orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Àmì Fún Mósè

1. Mósè dáhùn ó sì wí pé; “Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gbà mí gbọ́ ń kọ́? Tàbí tí wọn kò fi etí sílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ́nu mi, tí wọn sì wí pé, ‘Olúwa kò farahàn ọ́’?”

2. Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún un pé, “Kí ni ó wà ní ọwọ́ ọ̀ rẹ nnì?”Ó sì dáhùn pé, “ọ̀pá ni”

3. Olúwa sì sọ pé, “Sọ ọ̀pá náà sílẹ̀.”Mósè sì sọ ọ̀pá náà sílẹ̀, lọ́gán ni ọ̀pá náà di ejò, ó sì sá fún un.

4. Nígbà náà ni Ọlọ́run wá sọ fún un pé, “na ọwọ́ rẹ, kí o sì mú un ni ìrù.” Mósè sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mu ejò náà, ejò náà sì padà di ọ̀pá tí ó wà ni ọwọ́ rẹ̀.

5. Olúwa sì wí pé, “Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí wọn bá à le è gbàgbọ́ pé, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn: Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì, àtì Ọlọ́run Jákọ́bù; tí farahàn ọ́.”

6. Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ ìnú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀.” Mósè sì ti ọwọ́ rẹ̀ bọ inú aṣọ ní igbá àyá rẹ̀, ní ìgbá ti ó sì yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ ti dẹ́tẹ̀, ó sì ti funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.

7. Ó sì wí pé, “Nísinsìnyìí, fi ọwọ́ náà padà sí abẹ́ aṣọ ní igbá àyà rẹ.” Mósè sì ṣe bẹ́ẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ́ sípò bí àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ tó kù.

8. Ní ìgba náà ni Olúwa wí pé; “Bí wọn kò bá gbà ọ́ gbọ́ tàbí kọ ibi ara sí iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́, wọ́n le è ti ipaṣẹ̀ iṣẹ́ ìyanu kejì gbàgbọ́.

9. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gba àwọn méjèèjì wọ̀nyí gbọ́, tí wọn kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ, bu omi díẹ̀ láti inú odò Náílì kí o si dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀, omi tí ìwọ bù láti inú odò yìí yóò sì di ẹ̀jẹ̀.”

10. Mósè sì sọ fún Olúwa pé, “Èmi jẹ́ akọ́lòlò, èmi kì í ṣe ẹni tó lè sọ̀rọ̀ já gaara láti ìgbà àtijọ wá tàbí láti ìgbà ti o ti ń bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, mo jẹ́ ẹni ti ahọ́n rẹ̀ lọ́ tí ó sì ń lọ́ra àti sọ̀rọ̀.”

11. Olúwa sì sọ fún un pé, “Ta ni ó fún ènìyàn ni ẹnu? Ta ni ó mú un ya odi tàbí adití? Ta ni ó mú un ríran, tàbí mú un fọ́jú? Ǹjẹ́ kì í ṣe Èmi Olúwa?

12. Lọ nísinsìnyìí, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀. Èmi yóò sì kọ́ ọ ni ohun ti ìwọ yóò sọ.”

13. Mósè dáhùn ó wí pé, “Olúwa jọ̀wọ́ rán ẹlòmíràn láti lọ ṣe iṣẹ́ yìí.”

14. Ìbínú Ọlọ́run ru sókè sí Mósè, ó sì sọ pé, “Árónì ará Léfì arákùnrin rẹ ńkọ́? Mo mọ̀ pé ó lè sọ̀rọ̀ já gaara, ó ti wà ní ọ̀nà rẹ̀ báyìí láti pàdé e rẹ. Inú rẹ̀ yóò sì dùn ti ó bá rí ọ.

15. Ìwọ yóò sọ̀rọ̀ fún un, ìwọ yóò sì fi ọ̀rọ̀ sí i lẹ́nu: Èmi yóò ràn yín lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀. Èmi yóò kọ́ ọ yín ni ohun ti ẹ ó ṣe.

