orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Obìnrin Ará Ṣúnámù Gba Ilẹ̀ Rẹ̀ Padà.

1. Nísin yìí, Èlíṣà wí fún obìnrin náà tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin jí pàdà sáyé pé, “jáde lọ pẹ̀lú ìdílé rẹ kí o sì lọ dúró fún ìgbà díẹ̀ ní ibíkíbi tí o bá le dúró sí, nítorí Olúwa ti pàṣẹ ìyàn ní ìlú tí yóò lò tó ọdún méje.”

2. Obìnrin náà tẹ̀ ṣíwájú gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ti sọ. Òun àti ìdílé rẹ̀ sá lọ, wọ́n sì dúró ní ilé àwọn ará Fílístínì fún ọdún méje.

3. Ní ẹ̀yìn ọdún méje ó sì padà wá láti ilẹ̀ àwọn ará Fílístínì ó sì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba láti lọ bẹ̀ẹ́ fún ilé àti ilẹ̀ rẹ̀.

4. Ọba sì ń sọ̀rọ̀ sí Géhásì, ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run pé, “Sọ fún mi nípa gbogbo ohun ńlá tí Èlísà ti ṣe.”

5. Bí Gèhásì ti ń sọ bí tí Èlíṣà ṣe jí òkú di alàyè, obìnrin náà tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tí Èlíṣà ti dá padà sí ayé wá láti bẹ ọba fún ilé àti ilẹ̀ rẹ̀.Gèhásì sì wí pé, “Obìnrin náà nì yí Olúwa mi ọba, ọmọkùnrin rẹ náà nìyí tí Èlísà ti jí dìde sí ayé.”

6. Ọba bèèrè lọ́wọ́ obìnrin náà nípa rẹ̀, ó sì sọ fún un.Ó sì yan ìjòyè kan fún ún fún ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó sì wí fún un pé, “Ẹ fún un padà gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ tirẹ̀, àti pẹ̀lú gbogbo èrè ilé rẹ̀ fún ún láti ọjọ́ tí ó ti kúrò ní ìlú títí di àsìkòyí.”

Hásáélì Pa Bẹni-Hádádì

7. Èlíṣà lọ sí Dámásíkù, Bẹni-Hádádì ọba Ṣíríà ń ṣe àìsàn. Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba pé, “Ènìyàn Ọlọ́run ti wá láti gbogbo ọ̀nà òkè síbí”,

8. ó sì wí fún Hásáélì pé, “Mú ẹ̀bùn kan pẹ̀lú rẹ láti lọ pàdé ènìyàn Ọlọ́run. Kí o sì béèrè Olúwa láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣé èmi yóò sàn nínú àìsàn yìí?”

9. Hásáélì lọ láti pàdé Èlísà, ó mú lọ pẹ̀lú rẹ̀ ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bí ogójì ẹrù ìbákasìẹ tí gbogbo ìní tí ó dára jù fún wíwò ti Dámásíkù, ó sì wọlé lọ ó sì dúró níwájú rẹ̀, ó sì wí pé, “Ọmọ rẹ Bénhádádì ọba Ṣíríà rán mi láti béèrè pé, ‘Ṣé èmi yóò sàn nínú àìsàn mi yìí?’ ”

10. Èlíṣà da á lóhùn pé, “Lọ kí o lọ sọ fún un pé, ‘Ìwo ìbá sàn ní tòótọ́’; ṣùgbọ́n Olúwa ti fi hàn mí pé nítòotọ́ òun yóò kú.”

11. Ó sì ranjú mọ́ ọn pẹ̀lú àtẹjúmọ́ gidigidi títí tí ojú fi ti Hásáélì. Nígbà náà ènìyàn Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún.

12. “Kí ni ó dé tí Olúwa mi fi ń sunkún?” Hásáélì bèèrè.“Nítorí pé èmi mọ ibi tí ìwọ yóò ṣe sí Ísírẹ́lì,” ó sì dáhùn pé, “Ìwọ yóò fi iná si odi agbára wọn, ìwọ yóò, pa àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin wọn pẹ̀lú idà, ìwọ yóò kọlù àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, ìwọ ó sì fọ́ wọn túútúú, ìwọ o sì la inú àwọn aboyún wọn.”

