orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66
  67. 67
  68. 68
  69. 69
  70. 70
  71. 71
  72. 72
  73. 73
  74. 74
  75. 75
  76. 76
  77. 77
  78. 78
  79. 79
  80. 80
  81. 81
  82. 82
  83. 83
  84. 84
  85. 85
  86. 86
  87. 87
  88. 88
  89. 89
  90. 90
  91. 91
  92. 92
  93. 93
  94. 94
  95. 95
  96. 96
  97. 97
  98. 98
  99. 99
  100. 100
  101. 101
  102. 102
  103. 103
  104. 104
  105. 105
  106. 106
  107. 107
  108. 108
  109. 109
  110. 110
  111. 111
  112. 112
  113. 113
  114. 114
  115. 115
  116. 116
  117. 117
  118. 118
  119. 119
  120. 120
  121. 121
  122. 122
  123. 123
  124. 124
  125. 125
  126. 126
  127. 127
  128. 128
  129. 129
  130. 130
  131. 131
  132. 132
  133. 133
  134. 134
  135. 135
  136. 136
  137. 137
  138. 138
  139. 139
  140. 140
  141. 141
  142. 142
  143. 143
  144. 144
  145. 145
  146. 146
  147. 147
  148. 148
  149. 149
  150. 150

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 149 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ fi ìyìn Olúwa.Ẹ kọrin titun sí Olúwa.Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́

2. Jẹ́ kí Ísírẹ́lì kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá ajẹ́ kí àwọn ọmọ Síónì kí ó níayọ̀ nínú ọba wọn.

3. Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ Rẹ̀jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.

4. Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé

5. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá Rẹ̀kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.

6. Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọnàti idà olójú méjì ní ọ́wọ́ wọn.

7. Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀ èdè,àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn,

8. Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọnàti láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀irin de àwọn ọlọ́lá wọn.

9. Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ Rẹ̀ sí wọnèyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀.Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.