orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Orí Àáké Fò Lójú Omi

1. Àwọn ọmọ wòlíì sọ fún Èlíṣà pé, “Wò ó, ní ibi tí a ti pàdé pẹ̀lú rẹ, ó kéré fún wa.

2. Jẹ́ kí àwa kí ó lọ sí Jọ́dánì, ní ibi tí ẹnìkọ̀ọ̀kan ti le rí ọ̀pá kan, jẹ́ kí àwa kí ó kọ́lé síbẹ̀ fún wa láti gbé.”Ó sì wí pé, “lọ.”

3. Nígbà náà ni ọ̀kan lára wọn wí pé, “Ṣé ìwọ kò ní jọ̀wọ́ wa pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ?”“Èmi yóò lọ,” Èlíṣà dá a lóhùn.

4. Ó sì lọ pẹ̀lú wọn.Wọ́n sì lọ sí Jọ́dánì wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gé igi

5. Bí ọ̀kan ṣe gé igi náà, àáké irin náà bọ́ sínú omi, ó kí gbe sókè pé, o! Olúwa mi, “mo yá a ni”

6. Ènìyàn Ọlọ́run sì béèrè pé, “Níbo ni ó bọ́ sí?” Nígbà tí ó fi ibẹ̀ hàn án, Èlíṣà ge igi kan ó sì jù ú síbẹ́, ó sì mú irin náà fò lójú omi.

7. Ó wí pé, “Gbé e jáde” Nígbà náà ọkùnrin náà na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú un.

8. Nísinsìn yìí ọba Árámù ó wà ní ogun pẹ̀lú Ísírẹ́lì ó sì bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ gbérò, ó wí pé “Èmi yóò ṣe ibùdó mi sí ibí yìí nínú èyí náà àti bí ibí yìí.”

9. Ènìyàn Ọlọ́run rán iṣẹ́ sí ọba Ísírẹ́lì, “kíyèsí ara láti kọjá ní ibẹ̀ yẹn, nítorí pé ará Árámù wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ síbẹ̀.”

10. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì wo ibi tí ènìyàn Ọlọ́run náà fi hàn, ní ẹ̀ẹ̀kan sí i Èlíṣà kìlọ̀ fún ọba, bẹ́ẹ̀ ni ó wà lórí sísọ ní ibẹ̀.

11. Èyí mú ọba Árámù bínú. Ó pe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé ìwọ kò ní sọ fún un èwo nínú wa ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọba Ísírẹ́lì?”

12. “Kò sí ọ̀kan nínú wa, Olúwa ọba mi,” ọ̀kan lára ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí pé, “ṣùgbọ́n Èlíṣà, wòlíì tí ó wà ní Ísírẹ́lì, sọ fún ọba Ísírẹ́lì ọ̀rọ̀ gangan tí ó sọ nínú yàrá rẹ̀.

13. “Lọ, kí ẹ lọ wo ibi tí ó wà,” ọba pa á láṣẹ, “Kí èmi kí ó lè rán ènìyàn láti lọ mú un wá.” Ìròyìn padà wá. “Ó wà ní Dótanì.”

14. Nígbà náà ó rán àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ àti ogun ńlá tí ó le síbẹ̀. Wọ́n sì lọ ní alẹ́ wọ́n sì yí ìlú náà ká.

15. Nígbà tí ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run dìde ó sì jáde lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, ogun pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ wọn ti yí ìlú náà ká. “Yé è, Olúwa mi, kí ni kí àwa kí ó ṣe?” ìránṣẹ́ náà béèrè.

16. “Má ṣe bẹ̀rù,” wòlíì náà dáhùn, “Àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa, wọ́n pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ.”

17. Èlíṣà sì gbàdúrà, “Olúwa, la ojú rẹ̀ kí ó ba à lè ríran.” Nígbà náà Olúwa la ojú ìránṣẹ́ náà, ó sì wò, ó sì rí òkè ńlá tí ó kún fún ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ iná gbogbo yí Èlíṣà ká.

18. Bí àwọn ọ̀tá ṣe ń sọ̀kalẹ̀ wá níwájú rẹ, Èlíṣà gbàdúrà sí Olúwa pé. “Bu ìfọ́jú lu àwọn ènìyàn wọ̀nyí,” Olúwa sì se gẹ́gẹ́ bí Èlíṣà ti béèrè.

19. Èlíṣà sọ fún wọn pé “Èyí kì í ṣe ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ni èyí kì í ṣe ìlú náà. Tẹ̀lé mi, èmi yóò mú u yín lọ sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin tí ẹ̀yin ń wá.” Ó sì sìn wọ́n lọ sí Samáríà.

20. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n wọ ìlú náà, Èlíṣà wí pé, “Olúwa, la ojú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kí wọn kí ó lè ríran.” Nígbà náà Olúwa la ojú wọn, wọ́n sì ríran, wọ́n sì wà níbẹ̀, nínú Samáríà.

21. Nígbà tí ọba Ísírẹ́lì rí wọn, ó béèrè lọ́wọ́ Èlíṣà pé, “Ṣé kí èmi kí ó pa wọ́n, Baba mi? Ṣé kí èmi kí ó pa wọ́n?”

22. “Má se pa wọ́n,” ó dáhùn. “Ṣé ìwọ yóò pa àwọn ọkùnrin tí ìwọ mú pẹ̀lú idà rẹ tàbí ọrun rẹ? Gbé oúnjẹ àti omi ṣíwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ kí wọn sì mu, nígbà náà kí wọn padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn.”

23. Bẹ́ẹ̀ ni ó pèṣè àṣè ńlá fún wọn, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ tí wọ́n mu, ó sì rán wọn lọ, wọ́n sì padà sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ẹgbẹ́ láti Árámù dáwọ́ ìgbógun ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì dúró.

Ìyàn Nínú Ìkámọ́ Samáríà

24. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ni Bẹni-Hádádì ọba Árámù kó gbogbo àwọn ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì yan sókè wọ́n sì dúró ti Samáríà.

25. Ìyàn ńlá sì mú ní ìlú náà; wọ́n dúró tìí tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ní ọgọ́ọ̀rùnún ìwọ̀n fàdákà àti ìdámẹ́rin òṣùwọ̀n kábù imí ẹyẹlé, fún ìwọ̀n fàdákà márùn ún.

26. Gẹ́gẹ́ bí ọba Ísírẹ́lì ti ń kọjá lọ lórí odi, obìnrin kan sunkún sí I pé, “Ràn mí lọ́wọ́, Olúwa ọba mi!”

27. Ọba sì dá a lóhùn pé, “Tí Olúwa kò bá ràn ọ́ lọ́wọ́, níbo ni èmi ti lè rí ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀? Láti inú ilé ìpakà? Láti inú ibi ìfúntí?”

28. Nígbà náà ó béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?”Obìnrin náà dáhùn pé, “Obìnrin yìí wí fún mi pé, ‘Mú ọmọkùnrin rẹ wá kí àwa kí ó lè jẹ ẹ́ lónìí, ní ọ̀la àwa yóò jẹ ọmọkùnrin tèmi.’

29. Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe ọmọkùnrin mi a sì jẹ ẹ́. Ní ọjọ́ kejì mo wí fún un pé, ‘Mú ọmọkùnrin rẹ wá kí àwa kí ó lè jẹ,’ ṣùgbọ́n ó ti gbé e pamọ́.”

30. Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ obìnrin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya. Gẹ́gẹ́ bí ó sì ti ń kọjá lọ sí orí odi, àwọn ènìyàn wò ó níbẹ̀ ní abẹ́, ó ní aṣọ ọ̀fọ̀ ní ara rẹ̀.

31. Ó sì wí pé, “Kí Olúwa kí ó fi ìyà jẹ mí, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ dájúdájú, pé orí ọmọkùnrin Èlíṣà ọmọ Sáfátì kì ó wà ní ọrùn rẹ̀ ní òní!”

32. Nísinsìnyí Èlíṣà jókòó ní ilé rẹ̀ àwọn àgbààgbà náà jókòó pẹ̀lú rẹ̀. Ọba sì rán oníṣẹ́ ṣíwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó tó dé ibẹ̀, Èlíṣà sọ fún àwọn àgbààgbà pé, “Ṣé èyin kò rí bí apànìyàn ti ń rán ẹnìkan láti gé orí mi kúrò? Ẹ wò ó, nígbà tí ìránṣẹ́ náà bá dé, ẹ ti ìlẹ̀kùn kí ẹ sì dì í mú ṣinṣin nítorí rẹ̀, kì í ṣe ìró ẹsẹ̀ ọ̀gá rẹ̀ wà lẹ́yìn rẹ?”

33. Nígbà tí ó sì ń sọ̀rọ̀ sí wọn, ìránṣẹ́ náà sọ̀kalẹ̀ wá bá a. Ọba náà sì wí pé, “Ibi yìí láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni. Kí ni ó dé tí èmi yóò fi dúró de Olúwa sí i?”