1. Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyànẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀
2. Báwo ni Olúwa ọ̀gá ògo ti ni ẹ̀rù tóọba ńlá lórí gbogbo ayé
3. Ó ṣẹ́ àwọn orílẹ̀ èdè lábẹ́ waàwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa
4. Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún waọlá Jákọ́bù, ẹni tí ó fẹ́ wa
5. Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀ Olúwa ti òun ti àriwo ipè
6. Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, Ẹ kọrin ìyìnẸ kọrin ìyìn sí ọba wa, Ẹ kọrin ìyìn!
7. Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayéẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Sáàmù!
8. Ọlọ́run jọba lórí gbogbo ayé;Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ Rẹ̀
9. Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọgẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Ábúráhámùnítorí asà ayé ti Ọlọ́run niòun ni ó ga jùlọ.