1. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
2. Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run:nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
3. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn Olúwa,nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
4. Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
5. Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
6. Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
7. Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé
8. Òòrùn láti jọba ọ̀sán;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
9. Òsùpá àti ìràwọ̀ láti jọba òru;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
10. Fún ẹni tí ó kọlu Éjíbítì lára àwọn àkọ́bí wọn;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
11. Ó sì mú Ísírẹ́lì jáde kúrò láàrin wọn;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
12. Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
13. Fún ẹni tí ó pín òkun pupa ní ìyà;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
14. Ó sì mú Ísírẹ́lì kọjá láàrin Rẹ̀nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
15. Ṣùgbọ́n ó bi Fáráò àti ogun Rẹ̀ ṣubú nínú òkun pupa;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
16. Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn Rẹ̀ la ihà jánítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
17. Fún ẹni tí ó kọ lu àwọn ọba ńlá;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
18. Ó sì pa àwọn ọba olókìkínítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
19. Síónì, ọba àwọn ará Ámórìnítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
20. Àti Ógù, ọba Báṣánì;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
21. Ó sì fi ilẹ̀ wọn fúnni ní ìní,nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
22. Ìní fún Ísírẹ́lì, ìránṣẹ́ Rẹ̀,nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
23. Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
24. Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
25. Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbonítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.
26. Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.