1. Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi,ó sì dámi lóhùn
2. Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ète èkéàti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.
3. Kí ni kí a fi fún ọ?Àti kín kí a tún ṣe fún ọ,ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?
4. Òun yóò bá ọ́ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun,pẹ̀lú eyin iná igi ìgbálẹ̀.
5. Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Mésékì,nítorí èmi gbé nínú àgọ́ Kédárì!
6. Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbéláàrin àwọn tí ó kóríra àlàáfíà.
7. Ènìyàn àlàáfíà ni mí;ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni ti wọn.