orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 59 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ẹ̀ṣẹ̀, Ìjẹ́wọ́ Àti Ìràpàdà

1. Lódodo ọwọ́ Olúwa kò kúrú láti gbàlà,tàbí kí etí rẹ̀ wúwo láti gbọ́.

2. Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín;Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojúu rẹ̀ pamọ́ fún un yíntó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́.

3. Nítorí ọwọ́ọ yín di aláìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀,àti ìka ọwọ́ọ yín fún ẹ̀bi.Ètèe yín ń pa irọ́ púpọ̀,ahọ́n an yín sì ń ṣọ̀rọ̀ nǹkan ibi.

4. Kò sí ẹni tí ó bèèrè fún ìdájọ́ òdodo;kò sí ẹni tí ó ro ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́.Wọ́n gbọ́kànlé àwíjàre aṣán àti ọ̀rọ̀ irọ́;wọ́n lóyún ìkà, wọn sì bí wàhálà

5. Wọn ń pa ẹyín pamọ́lẹ̀wọn sì ń ta owú aláǹtakùn.Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹyin wọn yóò kú,àti nígbà tí a pa ọ̀kan, pamọ́lẹ̀ ni ó jáde.

6. Òwú wọn kò wúlò fún aṣọ rírán;wọn kò lè fi aṣọ tí wọ́n hun bo ara wọn.Iṣẹ́ wọn jẹ́ ti ibi, ìwà jàǹdàkú sì kún ọwọ́ wọn.

7. Ẹsẹ̀ wọn yára bọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀;wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.Èrò wọn sì jẹ́ èrò ibi;ìparun àti ìdahoro ni ó wà ní ṣíṣe àmì ọ̀nà wọn.

8. Ọ̀nà àlàáfíà èyí ni wọn kò mọ̀;kò sí òdodo ní ojú ọ̀nà wọnwọ́n ti sọ wọ́n dì ọ̀nà kọ́rọkọ́rọ,kò sí ẹni tí ó tọ ọ̀nà yìí tí yóò rí àlàáfíà.

9. Nítorí èyí ni ẹ̀tọ́ fi jìnnà sí wa,àti tí òdodo kò fi tẹ̀wá lọ́wọ́.A ń wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ jẹ́ òkùnkùn;fún ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n à ń rìn nínú òjìji.

10. Gẹ́gẹ́ bí afọ́jú à ń táràrà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògirití a ń wá ọ̀nà wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí kò ní ojú.Ní ọ̀sán gangan ni à ń kọsẹ̀ bí ẹni pé alẹ́ ni;láàrin alágbára àwa dàbí òkú.

11. Gbogbo wa là ń ké bí i bíárì;àwa pohùnréré ẹkún bí àdàbàA ń wá ìdájọ́ òdodo ṣùgbọ́n kò sí; à ń wọ̀nàfún ìtúsílẹ̀, ṣùgbọ́n ó jìnnà réré.

12. Nítorí àwọn àṣìṣe wa pọ̀ níwájú rẹ,àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí takò wá.Àwọn àìṣedéédéé wa sì wà pẹ̀lú wa,àwa pẹ̀lú sì mọ àìṣedéédéé wa,

13. ọ̀tẹ̀ àti àrékérekè wa sí Olúwa,kíkọ ẹ̀yìn wa sí Ọlọ́run,dídá yánpọnyánrin àti ìnilára sílẹ̀,pípààrọ̀ tí ọkàn wa ti gbérò síta.

14. Nítorí èyí ni a ṣe lé ìdájọ́ òdodo ṣẹ́yìn,àti ti òdodo dúró lókèèrè;òtítọ́ ti ṣubú ní òpópó ọ̀nà,òdodo kò sì le è wọlé.

15. A kò rí òtítọ́ mọ́,àti ẹni tí ó bá sá ibi tì di ìjẹ. Olúwa wò ó ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́pé kò sí ìdájọ́ òdodo.

16. Òun rí i pé kò sí ẹnìkan,àyà fò ó pé kò sí ẹnìkan láti ṣèrànwọ́;nítorí apá òun tìkálárarẹ̀ ló ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún ara rẹ̀,àti òdodo òun tìkálára rẹ̀ ló gbé e ró.

17. Ó gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbàya rẹ̀,àti àsíborí ìgbàlà ní oríi rẹ̀;ó gbé ẹ̀wù ẹ̀san wọ̀ó sì yí ara rẹ̀ ní ìtara bí ẹ̀wù.

18. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ti ṣe,bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣan ánìbínú fún àwọn ọ̀tá rẹ̀àti ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀;òun yóò ṣan án fún àwọn erékùṣù ẹ̀tọ́ wọn.

19. Láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,àti láti ìlà oòrùn, wọn yóò bọ̀wọ̀ fún ògo rẹ̀.Nítorí òun yóò wá gẹ́gẹ́ bí i rírú omièyí tí èémí Olúwa ń tì lọ.

20. “Olùdáǹdè yóò wá sí Ṣíhónì,sí àwọn tí ó wà ní Jákọ́bù tí óronúpìwàdá ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí.

21. “Àti fún èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn nìyìí,” ni Olúwa wí, “Ẹ̀mí mi, tí ó wà nínú yín, àti ọ̀rọ̀ mi tí mo ti fi sí ẹnu yín, kì yóò kúrò lẹ́nu yín, tàbí lẹ́nu àwọn ọmọ yín, tàbí láti ẹnu àwọn ìrandíran wọn láti àkókò yìí lọ àti títí láéláé” ni Olúwa wí.