1. Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi péẸ jẹ́ kí a lọ sílé Olúwa.
2. Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè Rẹ,ìwọ Jérúsálẹ́mù.
3. Jérúsálẹ́mù, ìwọ tí a kọ́ bí ìlútí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan
4. Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ,àwọn ẹ̀yà Olúwa,ẹ̀rí fún Ísírẹ́lì, látimáa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa.
5. Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀,àwọn ìtẹ́ ilé Dáfídì.
6. Gbàdúrà fún àlàáfíà Jérúsálẹ́mù;àwọn tí o fẹ́ ọ yóò ṣe rere.
7. Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi Rẹ̀,àti ire nínú ààfin Rẹ̀.
8. Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mièmi yóò wí nísinsìyí pé,kí àlàáfíà kí ó wà nínú Rẹ̀;
9. Nítorí ilé Olúwa Ọlọ́run wa,èmi yóò máa wá ire Rẹ̀.