèsí ara yín gidigdidi láti pa ìlànà àti àsẹ, àti òfin tí ó kọ fún un yín mọ́. Ẹ má ṣe sin ọlọ́run mìíràn.

38. Ẹ má ṣe gbàgbé májẹ̀mú tí mo ti ṣe pẹ̀lú yín mọ́ àti kí ẹ má sin ọlọ́run mìíràn.

39. Kúkú ṣin Olúwa Ọlọ́run rẹ; Òun ni ẹni náà tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀ta a yín.”

40. Wọn kò ní gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ wọ́n ti àtijọ́.

41. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn wọn sin Olúwa, wọ́n sì ń sin òrìṣà wọn. Títí di ọjọ́ òní ọmọ wọn àti àwọn ọmọ-ọmọ wọn sì ń ṣe bí àwọn baba wọn ti ń ṣe.