orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Jóásì Tún Ilé Tí A Kọ́ Fún Olúwa Ṣe

1. Ní ọdún keje tí Jéhù, Jóásì di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ogójì ọdún. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Síbíyà: Ó wá láti Beeriṣébà.

2. Jóásì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa ní gbogbo ọdún tí Jéhóíádà àlùfáà fi àsẹ fún un.

3. Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí wọn ní ìdí; Àwọn ènìyàn sì tẹ̀ṣíwájú láti máa rú ẹbọ àti sísun tùràrí níbẹ̀.

4. Jóásì sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Gba gbogbo owó tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ mímọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa owó tí a gbà ní ìgbà kíka àwọn ènìyàn ìlú, owó tí a gbà láti ọwọ́ olúkúlùkù bí wọ́n ti ṣe jẹ́ ẹ̀yà àti owó tí ó ti ọkàn olúkúlùkù wá tí a múwá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

5. Jẹ́ kí gbogbo àlùfáà gba owó náà lọ́wọ́ ọ̀kan nínú àwọn akápò. Kí a sì lò ó fún túntún ohunkóhun tí ó bá bàjẹ́ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.”

6. Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹtàlélógún ọba Jóásì, àwọn àlùfáà kò ì tí ì tún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.

7. Nígbà náà, ọba Jóásì pe Jéhóíádà àlùfáà àti àwọn àlùfáà yóòkù, ó sì bi wọ́n, pé “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tún ìbàjẹ́ tí a ṣe sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe? Ẹ má ṣe gba owó mọ́ lọ́wọ́ àwọn afowópamọ́, ṣùgbọ́n ẹ gbé e kalẹ̀ fún túntun ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.”

8. Àwọn àlùfáà faramọ́ pé wọn kò ní gba owó kankan mọ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sì ni, wọn kò sì ní tún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe mọ́ fún ra wọn.

9. Jéhóíádà àlùfáà mú àpótí kan, ó sì lu ihò sí ìdérí rẹ̀. Ó gbé e sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ ní apá ọ̀tún bí ẹnìkan ti wọlé tí a kọ́ fún Olúwa. Àwọn àlùfáà tí ó ṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé fi sínú àpótí náà gbogbo owó tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

10. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá ti rí wí pé owó púpọ̀ wà nínú àpótí, akọ̀wé àti olórí àlùfáà yóò wá, wọ́n á ka owó náà tí wọ́n ti mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Wọn a sì kó o sínú àwọn àpò.

11. Nígbà tí wọ́n bá ti pinnu iye rẹ̀, wọn a kó owó náà fún àwọn tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Pẹ̀lú u rẹ̀, wọ́n sọ fún àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ lórí ilé tí a kọ́ fún Olúwa; Àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà àti àwọn olùkọ́lé.

12. Àwọn ilé ńlá àti àwọn agékúta. Wọ́n ra igi gẹdú àti òkúta tí wọ́n tọ́jú fún titun ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe. Wọ́n tún ohun gbogbo tí wọ́n ná fún títún tẹ́ḿpílì ṣe.

13. Owó tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa kò jẹ́ níná fún ṣíṣe òpó fàdákà, àlùmágàjí fìtílà, àwokòtò, ipè, ohun èlò wúrà tàbí ohun èlò fàdákà kan fún ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

14. A sì san án fún àwọn ọkùnrin tí ó ń ṣiṣẹ́, tí wọ́n ń tọ́jú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

15. Wọn kò sì bá àwọn ọkùnrin náà sírò, ní ọwọ́ ẹni tí wọ́n fún ní owó láti san fún àwọn òṣìṣẹ́. Torí wọ́n ṣe é pẹ̀lú òdodo tí ó pé.

16. Owó láti ibi ọrẹ ẹ̀bi àti ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ ní a kò mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa: ó jẹ́ ti àwọn àlùfáà.

17. Ní déédéé àkókò yìí, Hásáélì ọba Ṣíríà gòkè lọ láti dojúkọ Gátì àti láti fi agbára mú un. Nígbà náà, ó yípadà láti dójukọ Jérúsálẹ́mù.

18. Ṣùgbọ́n Jóásì ọba Júdà mú gbogbo ohun mímọ́ tí a gbé ka iwájú tí a yà sọ́tọ̀ nípasẹ̀ baba rẹ̀—Jéhósáfátì, Jéhórámù àti Áhásáyà, àwọn ọba Júdà, àti àwọn ẹ̀bùn tí òun tìkálára rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ àti gbogbo wúrà, tí ó rí nínú ibi ìfowópamọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa àti níti ààfin ọba, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Hásáélì; ọba Ṣíríà, tí ó sì fa padà kúrò ní Jérúsálẹ́mù.

19. Pẹ̀lú ìyókù ìṣe Jóásì, àti ohun gbogbo tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Júdà?

20. Àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ sí i wọ́n sì lù ú pa ní Bẹti-Mílò ní ọ̀nà sí Ṣílà.

21. Àwọn oníṣẹ́ tí ó pa á jẹ́ Jósábádì ọmọ Ṣíméátì àti Jéhósábádì ọmọ Ṣómérì. Ó kú, wọ́n sì sin-ín pẹ̀lú baba rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dáfídì. Ámásáyà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.