1. Nígbà tí Ísírẹ́lì jáde ní Éjíbítì,ilé Jákọ́bù láti inú ènìyàn àjòjì èdè
2. Júdà wà ní ibi mímọ́,Ísírẹ́lì wà ní ìjọba.
3. Òkun sì rí i, ó sì wárìrì:Jódáni sì padà sẹ́yìn.
4. Àwọn òkè ńlá ń fò bí agbo àtiòkè kékèké bí ọ̀dọ́ àgùntàn.
5. Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ òkun, tí ìwọ fi wárìrì?Ìwọ Jódánì, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?
6. Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí agbo,àti ẹ̀yin òkè kékèké bí ọ̀dọ́ àgùntàn?
7. Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa;ní iwájú Ọlọ́run Jákọ́bù
8. tí ó sọ àpáta di adágún omi,àti òkúta-ìbọn di orísun omi.