1. Ọlọ́run ni ààbò àti agbára waó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ nínú ìgbà ìpọ́njú.
2. Nítori náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ sí ayé ní ìdítí òkè sì ṣubú sínú òkun
3. Tí omi Rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mìtí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára Rẹ̀. Sela
4. Odò ńlá kan wà tí sísàn Rẹ̀ mú ìnú ìlú Ọlọ́run dùnibi mímọ́, nibi ti ọ̀gá ògo ń gbé.
5. Ọlọ́run wà pẹ̀lú Rẹ̀, kò ní yẹ̀:Ọlọ́run yóò ràn an lọ́wọ́ ní kùtùkùtù ọ̀wúrọ̀
6. Àwọn orílẹ̀ èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba subúó gbé ohun Rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.
7. Ọlọ́run awọn ọmọ ogún wà pẹ̀lú waỌlọ́run Jákọ́bù ni ààbò wa
8. Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwairú ahoro tí ó ṣe ní ayé
9. O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayéó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjìó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná
10. Ẹ dúró jẹ́ẹ kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́runA ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀ èdèA o gbé mi ga ní ayé.
11. Ọlọ́run alágbára wà pẹ̀lú waỌlọ́run Jákọ́bù sì ni ààbò wa.