orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà ìjọba Jéhóíákímù, Nebukadinéṣárì ọba Bábílónì gbógun sí ilẹ̀ náà, Jéhóíákímù sì di ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́ta. Ṣùgbọ́n nígbà náà ó yí ọkàn rẹ̀ padà ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadinéṣárì.

2. Olúwa sì rán àwọn ará Bábílónì, àwọn ará Aráméánì, àwọn ará Móábù àti àwọn ọmọ Ámónì. Ó rán wọn láti pa Júdà run, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípaṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.

3. Nítòótọ́ eléyìí ṣẹlẹ̀ sí Júdà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, láti mú wọn kúrò níwájú rẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Mánásè àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe.

4. Àti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí a ta sílẹ̀ nítorí ó ti kún Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí Olúwa kò sì fẹ́ láti dáríjìn.

5. Ní ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jéhóíákímù, àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ọba Júdà?

6. Jéhóíákímù sùn pẹ̀lú baba rẹ̀, Jéhóíákínì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

7. Ọba Éjíbítì kò sì tún jáde ní ìlú rẹ̀ mọ́, nítorí ọba Bábílónì ti gba gbogbo agbégbé rẹ̀ láti odò Éjíbítì lọ sí odò Éúférátè.

Jéhóíákínì Ọba Júdà.

8. Jéhóíákínì jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a sì máa jẹ́ Néhúṣítà ọmọbìnrin Élínátanì; ó wá láti Jérúsálẹ́mù.

9. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe.

10. Ní àkókò náà àwọn ìjòyè Nebukadinéṣárì ọba Bábílónì wá sílẹ̀ Jérúsálẹ́mù wọ́n sì gbé dófì kalẹ̀ fún un,

11. Nebukadinéṣárì fúnrarẹ̀ wá sókè sí ìlú nígbà tí àwọn ìjòyè fi ogun dótì í.

12. Jéhóíákímù ọba Júdà àti ìyá rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìwẹ̀fà àti àwọn ìjòyè gbogbo wọn sì jọ̀wọ́ ara wọn fún un.Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀ ti ọba Bábílónì ó mú Jéhóíákínì ẹlẹ́wọ̀n.

13. Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ Nebukadinéṣárì kó gbogbo ìṣúra láti inú ilé Olúwa àti láti ilé ọba, ó sì mú u lọ gbogbo ohun èlò wúrà ti Ṣólómónì ọba Ísírẹ́lì

14. Ti kọ́ fún Olúwa, Ó kó wọn lọ sí ìgbékùn gbogbo Jérúsálẹ́mù: gbogbo ìjòyè àti àwọn akọni alágbára ọkùnrin, àti gbogbo oníṣọ̀nà àti ọlọ́nà tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbàárún ún, àwọn talákà ènìyàn ilẹ̀ náà nìkan ni ó kù.

15. Nebukadinéṣárì mú Jéhóíákínì ní ìgbékùn lọ sí Bábílónì. Ó sì tún mú ìyá ọba láti Jérúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì, ìyàwó rẹ̀ àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn olórí ile náà.

16. Ọba Bábílónì àwọn ọkùnrin ọlọ́lá tí ó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàarin (7000) alágbára ọkùnrin, alágbára tí ó yẹ fún ogun, àti àwọn ẹgbẹ̀rùn (1000) oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ.

17. Ó sì mú Mátanáyà arákùnrin baba Jéhóíákínì, ọba ní ìlú rẹ̀ ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Ṣedekáyà.

Ṣedekáyà Ọba Júdà

18. Ṣedekáyà jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kànlá. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hámútalì ọmọbìnrin Jeremáyà; ó sì wá láti Líbínà.

19. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Jéhóíákínì ti ṣe.

20. Nítorí tí ìbínú Olúwa, ni gbogbo èyí ṣe sẹ sí Jérúsálẹ́mù, àti Júdà, ní òpin ó ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀.Nísinsìn yìí Ṣedekíàyà sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Bábílónì.