orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66
  67. 67
  68. 68
  69. 69
  70. 70
  71. 71
  72. 72
  73. 73
  74. 74
  75. 75
  76. 76
  77. 77
  78. 78
  79. 79
  80. 80
  81. 81
  82. 82
  83. 83
  84. 84
  85. 85
  86. 86
  87. 87
  88. 88
  89. 89
  90. 90
  91. 91
  92. 92
  93. 93
  94. 94
  95. 95
  96. 96
  97. 97
  98. 98
  99. 99
  100. 100
  101. 101
  102. 102
  103. 103
  104. 104
  105. 105
  106. 106
  107. 107
  108. 108
  109. 109
  110. 110
  111. 111
  112. 112
  113. 113
  114. 114
  115. 115
  116. 116
  117. 117
  118. 118
  119. 119
  120. 120
  121. 121
  122. 122
  123. 123
  124. 124
  125. 125
  126. 126
  127. 127
  128. 128
  129. 129
  130. 130
  131. 131
  132. 132
  133. 133
  134. 134
  135. 135
  136. 136
  137. 137
  138. 138
  139. 139
  140. 140
  141. 141
  142. 142
  143. 143
  144. 144
  145. 145
  146. 146
  147. 147
  148. 148
  149. 149
  150. 150

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 91 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìdánilójú Ààbò Ọlọ́run

1. Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ ọ̀gá ògoni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.

2. Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé,“Òun ní ààbò àti odi mi,Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.

3. Ní tòótọ́ òun yóò gbà mí nínúìdẹkùn àwọn pẹyẹ pẹyẹàti nínú àjàkálẹ̀-àrùn búburú.

4. Òun yóò fi ìyẹ́ Rẹ̀ bò mí,àti ni abẹ́ ìyẹ́ Rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò;òtítọ́ Rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.

5. Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru,tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,

6. Tàbí fún àjàkálẹ̀-àrùn tí ń rìn kiri ni òkùnkùn,tàbí fún ìparun ti ń rin kirí ni ọ̀sán gangan.

7. Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ Rẹ,ẹgbàarùn ún ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹṣùgbọ́n kì yóò sún mọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ

8. Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú Rẹàti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.

9. Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò Rẹ,ìwọ fi Ọ̀ga Ògo ṣe ibùgbé Rẹ.

10. Búburú kan ki yóò subu lù ọ́Bẹ́ẹ̀ ni àrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé Rẹ.

11. Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn ańgẹ́lì nípa tìrẹláti pa ọ́ mọ ní gbogbo ọ̀nà Rẹ;

12. Wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn,nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ Rẹ̀ gún òkúta.

13. Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀;ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò nì ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀

14. “Nítorí tí ìfẹ́ Rẹ sì mi,”“èmi yóò gbà ọ́;èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.

15. Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dáa lóhùn;èmi yóò wà pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ipọ́nju,èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un

16. Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùnèmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”