orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìbí Mósè

1. Ó sì ṣe, ọkùnrin ará ilé Léfì kan fẹ́ ọmọbìnrin ará Léfì kan ni ìyàwó.

2. Obìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Nígbà tí ó rí í pé ọmọ náà rẹwà, ó gbé ọmọ náà pamọ́ fún oṣù mẹ́ta.

3. Ṣùgbọ́n nígbà tí kò le è gbé e pamọ́ mọ́, ó fi ewé pápírúsì hun apẹ̀rẹ̀, ó sì fi ọ̀dà ati òjé igi sán apẹ̀rẹ̀ náà. Ó sì tẹ́ ọmọ náà sínú rẹ̀, ó sì gbe é sí inú esùnsún ni etí odò Náílì.

4. Arábìnrin rẹ̀ dúró ni òkèèrè láti wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà.

5. Nígbà náà ni ọmọbìnrin Fáráò sọ̀kalẹ̀ wá sí etí odò Náílì láti wẹ̀, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ń rìn ni etí bèbè odò. Ó sì ri apẹ̀rẹ̀ náà ni àárin esùnsún, ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin kan láti lọ gbé e wá,

6. ó sí i, ó sì rí ọmọ náà. Ọmọ náà ń sunkún, àánú ọmọ náà sì ṣe é. Ó wí pé “Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Hébérù ni èyí.”

7. Nígbà náà ni arábìnrin rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin Fáráò pé “Ṣé kí èmi lọ wá ọ̀kan lára àwọn obìnrin Hébérù wá fún ọ láti bá ọ tọ́jú ọmọ náà?”

8. Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni; lọ.” Arábìnrin náà sì lọ, ó sì pe ìyá ọmọ náà wá,

9. Ọmọbìnrin Fáráò sì wí fún un pé, “Gba ọmọ yìí kí o sì tọ́jú rẹ̀ fún mi, èmi yóò san owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ fún ọ” Ọmọbìnrin náà sì gbé ọmọ náà lọ, ó sì tọ́jú rẹ̀.

10. Nígbà tí ọmọ náà sì dàgbà, ó mú un tọ ọmọbìnrin Fáráò wá, ó sì di ọmọ rẹ̀. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Mósè, ó wí pé “Nítorí tí mo fà á jáde nínú omi.”

Mósè Sálọ Sí Mídíánì:

11. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Mósè ti dàgbà, ó jáde lọ sí ibi ti àwọn ènìyàn rẹ̀ wà, ó ń wò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ líle wọn, O ri ará Éjíbítì tí ń lu ará Ébérù, ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.

12. Ó wo ìhín, ó wo ọ̀hún, nígbà tí kò rí ẹnìkankan, ni ó bá pa ará Éjíbítì náà, ó sì bò ó mọ́ inú iyanrìn.

13. Ní ọjọ́ kejì, ó jáde lọ, ó rí àwọn ará Hébérù méjì tí wọ́n ń jà. Ó béèrè lọ́wọ́ èyí tí ó jẹ̀bi pé “Èéṣe tí ìwọ fi ń lu Hébérù arákùnrin rẹ?”

14. Ọkùnrin náà sì dáhùn pé “Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídájọ́ lórí wa? Ṣé o fẹ́ pa mí bí o ṣe pa ará Éjíbítì?” Nígbà náà ni ẹ̀rù ba Mósè, ó rò nínú ara rẹ̀ pé “ó ní láti jẹ́ wí pé ohun tí mo ṣe yìí ti di mímọ̀.”

15. Nígbà ti Fáráò sì gbọ́ nípa èyí, ó wá ọ̀nà láti pa Mósè, ṣùgbọ́n Mósè sá kúrò ní àrọ́wọ́tó o Fáráò, ó lọ sí Mídíánì láti máa gbé, nígbà tí ó dé bẹ̀, ó jókòó ni ẹ̀bá a kànga kan.

16. Ó sì ṣe, àlùfáà Mídíánì kan ni àwọn ọmọbìnrin méje, wọn sì wá láti pọn omi kún ọpọ́n ìmumi fún ẹran ọ̀sìn baba wọn.

17. Àwọn darandaran kán wá, wọ́n sì lé wọn sẹ́yìn, ṣùgbọ́n Mósè dìde láti gbà wọ́n sílẹ̀ àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fún ẹran wọn ní omi.

18. Nígbà ti àwọn ọmọbìnrin náà padà dé ọ̀dọ̀ Rúẹ́lì baba wọn, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé “Èéṣe tí ẹ̀yin fi tètè dé ni òní?”

19. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ará Éjíbítì kan ni ó gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn darandaran, ó tilẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti fa omi àti láti fún agbo ẹran ní omi.”

20. Ó sọ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, “Níbo ni ó wà? Èéṣe ti ẹ fi fi ọkùnrin náà sílẹ̀? Ẹ pè é wá jẹun.”

21. Mósè gbà láti dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin náà, ẹni tí o fi Sípórà, ọmọbìnrin rẹ̀ fún Mósè láti fi ṣe aya.

22. Ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Gésómù, ó wí pé “Èmi ń ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.”

23. Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ọba Éjíbítì kú. Àwọn ará Ísírẹ́lì ń kérora ní oko ẹrú wọn, wọ́n ń ké fún ìrànlọ́wọ́ nítorí oko ẹrú tí wọ́n wà, igbe wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

24. Ọlọ́run gbọ́ igbe wọn, ó sì rántí Májẹ̀mu rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù, Ísáákì àti pẹ̀lú Jákọ́bù.

25. Nítorí náà, Ọlọ́run bojú wo àwọn ará Ísírẹ́lì, Ó sì wà láti gbà wọ́n sílẹ̀.