orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Èlíjà Gun Kẹ̀kẹ́ Iná Lọ Sí Ọ̀run

1. Nígbà tí Ọlọ́run ń fẹ́ gbé Èlíjà lọ sí òkè ọ̀run nínú àjà, Èlíjà àti Èlíṣà wà ní ọ̀nà láti Gílgálì.

2. Èlíjà wí fún Èlíṣà pé, “Dúró níbí; Olúwa rán mi lọ sí Bétélì.”Ṣùgbọ́n Èlíṣà wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé Olúwa wà láyé àti gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, Èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Bétélì.

3. Àwọn ọmọ wòlíì ní Bétélì jáde wá sí ọ̀dọ̀ Èlíṣà wọ́n sì béèrè pé, “Ṣé ìwọ mọ̀ pé Olúwa yóò gba ọ̀gá rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ lónìí?”“Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi mọ̀,” Èlíṣà dáhùn “Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.”

4. Nígbà náà Èlíjà sì wí fún un pé, “Dúró níbí, Èlíṣà: Olúwa ti rán mi lọ sí Jẹ́ríkò.”Ó sì dá a lóhùn pé, “Bí ó ti dájú pé Olúwa yè àti tí ìwọ náà yè, Èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Wọ́n sì jọ lọ sí Jẹ́ríkò.

5. Àwọn ọmọ wòlíì tí ó wà ní Jẹ́ríkò sì gòkè tọ Èlíṣà wá wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé ìwọ mọ̀ wí pé Olúwa yóò gba ọ̀gá rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ lónìí?”“Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi mọ̀,” Ó dá wọn lóhùn, “Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ nípa rẹ̀.”

6. Nígbà náà Èlíjà wí fún un pé, “Dúró níbí; Olúwa rán mi lọ sí Jọ́dánì.”Ó sì dá a lóhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ wí pé, Olúwa yè àti gẹ́gẹ́ bí o ti yè, èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì sì jọ ń lọ.

7. Àádọ́ta àwọn ọkùnrin ọmọ wòlíì sì lọ láti lọ dúró ní ọ̀nà jínjìn, wọ́n sì kọ ojú da ibi tí Èlíjà àti Èlíṣà ti dúró ní Jọ́dánì.

8. Èlíjà sì mú agbádá ó sì ká a sókè ó sì lu omi náà pẹ̀lú rẹ̀. Omi náà sì pín sí ọ̀tún àti sí òsì, àwọn méjèèjì sì rékọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ̀.

9. Nígbà tí wọ́n rékọjá, Èlíjà sì wí fún Èlíṣà pé, “Sọ fún mi, kí ni èmi lè ṣe fún ọ kí ó tó di wí pé wọ́n gbà mí kúrò lọ́dọ̀ rẹ?”“Jẹ́ kí èmi kí ó jogún ìlọ́po méjì ẹ̀mí rẹ.” Ó dá a lóhùn.

10. “Ìwọ ti béèrè ohun tí ó ṣòro,” Èlíjà wí pé, “Síbẹ̀ tí ìwọ bá rí mi nígbà tí a bá gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ, yóò jẹ́ tìrẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kò ní rí bẹ́ẹ̀.”

11. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń rìn lọ tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ pọ̀, lọ́gán kẹ̀kẹ́ iná àti ẹsin iná yọ sí wọn ó sì ya àwọn méjèèjì nípa, Èlíjà sì gòkè lọ sí ọ̀run pẹ̀lú àjà.

12. Èlíṣà rí èyí ó sì kígbe sókè, “Baba mi! Baba mi! Kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin Ísírẹ́lì!” Èlíṣà kò sì rí i mọ́. Ó sì mú aṣọ ara rẹ̀ ó sì fà wọ́n ya sọ́tọ̀.

13. Ó sì mú agbádá tí ó ti jábọ́ láti ọ̀dọ̀ Èlíjà ó sì padà lọ, ó sì dúró lórí bèbè Jọ́dánì.

14. Ó sì mú agbádá náà tí ó jábọ́ láti ọwọ́ rẹ̀, ó sì lu omi pẹ̀lú rẹ̀. “Níbo ni Olúwa Ọlọ́run Èlíjà wà?” Ó bèèrè. Nígbà tí ó lu omi náà, ó sì pín sí apá ọ̀tún àti sí òsì, ó sì rékọjá.

15. Àwọn ọmọ wòlíì láti Jẹ́ríkò, tí wọ́n ń wò, wí pé, “Ẹ̀mí Èlíjà simi lé Èlíṣà.” Wọ́n sì lọ láti lọ bá a, wọ́n sì dojú bolẹ̀ níwájú rẹ̀.

16. “Wò ó,” wọ́n wí pé, “Àwa ìránṣẹ́ ni àádọ́ta ọkùnrin alágbára. Jẹ́ kí wọ́n lọ láti lọ wá ọ̀gá rẹ wá. Bóyá ẹ̀mí Olúwa ti gbé e sókè, ó sì gbé e kalẹ̀ lórí òkè ńlá tàbí lórí ilẹ̀.”“Rárá,” Èlíṣà dá a lóhùn pé, “Má ṣe rán wọn.”

17. Ṣùgbọ́n wọ́n forítì í títí ojú fi tì í láti gbà. Ó wí pé, “Rán wọn.” Wọ́n sì rán àádọ́ta ènìyàn tí ó wá a fún ọjọ́ mẹ́ta ṣùgbọ́n wọn kò ríi.

18. Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Èlíṣà, tí ó dúró ní Jẹ́ríkò, ó wí fún wọn pé, “Ṣé èmi kò sọ fún un yín kí ẹ má lọ?”

Ìwòsàn Omi

19. Àwọn ọkùnrin ìlú wí fún Èlíṣà, pé “Wò ó, Olúwa wa, ìtẹ̀dó ìlú yìí dára, gẹ́gẹ́ bí o ti rí i, ṣùgbọ́n omi náà kò dára ilẹ̀ náà sì jẹ́ aṣálẹ̀.”

20. Ó sì wí pé, “Mú àwokòtò tuntun fún mi wá, kí o sì mú iyọ̀ sí inú rẹ̀.” Wọ́n sì gbé e wá fún un.

21. Nígbà náà ó sì jáde lọ sí ibi orísun omi, ó sì da iyọ̀ sí inú rẹ̀, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi ti wo omi yìí sàn. Kò ní mú ikú wá mọ́ tàbí mú ilẹ̀ náà ṣá.’ ”

22. Omi náà sì ti dára ni mímu títí di òní, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Èlíṣà ti sọ.

Wọ́n Fi Èlíṣà Ṣe Yẹ̀yẹ́

23. Láti ibẹ̀ Èlíṣà lọ sókè ní Bétélì gẹ́gẹ́ bí ó ti ń rìn lọ lójú ọ̀nà, àwọn ọ̀dọ́ kan jáde wá láti ìlú náà wọ́n sì fi ṣe ẹlẹ́yà. “Má a lọ sókè ìwọ apárí!” Wọ́n wí pé. “Má a lọ sókè ìwọ apárí!”

24. Ó sì yípadà, ó sì wò wọ́n ó sì fi wọ́n bú ní orúkọ Olúwa. Nígbà náà béárì méjì sì jáde wá láti inú igbó ó sì lu méjìlélógójì (42) lára àwọn ọ̀dọ́ náà.

25. Ó sì lọ sí orí òkè Kámẹ́lì láti ibẹ̀ ó sì padà sí Samáríà.