orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ náà, obìnrin méjeyóò dì mọ́ ọkunrin kanyóò sì wí pé, “Àwa ó má a jẹ oúnjẹ ara waa ó sì pèsè aṣọ ara wa;sáà jẹ́ kí a má a fi orúkọ rẹ̀ pè wá.Mú ẹgan wá kúrò!”

Ẹ̀ka Olúwa Náà

2. Ní ọjọ́ náà, ẹ̀ka Olúwa yóò ní ẹwà àti ogo, èso ilẹ̀ náà yóò sì jẹ́ ìgbéraga àti ògo àwọn ti ó sálà ní Ísírẹ́lì.

3. Àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Síhónì, àwọn tí o kù ní Jérúsálẹ́mù, ni a ó pè ní mímọ́, orúkọ àwọn ẹni tí a kọ mọ́ àwọn alààyè ní Jérúsálẹ́mù.

4. Olúwa yóò wẹ ẹgbin àwọn obinrin Síhónì kúrò yóò sì fọ gbogbo àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ kúrò ní Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí ìná.

5. Lẹ́yìn náà, Olúwa yóò dá sorí òkè Síhónì àti sóríi gbogbo àwọn tí ó péjọ pọ̀ ṣíbẹ̀, kúrúkúrú èéfín ní ọ̀ṣán àti ìtànsán ọ̀wọ́ iná ní òru, lórí gbogbo ògo yìí ni ààbò yóò wà.

6. Èyí ni yóò jẹ́ ààbò àti òjìji kúrò lọ́wọ́ ooru ọ̀sán, àti ààbò òun ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìjì àti òjò.