13. Hásáélì sì wí pé. “Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ, ajá lásán làsàn yóò ṣe ṣe irú nǹkan ńlá bẹ́ẹ̀?”“Olúwa ti fi hàn mí pé ìwọ ni yóò jẹ ọba síríà,” Èlíṣà dá a lóhùn.

14. Nígbà náà Hásáélì fi Èlíṣà sílẹ̀ ó sì padà sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. Nígbà tí Bẹnihádádi bèèrè, “Kí ni ohun tí Èlíṣà sọ fún ọ?” Hásáélì dá a lóhùn, “Ó sọ fún mi wí pé ìwọ yóò sàn nítòótọ́.”

15. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì ó mú aṣọ tí ó nípọn, ó sì kì í bọ inú omi ó sì tẹ̀ẹ́ sí ojú ọba, bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú. Nígbá náà Hásáélì sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Jéhórámù Ọba Júdà.

16. Ní ọdún karùn-ún ti Jórámù ọmọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì, nígbà tí Jéhóṣáfátì jẹ́ ọba Júdà, Jéhórámù ọmọ Jéhóṣáfátì bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Júdà.

17. Ó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́jọ.

18. Ó sì rìn ní ọ̀nà ọba Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti lọ, nítorí ó fẹ́ ọmọbìnrin Áhábù ó sì ṣe ohun búburú níwájú Olúwa.

19. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, nítorí ti ìránṣẹ́ rẹ̀ Dáfídì. Olúwa kò fẹ́ pa Júdà run, ó ti ṣèlérí láti ṣètọ́jú ìmọ́lẹ́ fún Dáfídì àti àwọn ilé rẹ̀ títí láéláé.

20. Ní àsìkò Jéhórámù, Édómù ṣọ̀tẹ̀ lórí Júdà, ó sì jẹ́ ọba fúnrararẹ̀.

21. Bẹ́ẹ̀ ni Jéhórámù lọ sí Ṣáírì pẹ̀lú gbogbo kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Àwọn ará Édómù sì yí i ká àti kẹ̀kẹ́ àwọn olórí wọn, ṣùgbọ́n ó dìde dúró ní òru; àwọn ogun rẹ̀ síbẹ̀ síbẹ̀, sá padà lọlé.

22. Títí ó fi di òní, Édómù wà nínú ọ̀tẹ̀ lórí Júdà, Líbinà ṣọ̀tẹ̀ ní àkókò kan náà.

23. Gẹ́gẹ́ bí fún iṣẹ́ mìíràn ti ìjọba Jórámù, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà?

24. Jórámù sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú Dáfídì, Áhásáyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

Áhásáyà Ọba Júdà

25. Ní ọdún méjìlá Jórámù ọmọkùnrin Áhábù ọba Ísírẹ́lì, Áhásáyà ọmọkùnrin Jéhórámù ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀.

26. Áhásáyà jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jọba ní ọdún kan ní Jérúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Átalíàh, ọmọbìnrin Ómírìe ọba Ísírẹ́lì.

27. Nígbà tí ó rin ọ̀nà ilé Áhábù ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti ṣe, nítorí ó tan nípa ìgbéyàwó sí ìdílé Áhábù.

28. Áhásáyà sì lọ pẹ̀lú Jórámù ọmọ Áhábù lọ sí ogun lórí Hásáélì ọba Árámù ní Ramoti-Gílíádì. Àwọn ará Ṣíríà ṣẹ́ Jórámù lẹ́sẹ̀.

29. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Jórámù padà sí Jéṣérẹ́lì láti wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn tí ará Síríà ti jẹ níyà lórí rẹ̀ ní Rámò ní ojú ogun rẹ̀ pẹ̀lú Hásáélì ọba Árámù.Nígbà náà Áhásáyà ọmọ Jéhórámù ọba Júdà sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jésérẹ́lì láti lọ wo Jórámù ọmọ Áhábù nítorí tí ó fi ara pa.