orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìparun Olúwa Lórí Ilẹ̀ Ayé

1. Kíyèsí i, Olúwa yóò sọ ohungbogbo dòfo ní ilẹ̀ ayéyóò sì pa á runòun yóò pa ojúu rẹ̀ rẹ́yóò sì fọ́n àwọn olùgbé ibẹ̀ káàkiri—

2. bákan náà ni yóò sì rífún àlùfáà àti àwọn ènìyàn,fún ọ̀gá àti ọmọ ọ̀dọ̀,fún ìya-ilé àti ọmọbìnrin,fún olùtà àti olùrà,fún ayáni àti atọrọfún ayánilówó àti onígbésè.

3. Ilé ayé ni a ó sọ di ahoro pátapátaa ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ run. Olúwa ni ó ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.

4. Ilẹ̀ ayé ti gbẹ ó sì ṣá,ayé ń ṣòjòjò, àárẹ̀ mú un,àwọn ẹni gíga ilẹ̀ ayé wà nínú ìpọ́njú

5. àwọn ènìyàn ayé ti bà á jẹ́;wọ́n ti pa àwọn òfin runwọ́n ṣe lòdì sí àwọn ìlànàwọ́n sì ti ba májẹ̀mú ayérayé jẹ́.

6. Nítorí náà, ègún kan ti jẹ ayé run;àwọn ènìyàn rẹ̀ ní láti ru ẹ̀bi wọn.Nítorí náà, àwọn olùgbé ayé ti gbiná dànù,àwọn ẹ̀tàhóró ló sì kù.

7. Wáìnì tuntun ti gbẹ, àjàrà sì ti rọ,gbogbo àwọn alárìíyá sì kérora.

8. Àríyá ti tamborínì ti dákẹ́ariwo àwọn tí ń ṣàjọyọ̀ ti dáwọ́ dúróayọ̀ hápù ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.

9. Kò ṣeéṣe fún wọn láti máa mu wáìnì pẹ̀lú orin kíkọ mọ́ọtí líle ti di ìkorò fún àwọn ọ̀mu.

10. Ìlú tí a run ti dahoro,ẹnu ọ̀nà à bá wọlé kọ̀ọ̀kan ni a dí pa.

11. Ní òpópónà ni wọ́n ti ń kígbe fún wáìnìgbogbo ayọ̀ọ wọn ti di ìbànújẹ́,gbogbo àríyá ni a lé kúrò lórí ilẹ̀ ayé.

12. Ìlú ni a ti fi sílẹ̀ ní ahoro,ìlẹ̀kùn rẹ̀ ni a sì ti pa bámú bámú.

13. Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí ní orí ilẹ̀ ayéàti láàrin àwọn orílẹ̀ èdè pẹ̀lú,gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a lu igi ólífì,tàbí gẹ́gẹ́ bí i pàǹtí tí ó ṣẹ́kù lẹ́yìntí a kórè èso tán.

14. Wọ́n gbé ohùn wọn ṣókè, wọ́n sì hó fún ayọ̀;láti ìwọ̀ oòrùn ni wọn yóò ti polongoọlá-ńlá Olúwa.

15. Nítorí náà ní ìlà oòrùn ẹ fi ògo fún Olúwa;gbé orúkọ Olúwa ga, àníỌlọ́run Ísírẹ́lì,ní àwọn erékùṣù ti inú òkun,

16. Láti òpin ayé wá ni a ti gbọ́ orin;“Ògo ni fún olódodo n nì.”Ṣùgbọ́n mo wí pé, “mo ṣègbé, mo ṣègbé!”“Ègbé ni fún mi!Alárékérekè dalẹ̀!Pẹ̀lú ìhàlẹ̀ ni àgàbàgebè fi dalẹ̀!”

17. Ìpáyà, isà-òkú, àti ìdẹkùn ń dúró dè ọ́,Ìwọ ènìyàn ilẹ̀ ayé.

18. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá nítorí ariwo ìpayàyóò ṣubú sínú ihò,ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yọ́ jáde nínú ihòni ìdẹkùn yóò gbámú.Ibodè ọ̀run ti wà ní sísí sílẹ̀Ìpìlẹ̀ ayé mì tìtì.

19. Ilẹ̀ ayé ti fọ́ilẹ̀ ayé ti fọ́ dànù,a ti mi ilẹ̀ ayé rìrìrìrì.

20. Ilẹ̀ ayé yí gbiri bí ọ̀mùtí,ó bì síwá ṣẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́;Ẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ ń pa á lẹ́rùtó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣubú láìní lè dìde mọ́.

21. Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò jẹ ẹ́ níyàgbogbo agbára tí ó wà lókè lọ́runàti àwọn ọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé.

22. A ó dà wọ́n papọ̀gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n tí a dè nínú un túbú,a ó tì wọ́n mọ́ inú ẹ̀wọ̀na ó sì jẹ wọ́n ní ìyà lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́.

23. A ó rẹ òṣùpá sílẹ̀, ojú yóò sì ti òòrùn;nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò jọbaní orí òkè Ṣíhónì àti ní Jérúsálẹ́mù,àti níwájú àwọn alàgbà rẹ ní ògo.