16. Òun yóò bá ọ sọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn, yóò sì dàbí i pé ẹnu un rẹ ni a gbà sọ ọ̀rọ̀ náà, ìwọ yóò sì dàbí Ọlọ́run ní iwájú rẹ̀.

17. Ṣùgbọ́n mú ọ̀pá yìí ni ọwọ́ rẹ kí ìwọ bá à lè fi ṣe àwọn iṣẹ́ àmì ìyanu pẹ̀lú rẹ̀.”

Mósè padà sí Éjíbítì

18. Mósè padà sí ọdọ Jẹ́tírò baba ìyàwó rẹ̀, ó sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí n padà tọ àwọn ènìyàn mi lọ ni ilẹ̀ Íjíbítí láti wò bóyá wọ́n sì wà láàyè ṣíbẹ̀.”Jẹ́tirò sì dáhùn, ó wí pé, “Má a lọ ni àlàáfíà.”

19. Nísínsìnyìí, Olúwa ti sọ fún Mósè ni ilẹ̀ Mídíánì pé, “Má a padà lọ sí Éjíbítì, nítorí àwọn ti ó fẹ́ pa ọ ti kú.”

20. Mósè mú ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó kó wọn lé orí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ padà sí Éjíbítì. Ó sì mú ọ̀pa Ọlọ́run sí ọwọ́ rẹ̀.

21. Olúwa sì sọ fún Mósè pé, “Ní ìgbà tí ìwọ bá padà sí Éjíbítì rí i pé ìwọ se iṣẹ́ ìyanu ni iwájú Fáráò. Èmi ti fún ọ lágbára láti ṣe é. Èmi yóò sì ṣé àyà rẹ̀ le, òun kì yóò jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà kí ó lọ.

22. Lẹ́yìn náà, kí o sọ fún Fáráò pé, ‘Èyí ni Olúwa sọ: Ísírẹ́lì ní àkọ́bí ọmọ mi ọkùnrin,

23. mo sọ fún ọ, “Jẹ́ kí ọmọ mi lọ, ki òun kí ó lè máa sìn mí.” Ṣùgbọ́n ìwọ kọ̀ láti jẹ́ kí ó lọ; nítorí náà, èmi yóò pa àkọ́bí ọmọ rẹ ọkùnrin.’ ”

24. Ní ọ̀nà ìrìnàjò rẹ, ni ibi tí wọ́n gbé sùn ní ilé-èrò ní alẹ́, Olúwa pàdé Mósè, ó sì fẹ́ láti pa á.

25. Ṣùgbọ́n Ṣípórà mú ọ̀bẹ òkúta mímú, ó sì kọ ọmọ rẹ̀ ní ilà abẹ́, ó si fi awọ rẹ̀ kan ẹṣẹ̀ Mósè. Ṣípórà sì wí pé, “Ọkọ ẹlẹ́jẹ̀ ni ìwọ jẹ́ sí mi.”

26. Nítorí náà Olúwa yọ̀ǹda rẹ láti ìgbà tí ó ti wí pé, “Ẹlẹ́jẹ̀ ni ìwọ í ṣe.” Èyí tó túmọ̀ sí àkọlà abẹ́.

27. Olúwa sì sọ fún Árónì pé, “Lọ sínú ihà láti lọ pàdé Mósè.” Ní ìgbà náà ni ó lọ pàdé Mósè ní orí òkè Ọlọ́run, ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.

28. Ní ìgbà náà ni Mósè sì sọ ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti sọ fún un àti nípa gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un láti ṣe ní iwájú Fáráò.

29. Mósè àti Árónì pe gbogbo àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ.

30. Árónì sọ ohun gbogbo tí Olúwa sọ fún Mósè fún wọn

31. Wọ́n sì gbàgbọ́. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Olúwa ti bẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wò àti pé Olúwa ti gbọ́ nípa ìpọ́njú wọn, wọ́n tẹríba, wọ́n sì sìn ín. Ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ amì náà níwájú àwọn ènìyàn náà.