orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 64 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì ṣọ̀kalẹ̀ wá,tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ!

2. Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jótí ó sì mú kí omi ó hó,ṣọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mímọ̀ fún àwọn ọ̀ta rẹkí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ!

3. Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí,o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ.

4. Láti ìgbà ìwásẹ̀ kò sí ẹni tí ó gbọ́ ríkò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ,kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ,tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.

5. Ìwọ a máa wá fún ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọnń fi ayọ̀ ṣe ohun tótọ́,tí ó rántí ọ̀nà rẹ.Ṣùgbọ́n nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀ sí wọn,inú bí ọ.Báwo ni a ó ṣe gbà wá là?

6. Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́,gbogbo òdodo wa sì dàbí èkíṣà ẹlẹ́gbin;gbogbo wa kákò bí ewé,àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò.

7. Ẹnikẹ́ni kò pe orúkọ rẹtàbí kí ó gbìyànjú láti dì ẹ́ mú;nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ fún waó sì jẹ́ kí àwa ṣòfò dànù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.

8. Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀, Olúwa, ìwọ ni Baba wa.Àwa ni amọ̀, ìwọ ni ọ̀mọ;gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

9. Má ṣe bínú kọjá ààlà, Ìwọ Olúwa:Má ṣe rántíi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé.Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà,nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa.

10. Àwọn Ìlú Mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀;Ṣíhónì pàápàá aṣálẹ̀ ni, Jérúsálẹ́mù ibi ìkọ̀sílẹ̀.

11. Tẹ́ḿpìlì Mímọ́ ológo wa, níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́,ni a ti fi iná sun,àti ohun gbogbo tí í ṣe ìṣúra wa ti dahoro.

12. Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí, Olúwa, ìwọó ha sì tún fara rẹ pamọ́ bí?Ìwọ ó ha dákẹ́ kí o sì fìyà jẹwá kọjá ààlà bí?