orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Ikọ̀ Ọba Láti Bábílónì

1. Ní àkókò náà ni Méródákì-Báládánì ọmọ Báládánì ọba Bábílónì fi ìwé àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Heṣekáyà, nítorí ó gbọ́ pé ó ṣàìsàn ó sì gbádùn.

2. Heṣekáyà gba àwọn ikọ̀ yìí tayọ̀ tayọ̀, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà nínú yàrá ìpanǹkan mọ́ hàn wọn—sílífà, wúrà, ohun olóòórùn dídùn, òróró dídára, gbogbo nǹkan ogun rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìṣúra rẹ̀ kò sí ohunkóhun tí ó wà nínú ààfin rẹ̀ tàbí ní ìjọba rẹ̀ tí Heṣekáyà kò fi hàn wọ́n.

3. Lẹ́yìn náà wòlíì Àìṣáyà lọ sí ọ̀dọ̀ Heṣekáyà ọba ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí, níbo ni wọ́n sì ti wá?”“Láti ilẹ̀ jínjìnnà,” ni èsì Heṣekáyà. “Wọ́n wá sọ́dọ̀ mi láti Bábílónì.”

4. Wòlíì náà sì béèrè pé, “Kí ni wọ́n rí nínú ààfin rẹ?”“Wọ́n rí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin mi” ni ìdáhùn Heṣekáyà. “Kò sí ohun kankan nínú ìṣúra mi tí èmi kò fi hàn wọ́n.”

5. Lẹ́yìn náà ni Àìṣáyà sọ fún Heṣekáyà pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun:

6. Àsìkò ń bọ̀ nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin rẹ, àti ohun gbogbo tí àwọn baba rẹ ti kó jọ títí di ọjọ́ òní yóò di kíkólọ sí Bábílónì. Ohun kankan kò ní ṣẹ́kù ni Olúwa wí.

7. Àti díẹ̀ nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ, àwọn ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara rẹ tí a ó bí fún ọ ni a ó kó lọ, wọn yóò sì di ìwọ̀fà nínú ààfin ọba Bábílónì.”

8. “Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ dára,” ni èsì Heṣekáyà. Nítorí ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Àlàáfíà àti ààbò yóò wà ní Ìgbà ayé tèmi.”