orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ègbé Ni Fún Àwọn Tí Ó Gbẹ́kẹ̀lé Éjíbítì

1. Ègbé ni fún àwọn tí ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ síÉjíbítì fún ìrànwọ́,tí wọn gbẹ́kẹ̀lée eṣintí wọ́n fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọnàti agbára ńlá àwọn ẹlẹ́ṣin wọn,ṣùgbọ́n ti wọn kò bojúwo Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì n nì,tàbí kí wọn wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Olúwa.

2. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ òun pẹ̀lú jẹ́ ọlọgbọ́n ó sì lè mú ìparun wá;òun kì í kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ.Òun yóò dìde sí ilé àwọn ìkà,àti sí àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún aṣebi.

3. Ṣùgbọ́n ènìyàn ṣáà ni àwọn ará Éjíbítìwọn kì í ṣe Ọlọ́run;ẹran ara ni àwọn ẹṣin wọn, kì í ṣe ẹ̀mí.Nígbà tí Olúwa bá na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde,ẹni náà tí ó ń ṣèrànwọ́ yóò kọṣẹ̀,ẹni náà tí à ń ràn lọ́wọ́ yóò ṣubú;àwọn méjèèjì yóò sì jùmọ̀ parun.

4. Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:“Gẹ́gẹ́ bí i kìnnìún ti í kéàní kìnnìún ńlá lórí ẹranànjẹ rẹ̀bí a tilẹ̀ rí ẹgbẹ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàntí a sì pè wọ́n papọ̀ láti kojúu rẹ̀,ẹ̀rù kò lè bà á pẹ̀lú igbe wọnakitiyan wọn kò sì lè dí i lọ́wọ́bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò sọ̀kalẹ̀ wáláti jagun lórí òkè Ṣíhónì àti lórí ibi gíga rẹ̀.

5. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹyẹ ti ń rábàbà lókè Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bò Jérúsálẹ́mù,Òun yóò dáàbò bò ó yóò sì tú u sílẹ̀Òun yóò ré e kọjá yóò sì gbà á sílẹ̀.”

6. Ẹ padà sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣọ̀tẹ̀ sí gidigidi, Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì.

7. Nítorí ní ọjọ́ náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan yín yóò kọ àwọn ère fàdákà àti wúrà tí ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ẹ yín ti ṣe.

8. “Ásíríà yóò ṣubú lọ́wọ́ idà kan tí kò ti ọwọ́ ènìyàn wá;idà tí kì í ṣe ti ẹ̀dá alààyè ni yóò pa wọ́n.Wọn yóò sì sá níwájú idà náààti àwọn ọmọkùnrin wọn ni a ó fún ní iṣẹ́ ipá ṣe.

9. Ibi gíga wọn ni yóò wó lulẹ̀ nítorí ìpayà;nípa ìrísí agbára ogun wọn, àwọnọ̀gágun wọn yóò wárìrì,”ni Olúwa wí,ẹni tí iná rẹ̀ ń bẹ ní Ṣíhónì,ẹni tí ìléru rẹ̀ wà ní Jérúsálẹ́mù.