orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Sí Kúṣì

1. Ègbé ni fún ìwọ ilẹ̀ tí ó kún fún ariwo ìyẹ́,ní àwọn ipadò Kúṣì,

2. tí ó rán àwọn ikọ̀ lórí òkunlórí omi nínú ọkọ̀-ọpọ́n tí a fi kóríko ṣe.Ẹ lọ, ẹ̀yin ikọ̀ tí ó yára,sí àwọn ènìyàn gíga tí àwọ̀-ara wọn jọ̀lọ̀,sí àwọn ènìyàn tí a ń bẹ̀rù káàkiri,orílẹ̀ èdè aláfojúdi alájèjì èdè,tí odò pín ilẹ̀ rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ.

3. Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ayé,tí ó ń gbé orílẹ̀ ayé,nígbà tí a bá gbé àṣíá kan ṣókè lórí òkè,ẹ ó rí i,nígbà tí a bá fun fèrè kanẹ ó gbọ́ ọ.

4. Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:“Èmi yóò dákẹ́ jẹ́ ẹ́, n ó sì máa wo òréréláti ibùgbé e mi wá,gẹ́gẹ́ bí ooru gbígbóná nínú ìtànsán òòrùn,gẹ́gẹ́ bí òjò-dídì ní àárin gbùngbùn ìkóórè.”

5. Nítorí, kí ìkóórè tó bẹ̀rẹ̀, nígbà tíìtànná kò sí mọ́,nígbà tí ìtànná di èso tí ó ń pọ́n bọ̀.Òun yóò sì fi ọ̀bẹ ìwẹgi gé àwọ ìsó tuntun kúrò,yóò sì gé àwọn ẹ̀ka tí ó ńgbilẹ̀ lulẹ̀ a sì kó wọn dànù.

6. Gbogbo wọn la ó fi lé àwọn jẹran jẹran ẹyẹlọ́wọ́ lórí òkèàti fún àwọn ẹranko búburú;àwọn ẹyẹ yóò fi wọ́n ṣoúnjẹ nínú ẹ̀ẹ̀rùnàti àwọn ẹranko búburú nígbà òjò.

7. Ní àkókò náà ni a ó mú ẹ̀bùn wá fún Olúwa àwọn ọmọ-ogunláti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gíga tí ẹran ara wọn jọ̀lọ̀,láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí a bẹ̀rù níbi gbogbo,orílẹ̀ èdè aláfojúdi àti alájèjì èdè,ilẹ̀ ẹni tí omi pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ—a ó mú àwọn ẹ̀bùn náà wá sí òkè Síónì, ibi tí orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbé wà.