1. Kí ṣe fún wa, Olúwa kì ṣe fún wá,ṣùgbọ́n fún orúkọ Rẹ̀ ní a fi ògo fún,fún àánú àti òtítọ́ Rẹ.
2. Torí kí ní àwọn aláìkọlà yóò ṣe sọ pé,níbo ni Ọlọ́run wa wà.
3. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run:tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.
4. Òrìṣà fàdákà àti wúrà,iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn
5. Wọn ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ̀rọ̀,wọn ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
6. Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ràn:wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọ́n kò fi gbóòórùn
7. Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó,wọ́n ní ẹṣẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn;bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn.
8. Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn;gẹ́gẹ́ bẹ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ Rẹ̀ lé wọn.
9. Ìwọ Ísírẹ́lì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
10. Ẹ yin ilé Árónì, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:oun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn
11. Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:oun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn.
12. Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Ísírẹ́lì;yóò bùkún ilé Árónì.
13. Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,àti kékeré àti ńlá.
14. Olúwa yóò mú ọ pọ̀ síi síwájú àti síwájú,ìwọ àti àwọn ọmọ Rẹ̀.
15. Ẹ fi ìbùkún fún Olúwaẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
16. Ọ̀run àní ọ̀run ni ti, Olúwa:ṣùgbọ́n ayé lo fi fún ọmọ ènìyàn.
17. Òkú kò le yìn Olúwa,tàbí ẹni tí o ti lọ sí ìṣàlẹ̀ ìdákẹ́jẹ́.
18. Ṣùgbọ́n àwa o fi ìbùkún fún Olúwaláti ìsinsìn yí lọ àti títí láéláé.Ẹ yin Olúwa.