orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àjọ Ìrékọjá

1. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì ni ilẹ̀ Éjíbítì pé,

2. “Osù yìí ni yóò jẹ́ osù àkọ́kọ́ fún yín oṣù àkọ́kọ́ nínú ọdún yín.

3. Sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì pé ni ọjọ́ kẹwàá oṣù yìí, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan yóò mú ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan fún ìdílé rẹ̀, ọ̀kan fún agbo ilé kọ̀ọ̀kan.

4. Bí ìdílé kan bá kéré jù fún odidi ọ̀dọ́ àgùntàn kan, kí wọn kí ó ṣe àjọpín ọ̀kan pẹ̀lú aládùúgbò wọn ti ó sun mọ́ wọn kí wọ́n lo iye ènìyàn ti wọn jẹ láti ṣe òdìnwọ̀n irú ọ̀dọ́ àgùntàn ti wọn yóò lò ní ìbámu pẹ̀lú ìwọ̀n ti ẹni kọ̀ọ̀kan lè jẹ.

5. Ẹran tí ìwọ yóò mú gbọdọ̀ jẹ́ akọ ọlọ́dùn kan tí kò lábùkù, ìwọ lè mú lára àgbò tàbí ewúrẹ́.

6. Ṣe ìtọ́jú wọn títí di ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì yóò pa ẹran náà ní àfẹ̀mójúmọ́.

7. Wọn yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóò fi kan ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àti òkè ẹnu ọ̀nà àbáwọlé níbi tí wọ́n bá ti jẹ ẹran ọ̀dọ́ àgùntàn náà.

8. Ní òru ọjọ́ kan náà, wọn yóò jẹ ẹran tí a ti fi iná sun, pẹ̀lú ewe ewúro àti búrẹ̀dì aláìwú.

9. Ẹ má ṣe jẹ ẹran náà ni tútù tàbí ní bíbọ̀ nínú omi, ṣùgbọ́n kí ẹ fi iná sun orí, ẹsẹ̀ àti àwọn nǹkan inú ẹran náà.

10. Ẹ má ṣe fi èyíkéyìí sílẹ̀ di òwúrọ̀ ọjọ̀ kejì, bí ó bá sẹ́ kú di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ẹ jó o níná.

11. Báyìí ni ẹ̀yìn yóò ṣe jẹ tí ẹ̀yin ti àmùrè ní ẹ̀gbẹ́ yín, sáńdà yín ní ẹsẹ̀ yín àti ọ̀pá yín ni ọwọ́ yín. Ẹ yára jẹ ẹ́, oúnjẹ àjọ ìrékọjá Olúwa ni.

12. “Ní òru ọjọ́ yìí kan náà ni èmi yóò la gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì kọjá, èmi yóò sì pa gbogbo àkọ́bí àtènìyàn, àtẹranko, èmi yóò mú ìdájọ́ wà sí orí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Éjíbítì. Èmi ni Olúwa.”

13. Ẹ̀jẹ̀ ni yóò jẹ́ àmì fún un yín ní àwọn ilé tí ẹ̀yin wà, nígbà tí èmi bá rí ẹ̀jẹ̀ náà, èmi yóò ré e yín kọjá. Ìyọnu kì yóò kàn yín nígbà tí èmi bá kọlu Éjíbítì láti pa wọ́n run.

14. “Èyí ni ọjọ́ tí ẹ̀yin yóò máa ṣe ìrántí láàrin àwọn ìran tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn ni ẹ̀yin yóò ti máa ṣe àjọ ọdún rẹ fún Olúwa; ìlànà tí yóò wà títí ayé.

15. Fún ọjọ́ méje ni ẹ̀yin yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, ẹ ó gbé ìwúkàrà kúrò ni ilé yín, nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú láti ọjọ́ kìn-ín-ní di ọjọ́ keje ni kí a yọ kúrò ni Ísírẹ́lì.

16. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí ẹ pe àpèjọ mímọ́, kí ẹ sì pe àpèjọ mímọ́ mìíràn ni ọjọ́ keje. Ẹ má ṣe se iṣẹ́ kankan ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, yàtọ̀ fún pípèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn láti jẹ: Èyí ni gbogbo ohun tí ẹ̀yin lè ṣe.

17. “Ẹ ṣe àpèjẹ àkàrà aláìwú, nítorí ọjọ́ yìí ni mo mú un yín jáde ni Éjíbítì. Ẹ ṣe àjọyọ̀ ọjọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí yóò wà títí ayé ní àwọn ìran tí ń bọ̀.

18. Búrẹ́dì ti kò ni ìwúkàrà ni ẹ̀yin yóò jẹ láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọ̀kànlélógún osù àkọ́kọ́.

19. Fún ọjọ́ méje ni ẹ kò gbọ́dọ́ ni ìwúkàrà nínú ilé yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó ni ìwúkàrà nínú ni a ó yọ kúrò ni àárin àwùjọ Ísírẹ́lì, ìbá à ṣe àlejò tàbí ẹni tí a bí ní ilẹ̀ náà.

20. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe. Ní ibikíbi tí ẹ̀yin bá ń gbé, kí ẹ̀yin kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà.”

21. Ní ìgbà náà ni Mósè pé gbogbo àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ jáde lọ, kí ẹ sì yan ọ̀dọ́ àgùntàn fún àwọn ìdílé yín, kí ẹ sí pa ẹran àjọ ìrékọjá Olúwa.

22. Ẹ̀yin yóò sì mú ìdí-ewé hísópù, ẹ tì í bọ inú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà nínú ọpọ́n kí ẹ sì fi kun òkè à bá wọ ẹnu ọ̀nà ilé yín àti ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìlẹ̀kùn yín. Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ jáde sí òde títí di òwúrọ̀.

23. Ní ìgbà tí Olúwa bá ń lọ káàkiri ní ilẹ̀ Éjíbítì láti kọlù wọn, yóò rí ẹ̀jẹ̀ ni òkè ẹnu ọ̀nà àti ni ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà ilé yín, yóò sì re ẹnu ọ̀nà ilé náà kọjá, kì yóò gba apanirun láàyè láti wọ inú ilé e yín láti kọlù yín.

24. “Ẹ pa ìlànà yìí mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ ó máa ṣe títí ayérayé láàrin yín àti àwọn ìran yín.

25. Nígbà tí ẹ̀yin bá de ilẹ̀ tí Olúwa yóò fi fún un yín bí òun ti ṣe ìlérí, ẹ máa kíyèsí àjọ yìí.

26. Ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ yín, ‘Kí ni ohun tí àjọ yìí túmọ̀ sí fún un yín?’

27. Ẹ sọ fún wọn ni ìgbà náà, ‘Ẹbọ ìrékọjá sí Olúwa ni, ẹni tí ó rékọjá ilé e wa ni ìgbà tí ó kọlu àwọn ara Éjíbítì. Tí ó si da wa sí nígbà ti ó pa àwọn ara Éjíbítì.’ ” Àwọn ènìyàn sì tẹríba láti sìn.

28. Àwọn Ísírẹ́lì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè àti Árónì.

29. Ní ọ̀gànjọ́ òru Olúwa kọlu gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Éjíbítì, láti orí àkọ́bí. Fáráò tí ó wà ní orí ìtẹ́ títí dé orí àkọ́bí ẹlẹ́wọ̀n tí ó wà nínú ẹ̀wọ̀n àti àkọ́bí ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú.

30. Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀ àti gbogbo àwọn ara Éjíbítì dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, igbe ẹkún ńlá sì gba gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, nítorí kò sí ilé kan tí ó yọ sílẹ̀ tí ènìyàn kan kò ti kú.

Ìjáde Lọ

31. Fáráò sì ránṣẹ́ pe Mósè àti Árónì ní òru, ó sì wí pé, “Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì! Ẹ lọ láti sin Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹ ti béèrè.

32. Ẹ kó agbo àgùntàn yín àti agbo màlúù yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti sọ, kí ẹ sì máa lọ, kí ẹ sì súre fún mi.”

33. Àwọn ara Éjíbítì ń rọ àwọn ènìyàn náà láti yára máa lọ kúrò ní ilẹ̀ wọn. Wọ́n wí pé, “Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ gbogbo wa ni yóò kú!”

34. Àwọn ènìyàn náà sì mú ìyẹ̀fun pípò kí wọn tó fi ìwúkàrà sí i, wọ́n gbe le èjìká wọn nínú ọpọ́n tí wọ́n ti fi aṣọ dì.

35. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mósè ti sọ fún wọn. Wọ́n sì béèrè fún ohun èlò fàdákà àti wúrà àti fún aṣọ pẹ̀lú.

36. Olúwa ti mú kí àwọn ènìyàn yìí rí ojú rere àwọn ará Éjíbítì wọ́n sì fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún, wọ́n sì ko ẹrù àwọn ará Éjíbítì.

37. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì rìn láti Rámẹ́sẹ́sì lọ sí Sukoti. Àwọn ọkùnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rìn tó ọ̀gbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ni iye láì ka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.

38. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn ni ó bá wọ́n lọ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ọ̀sìn, agbo àgùntàn àti agbo màlúù.

39. Pẹ̀lú ìyẹ̀fun tí kò ní ìwúkàrà nínú tí wọ́n gbé jáde láti Éjíbítì wá ní wọ́n fi ṣe àkàrà aláìwú. Ìyẹ̀fun náà kò ni ìwúkàrà nínú nítorí a lé wọn jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wọn kò si rí ààyè láti tọ́jú oúnjẹ fún ara wọn.

40. Iye ọdun ti àwọn ará Ísírẹ́lì gbé ní ilẹ̀ Éjíbítì jẹ́ irínwó ọdún ó lé ọgbọ̀n (430).

41. Ní ọjọ́ ti irínwó ọdún ó le ọgbọ̀n (430) pé gan an ni gbogbo ènìyàn jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì.

42. Nítorí pé, Olúwa ṣe àìsùn ni òru ọjọ́ náà láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, ní òru yìí ni gbogbo Ísírẹ́lì ní láti máa se àìsùn láti fi bu ọlá fún Olúwa títí di àwọn ìran tí ń bọ̀.

Òfin Àjọ Ìrékọjá

43. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé, “Ìwọ̀n yìí ni àwọn òfin fún àjọ ìrékọjá:“Àjòjì kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀.

44. Ẹrú tí ẹ̀yin bá rà lè jẹ́ nínú rẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ̀yin bá ti kọ ọ́ ní ilà,

45. Ṣùgbọ́n àlejò àti alágbàṣe kò ni jẹ nínú rẹ̀.

46. “Nínú ilé ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ ẹ́; ẹ kò gbọdọ̀ mú èyíkéyìí nínú ẹran náà jáde kúrò nínú ilé. Ẹ má ṣe ṣẹ́ ọ̀kankan nínú egungun rẹ̀.

47. Gbogbo àjọ Ísírẹ́lì ni ó gbọdọ̀ ṣe àjọyọ̀ ọ rẹ̀.

48. “Àjòjì ti ó bá ń gbé ní àárin yín ti ó bá fẹ́ kópa nínú àjọ ìrékọjá Olúwa, ni o gbọdọ̀ kọ gbogbo àwọn ọmọkùnrin ilé rẹ̀ ní ìlà; ní ìgbà náà ni ó lè kó ipa gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí a bí ní ilẹ̀ náà. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí a kò bá kọ ní ìlà, wọ́n kò ni jẹ ni ara rẹ̀.

49. Òfin yìí kan náà ni ó mú àwọn ọmọ tí a bí ni ilẹ̀ náà àti àwọn àlejò tí ń gbé ní àárin yín.”

50. Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè àti Árónì.

51. Àti pé ní ọjọ́ náà gan-an ni Olúwa mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì gẹ́gẹ́ bí ìpín ìpín wọn.