orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 54 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ògo Ọjọ́ Iwájú Ti Ṣíónì

1. “Kọrin, Ìwọ obìnrin àgàn,ìwọ tí kò tí ì bímọ rí;búsí orin, ẹ hó fún ayọ̀,ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí;nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoroju ti ẹni tí ó ní ọkọ,”ni Olúwa wí.

2. Fẹ ibi àgọ́ rẹ lójú sí i,fẹ aṣọ àgọ́ rẹ kí ó gbòòrò sí i,má ṣe dá a dúró;sọ okùn rẹ di gígùn,mú òpo rẹ lágbára sí i.

3. Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn-ún àti sí òsì;ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀ èdè,wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn.

4. “Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́.Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù.Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwee rẹÌwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìwà-rópó rẹ mọ́.

5. Nítorí Ẹlẹ́dáà rẹ ni ọkọ rẹ Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ni Olùràpadà rẹ;a sì pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.

6. Olúwa yóò pè ọ́ padàà fi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀tí a sì bà lọ́kàn jẹ́obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́,tí a sì wá já kulẹ̀” ni Olúwa wí.

7. “Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀,ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóòmú ọ padà wá.

8. Ní ríru ìbínú.Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan,ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kunÈmi yóò síjú àánú wò ọ́,”ni Olúwa Olùdáǹdè rẹ wí.

9. “Sí mi, èyí dàbí i àwọn ọjọ́ Núà,nígbà tí mo búra pé àwọn omiNúà kì yóò tún bo ilẹ̀ ayé mọ́.Bẹ́ẹ̀ ni nísinsìnyìí mo ti búra láti má ṣe bínú sí ọ,bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí mọ́.

10. Bí a tilẹ̀ mi àwọn òkè ńlátí a sì sí àwọn òkè kékeré nídìí,Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ìfẹ́ àìkùnà mi fún ọ kì yóò yẹ̀ láéláétàbí májẹ̀mú àlàáfíà ni a ó mú kúrò,”ni Olúwa, ẹni tí ó síjú àánú wò ọ́ wí.

11. Ìwọ ìlú tí a pọ́n lójú, tí ìjì ń gbá kirití a kò sì tù nínú,Èmi yóò fi òkúta tìróò kọ́ ọàti ìpìlẹ̀ rẹ pẹ̀lú sáfírésì.

12. Èmi yóò fi rúbísì ṣe odiì rẹ,àwọn ẹnu ọ̀nà ni a ó fi ohun èlò dáradára fún,àti àwọn ògiri rẹ pẹ̀lú òkúta iyebíye.

13. Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni Olúwa yóò kọ́,àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀.

14. Ní òdodo ni a ó fi ìdí rẹ kalẹ̀Ìwà ipá yóò jìnnà sí ọo kò ní bẹ̀rù ohunkóhunÌpayà la ó mú kúrò pátapáta;kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.

15. Bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ bá ọ jà, kò ní jẹ́ láti ọwọ́ọ̀ mi;ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ọ jà ni yóò túúbá fún ọ.

16. “Kíyèsí i, Èmi ni ó dá alágbẹ̀dẹtí ń fẹ́ iná èédú di èjò-inátí ó sì ń mú ohun èlò wá tí ó bá iṣẹ́ rẹ mu.Èmi náà sì ni ẹni tí ó dá apanirun láti ṣe iṣẹ́ ibi;

17. Kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò ṣe nǹkan,ìwọ yóò já ahọ́nkáhọ́n tó bá fẹ̀ṣùn kàn ọ́ kulẹ̀.Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ Olúwa,èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,”ni Olúwa wí.