orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 61 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ọdún Ojúrere Olúwa

1. Ẹ̀mí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà lára minítorí Olúwa ti fi àmì-òróró yàn míláti wàásù ìhìnrere fún àwọn talákà.Ó ti rán mi láti ṣe àwòtan oníròbìnújẹ́láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùnàti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,

2. Láti kéde ọdún ojúrere Olúwaàti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa,láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,

3. àti láti pèṣè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Ṣíhónìláti dé wọn ládé ẹ̀yẹ dípò eérú,òróró ìdùnnú dípò ìbànújẹ́,àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúùru ọkàn.A ó sì pè wọ́n ní óákù òdodo,irúgbìn Olúwaláti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.

4. Wọn yóò tún àwọn ahoro ìṣẹ̀ǹbáyé kọ́wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́tijọ́ náà bọ̀ sípò;wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padàtí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn.

5. Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ;àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ.

6. A ó sì máa pè yín ní àlùfáà Olúwa,a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa.Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdèàti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo.

7. Dípò àbùkù wọnàwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po-méjì,àti dípò àbùkù wọnwọn yóò yọ̀ nínú ìníi wọn;bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn,ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ ti wọn.

8. “Nítorí Èmi, Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo;mo kórìíra olè jíjà àti ẹ̀ṣẹ̀Ní òtítọ́ mi èmi yóò ṣẹ̀san fún wọnèmi yóò sì dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lúu wọn.

9. A ó mọ ìrandíran wọn láàrin àwọn orílẹ̀ èdèàti àwọn ìran wọn láàrin àwọn ènìyànGbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò mọ̀ péwọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí Olúwa ti bùkún.”

10. Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa;ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi.Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlàó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo;gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe oríi rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà,àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́.

11. Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ti í mú èhù jádeàti bí ọgbà ṣe ń mú irúgbìn dàgbà,Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò ṣe mú òdodo àti ìyìnkí ó ru sókè níwájú gbogbo orílẹ̀ èdè.