orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66
  67. 67
  68. 68
  69. 69
  70. 70
  71. 71
  72. 72
  73. 73
  74. 74
  75. 75
  76. 76
  77. 77
  78. 78
  79. 79
  80. 80
  81. 81
  82. 82
  83. 83
  84. 84
  85. 85
  86. 86
  87. 87
  88. 88
  89. 89
  90. 90
  91. 91
  92. 92
  93. 93
  94. 94
  95. 95
  96. 96
  97. 97
  98. 98
  99. 99
  100. 100
  101. 101
  102. 102
  103. 103
  104. 104
  105. 105
  106. 106
  107. 107
  108. 108
  109. 109
  110. 110
  111. 111
  112. 112
  113. 113
  114. 114
  115. 115
  116. 116
  117. 117
  118. 118
  119. 119
  120. 120
  121. 121
  122. 122
  123. 123
  124. 124
  125. 125
  126. 126
  127. 127
  128. 128
  129. 129
  130. 130
  131. 131
  132. 132
  133. 133
  134. 134
  135. 135
  136. 136
  137. 137
  138. 138
  139. 139
  140. 140
  141. 141
  142. 142
  143. 143
  144. 144
  145. 145
  146. 146
  147. 147
  148. 148
  149. 149
  150. 150

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìdúpẹ́ Fún Ìtúsílẹ̀ Àti Àdúrà Fún Ìrànlọ́wọ́

1. Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa;ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.

2. Ó fà mí yọ gòkèláti inú ihò ìparun,láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀,ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta,ó sì jẹ́ kí ìgbesẹ̀ mi wà láìfòyà.

3. Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu,àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa.Ọ̀pọ̀ yóò ríi wọn yóò sì bẹ̀rù,wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa.

4. Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n ọn-nìtí ó fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọntí wọn kò sì yípadà sí agbéraga,tàbí àwọn tí ó yapalọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn.

5. Olúwa Ọlọ́run mi, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ni àwọn isẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe.Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa;ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹtí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn,wọn ju ohun tíènìyàn leè kà lọ.

6. Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,ìwọ ti sí mi ní etí.Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ni ìwọ kò bèèrè.

7. Nígbà náà ni mo wí pé,“Èmi nìyí;nínú ìwé kíkà nìa kọ ọ nípa temí wí pé.

8. Mo ní inú dídùnláti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ Rẹ,ìwọ Ọlọ́run mi;Òfin Rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”

9. Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlàláàrin àwùjọ ńlá;wòó,èmi kò pa ètè mí mọ́,gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀,ìwọ Olúwa.

10. Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlàsin ní àyà mi,èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́àti ìgbàlà Rẹ̀:èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀àti òtítọ́ Rẹ̀ mọ́kúrò láàrin àwọn ìjọ ńlá.

11. Ìwọ má ṣe,fa àánú Rẹ̀ tí ó rọnúsẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi; Olúwajẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ Rẹàti òtítọ́ Rẹkí ó máa pa mí mọ́títí ayérayé.

12. Nítorí pé àìníye ibini ó yí mi káàkiri,ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi,títí tí èmi kò fi ríran mọ́;wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,àti wí pé àyà mí ti kùnà.

13. Jẹ́ kí ó wù ọ́,ìwọ Olúwa,láti gbà mí là; Olúwa,yára láti ràn mí lọ́wọ́.

14. Gbogbo àwọn wọ̀nnìni kí ojú kí ó tìkí wọn kí ó sì dààmúàwọn tí ń wá ọkàn miláti parun:jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìnki á sì dójú tì wọ́n,àwọn tí n wá ìpalára mi.

15. Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, “Áà! Áá!”ó di ẹni àfọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtijú wọn.

16. Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń wá ọkí ó máa yọ̀kí inú wọn sì máa dùn sí ọ;kí gbogbo àwọn tí ó sì fẹ́ ìgbàlà Rẹkí o máa wí nígbà gbogbo pé,“Gbígbéga ni Olúwa!”

17. Bí ó ṣe ti èmi ni,talákà àti aláìní ni èmi,ṣùgbọ́n Olúwa ń ṣe ìrántí mi.Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ miàti ìgbàlà mi;Má ṣe jẹ́ kí ó pẹ́,ìwọ Ọlọ́run mi.