1. Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá,ó ṣe ìdájọ́ láàárin àwọn “ọlọ́run òrìṣà”:
2. “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìsòdodokí ó sì ṣe ojú ìṣájú sí àwọn ènìyàn búburú?
3. Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba;ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.
4. Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní;gbà wọ́n kùró lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.
5. “Wọn kò mọ̀ ohunkankan,wọn kò lóye ohunkankan.Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn;a ni gbogbo ìpínlẹ̀ ayé.
6. “Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”;ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ ọ̀gá ògo jùlọ.’
7. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin o kú bí ènìyàn lásán;ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ aládé.”
8. Dìde Ọlọ́run ṣe ìdájọ́ ayé,nítorí gbogbo orílẹ̀ èdè ni ìní Rẹ.