orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àìṣàn Heṣekáyà

1. Ní ọjọ́ náà ni Heṣekáyà ṣe àìṣàn dé ojú ikú. Wòlíì Àìṣáyà ọmọ Ámósì sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ohun tí Olúwa wí nìyìí: palẹ̀ iléẹ̀ rẹ mọ́, bí ó ti yẹ nítorí pé ìwọ yóò kú; ìwọ kì yóò dìde àìṣàn yìí.”

2. Heṣekáyà yí ojúu rẹ̀ sí ara ògiri, ó sì gba àdúrà sí Olúwa,

3. “Rántí, Ìwọ Olúwa, bí mo ti rìn pẹ̀lú òtítọ́ níwájúù rẹ, àti bí mo ti fi ọkàn dídúró ṣinṣin ṣe ohun tí ó dára ní ojúù rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Heṣekáyà sì ṣunkún kíkorò.

4. Lẹ́yìn náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Àìṣáyà wá pé

5. “Lọ kí o sì sọ fún Heṣekáyà pé, ‘Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Ọlọ́run Dáfídì baba rẹ sọ pé: Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ; Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀dógún kún ọjọ́ ayé rẹ.

6. Èmi yóò sì gba ìwọ àti ìlú yìí sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọba Áṣíríà. Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí.

7. “ ‘Èyí yìí ni àmì tí Olúwa fún ọ láti fi hàn wí pé Olúwa yóò mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ:

8. Èmi yóò mú òjìji òòrùn kí ó padà ṣẹ́yìn ní ìsísẹ̀ mẹ́wàá nínú èyí tí ó fi ṣọ̀kalẹ̀ ní ibi àtẹ̀gùn ti Áhásì.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni òòrùn padà ṣẹ́yìn ní ìsíṣẹ̀ mẹ́wàá sí ibi tí ó ti dé tẹ́lẹ̀.

9. Ìwé tí Heṣekáyà ọba Júdà kọ lẹ́yìn àìṣàn rẹ̀ nígbà tí ó ti gbádùn tán:

10. Èmi wí pé, “Ní àárin gbùngbùn ọjọ́ ayé mièmi ó ha kọjá lọ ní ibodè ikúkí a sì dùn mí ní àwọn ọdún mi tí ó ṣẹ́kù?”

11. Èmi wí pé, “Èmi kì yóò lè tún rí Olúwa mọ́,àni Olúwa, ní ilẹ̀ àwọn alààyè;èmi kì yóò lè síjú wo ọmọnìyàn mọ́,tàbí kí n wà pẹ̀lú àwọn tí ó sì ńgbe orílẹ̀ ayé báyìí.

12. Gẹ́gẹ́ bí àgọ́ olùṣọ́-àgùntàn, ilé mini a ti wó lulẹ̀ tí a sì gbà kúrò lọ́wọ́ọ̀ mi.Gẹ́gẹ́ bí ahunsọ mo ti ká ayé mi nílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni òun sì ti ké mi kúrò lára àṣà;ọ̀ṣán àti òru ni ìwọ ṣe òpin mi.

13. Èmi fi ṣùúrù dúró títí di àfẹ̀mọ́jú,ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí kìnnìún ó ti fọ́ gbogbo egungun mi;ọ̀ṣán àti òru ni ìwọ fi ṣe òpin mi.

14. Èmi sunkún gẹ́gẹ́ bí ìṣáré tàbí ìgún,Èmi pohùnréré gẹ́gẹ́ bí aṣọ̀fọ̀ àdàbà.Ojú mi rẹ̀wẹ̀sì gẹ́gẹ́ bí mo ti ń wo àwọn ọ̀run.Ìdààmú bámi; Ìwọ Olúwa, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi!”

15. Ṣùgbọ́n kí ni èmi lè sọ?Òun ti bá mi ṣọ̀rọ̀ àti pé òuntìkálára rẹ̀ ló ti ṣe èyí.Èmi yóò máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ minítorí ìpọ́njú ẹ̀mí mi yìí.

16. Olúwa, nípa nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn ń gbé;àti pé ẹ̀mí mi rí iyè nínú un wọn pẹ̀lú.Ìwọ dá ìlera mi padàkí o sì jẹ́ kí n wà láàyè

17. Nítòótọ́ fún àǹfààní mi nipé mo jẹ ìyà irú ìpọ́njú báyìí.Nínú ìfẹ́ rẹ ni o pamí mọ́kúrò nínú ọ̀gbun ìparun;ìwọ sì ti fi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.

18. Nítorí pé iṣà òkú kò le è yìn ọ́,ipò òkú kò le è kọ orin ìyìn rẹ;àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ sínú ọ̀gbunkò lè ní ìrètí fún òtítọ́ rẹ.

19. Alààyè, àwọn alààyè wọ́n ń yìn ọ́,gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe lónìí;àwọn baba sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa òtítọ́ rẹ.

20. Olúwa yóò gbà mí làbẹ́ẹ̀ ni àwa yóò sì kọrin pẹ̀lú ohun èlò olókunní gbogbo ọjọ́ ayé wanínú tẹ́ḿpìlì ti Olúwa.

21. Àìṣáyà ti sọ pé, “Pèṣè ìsù (ohun gbígbóná tí a dì mọ́ ojú egbò) kí o sì fi sí ojú oówo náà, òun yóò sì gbádùn.”

22. Heṣekáyà ti sọ pé, “Kí ni yóò jẹ́ àmì pé èmi yóò gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlì Olúwa?”