orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bésálélì, Óhólíábù àti olúkúlùkù ọlọ́gbọ́n ẹni tí Olúwa tí fún ní ọgbọ́n àti agbára láti mọ bí a ti í ṣe gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ ni kí wọn ṣe iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ.”

2. Mósè sì pe Bésálélì àti Óhóábù àti gbogbo ọlọ́gbọ́n ènìyàn ẹni tí Olúwa ti fún ni agbára àti gbogbo ẹni tí ó fẹ́ láti wá sé iṣẹ́ náà.

3. Wọ́n gba gbogbo ọrẹ tí àwọn ọmọ Isirẹli ti mú wá lọ́wọ́ Mósè fún kíkọ́ ibi mímọ́ náà. Àwọn ènìyàn sì ń mú ọrẹ àtinúwá wá ní àràárọ̀.

4. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣẹ́ ọnà tí wọn ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀.

5. Mósè sì wí pé, “Àwọn ènìyàn mú púpọ̀ wá fún síṣe iṣẹ́ náà ju bi Olúwa ti pa á láṣẹ láti ṣe lọ.”

6. Mósè sì pàṣẹ, wọ́n sì rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo ibùdó: “Kí ọkùnrin tàbí obìnrin má ṣe ṣe ohun kankan bí ọrẹ fún ibi mímọ́ náà mọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni a dá àwọn ènìyàn lẹ́kun láti mú un wá sí i,

7. nítorí ohun tí wọ́n ti ni ti ju ohun tí wọn fẹ́ fi ṣe gbogbo iṣẹ́ náà lọ.

Àgọ́ náà

8. Gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin láàrin àwọn òṣìṣẹ́ ni wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú aṣọ títa mẹ́wàá ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, tí aṣọ aláró, ti elésèé àlukò àti ti òdòdó, pẹ̀lú àwọn kérúbù ṣe iṣẹ́ sí wọn nípa ọgbọ́n iṣẹ́ ọnà.

9. Gbogbo aṣọ títa náà jẹ́ ìwọ̀n kan ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlọ́gbọ̀n (28) ní gíga àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀.

10. Wọ́n sì pa aṣọ títa márùn-ún pọ̀ mọ̀ ara wọn, wọ́n sì tún ṣe bẹ́ẹ̀ sì márùn-ún tó kù.

11. Wọ́n sì pa ajábó aṣọ aláró ní etí aṣọ títa kan láti ìsẹ́tí rẹ̀ dé ibi òpin, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní o ṣe sí ìhà etí ikangun aṣọ títa kejì ní ibi òpin èkejì.

12. Àádọ́ta (50) ajábó ní ó pa lára aṣọ títa kan, àti àádọ́ta ajábó ni ó sì lò pa ní etí aṣọ títa tí ó wà ní ọ̀kánkán ara wọn.

13. Wọ́n sì ṣe àádọ́ta ìkọ́ wúrà, ó sì lò wọ́n láti fi kọ́ méjì aṣọ títa papọ̀ bẹ́ẹ̀ Àgọ́ náà sì di ọ̀kan.

14. Wọ́n ṣe aṣọ títa ti irun ewúrẹ́ fún Àgọ́ náà lórí Àgọ́ náà mọ́kànlá ni gbogbo rẹ̀ papọ̀.

15. Gbogbo aṣọ títa mọ́kọ̀ọ̀kànlá náà jẹ́ ìwọ̀n kan ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́, ní gígá àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀.

16. Wọ́n so àsọ títa márùn-ún pọ̀ mọ́ ara wọn, wọ́n sì tún so mẹ́fà tó kù mọ́ ara wọn.

17. Wọ́n sì pa àádọ́ta (50) ajábó sí ìsẹ́tí ìkángun aṣọ títa ní apá kan, wọ́n sì tún pa ajábó mìíràn sí ìsẹ́tí ìkángun aṣọ títa ní apá ibòmíràn.

18. Wọ́n ṣe àádọ́ta (50) ìkọ́ idẹ láti so Àgọ́ náà pọ̀ kí o lè jẹ́ ọ̀kan.

19. Wọ́n sì ṣe ìbòrí àwọ àgbò tí a rì ní pupa, àti ìbòrí màlúù odò lórí rẹ̀.

20. Wọ́n ṣe pákó igi kaṣíá tí ó dúró fún Àgọ́ náà.

21. Ọ̀kọ̀ọ̀kan pákó náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gíga àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀,

22. pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì tí ó kọjú sí ara wọn. Wọ́n ṣe gbogbo pákó Àgọ́ náà bí èyí.

23. Wọn ṣe ogún pákó sí ìhà gúsù Àgọ́ náà.

24. Wọ́n sì ṣe ogójì (40) fàdákà ihò ìtẹ̀bọ̀ lọ sí ìṣàlẹ̀ wọn ìtẹ̀bọ̀ méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìṣàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀.

25. Fún ìhà kejì, ìhà àríwá Àgọ́ náà, wọ́n ṣe ogún pákó

26. ogójì (40) fàdákà ihò ìtẹ̀bọ̀ méjì ní ìṣàlẹ̀ pákó kọ̀ọ̀kan.

27. Wọ́n ṣe pákó mẹ́fà sì ìkángun, ní ìkangun ìhà ìwọ̀ oòrùn Àgọ́ náà,

28. pákó méjì ni wọ́n ṣe sí igun Àgọ́ náà ní ìkangun.

29. Ní igun méjèèjì yìí, pákó méjì ni ó wà níbẹ láti ìdí dé orí rẹ̀ wọ́n sì kó wọ́n sí òrùka kan; méjèèjì rí bákan náà.

30. Wọ́n jẹ́ pákó mẹ́jọ àti fàdákà mẹ́rìn-lélógún ìhò ìtẹ̀bọ̀, méjì wà ní ìṣàlẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

31. Wọ́n sì tún ṣe ọ̀pá igi kaṣíà: márùn ún fún pakó ní ìhà kọ̀ọ̀kan Àgọ́ náà,

32. márùn-ún fún àwọn tí ó wà ní ìhà kejì, márùn-ún fún pákó tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ní ìkangun Àgọ́ náà.

33. Wọ́n sì ṣe ọ̀pá àárin tí yóò fi jáde láti ìkangun dé ìkangun ní àárin àwọn pákó náà.

34. Wọ́n bo àwọn pákó pẹ̀lú wúrà, wọ́n sì ṣe àwọn òrùkà wúrà láti gbá ọ̀pá náà mú. Wọ́n sì tún bo ọ̀pá náà pẹ̀lú wúrà.

35. Wọ́n ṣe aṣọ títa ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, wọ́n ṣe kérúbù si pẹ̀lú ọgbọ́n oníṣẹ́ ọnà.

36. Wọ́n sì ṣe òpó igi kasíá mẹ́rin fún-un wọ́n sì bò wọ́n pẹ̀lú wúrà. Wọ́n sì ṣe àwọn ìkọ́ wúrà fún wọn, wọ́n sì gba ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà mẹ́rin wọn.

37. Fún ẹnu ọ̀nà Àgọ́ náà wọ́n ṣe aṣọ títa ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkù, ti òdòdò àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára iṣẹ́ abẹ́rẹ́;

38. wọ́n sì ṣe òpó márùn-ún pẹ̀lú ìkọ́ wọn. Wọ́n bo orí àwọn òpó náà àti ìgbànú wọn pẹ̀lú wúrà, wọn sì ṣe ihò ìtẹ̀bọ̀ márùn-ún wọn ní idẹ.