1. Ẹ máa yin Olúwa. Èmi yóò máayìn Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi,ní àwujọ àwọn olóòtọ́, àti ní ijọ ènìyàn.
2. Iṣẹ́ Olúwa tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú Rẹ̀.
3. Iṣẹ́ Rẹ̀ ní ọlá ńlá àti ògo:àti òdodo Rẹ̀ dúró láéláé.
4. Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀, láti máa rántí: Olúwa ni olóore ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.
5. O ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀:oun ń rántí májẹ̀mú Rẹ̀.
6. Ó ti fi hàn àwọn ènìyàn Rẹ̀ agbára isẹ́ Rẹ̀láti fún wọn ní ilẹ̀lérí ni ìní
7. Iṣẹ́ ọwọ Rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;gbogbo òfin Rẹ̀ sì dájú.
8. Wọ́n dúró láé àti láé,ní òtítọ́ àti òdodo ní a ṣe wọ́n.
9. Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn Rẹ̀:ó pàṣẹ májẹ̀mú Rẹ̀ títí láé:mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ní orúkọ Rẹ̀.
10. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin Rẹ̀:ìyìn Rẹ̀ dúró láé.