orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Mósè pẹ́ kí ó tó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè wá, wọn péjọ yí Árónì ká, wọ́n sì wí pé, “Wá, dá òrìṣà tí yóò máa ṣáájú wa fún wa. Bí ó ṣe ti Mósè tí ó mú wa jáde láti Éjíbítì wá, àwa kò mọ́ ohun tí ó ti sẹlẹ̀ sí i.”

2. Árónì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ bọ́ òrùka wúrà tí ó wà ní etí àwọn ìyàwò yín, tí àwọn ọmọkùnrin yín, àti tí àwọn ọmọbìnrin yín, kí ẹ sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi.”

3. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ènìyàn bọ́ òrùka etí wọn, wọn sì kó wọn wá fún Árónì.

4. Ó sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ó sì fi ṣe ohun ọnà fínfin, ó sì dàá ní àwòrán ẹgbọrọ màlúù. Nígbà náà ni wọn wí pé, “Ísírẹ́lì, wọ̀nyí ni òrìṣà, ti ó mú un yín jáde wá láti Éjíbítì.”

5. Nígbà ti Árónì rí èyí, ó kọ́ pẹpẹ kan níwájú ẹgbọrọ màlúù náà, ó sì kéde pé, “Lọ́la ni àjọyọ̀ sí Olúwa.”

6. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn dìde ní kùtùkùtù ọjọ́ kejì, wọ́n sì rúbọ síṣun, wọ́n sì mú ẹbọ àlàáfíà wá. Lẹ́yìn náà wọ́n jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde láti ṣeré.

7. Olúwa sì wí fún Mósè pé, “Ṣọ̀kalẹ̀ lọ, nítorí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú gòkè wá láti Éjíbítì, wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀.

8. Wọ́n ti yára láti yípadà kúrò nínú ohun ti mo pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì ti dá ère ẹ̀gbọrọ màlúù fún ara wọn. Wọ́n ti foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì ti rúbọ sí i, wọ́n sì ti sọ pé, ‘Ísíirẹ́lì wọ̀nyí ní òrìṣà tí ó mú un yín jáde láti Éjíbítì wá.’ ”

9. Olúwa wí fún Mósè pé, “Èmi ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, wọ́n sì jẹ́ ọlọ́rùn líle ènìyàn.

10. Ǹjẹ́ nísinsin yìí fi mí sílẹ̀, nítorí kí ìbínú mi lè gbòná sí wọn, kí èmi sì lè pa wọ́n run. Nígbà náà ni èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá.”

11. Ṣùgbọ́n Mósè kígbe fún ojú rere Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa, è é ṣe tí ìbínú rẹ yóò ṣe gbóná sí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú jáde láti Éjíbítì wá pẹ̀lú agbára ńlá àti ọwọ́ agbára?

12. È é ṣe tí àwọn ará Éjíbítì yóò ṣe wí pé, ‘Nítorí ibi ni ó ṣe mọ̀ ọ́ mọ̀ mú wọn jáde, láti pa wọ́n ní orí òkè àti láti gbá wọn kúrò lórí ayé’? Yípadà kúrò nínú ìbínú rẹ tí ó múná, yí ọkàn padà, kí o má sì ṣe mú ìparun wá sórí àwọn ènìyàn rẹ.

13. Rántí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Ábúráhámù, Ísáákì àti Ísírẹ́lì, ẹni tí ìwọ búra fún fúnraàrẹ: ‘tí o wí fún wọn pé, èmi yóò mú irú ọmọ rẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, èmi yóò sì fún irú ọmọ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ tí mo ti pinnu fún wọn, yóò sì jẹ́ ogún ìní wọn láéláé.’ ”

14. Nígbà náà ni Olúwa yí ọkàn padà, kò sì mú ìparun náà tí ó sọ wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́.

15. Mósè sì yípadà, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà pẹ̀lú okuta wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀. Wọ́n kọ ìwé síhà méjèèjì, iwájú àti ẹ̀yin.

16. Iṣẹ́ Ọlọ́run sì ni wàláà náà; ìkọ̀wé náà jẹ́ ìkọ̀wé Ọlọ́run, a fín-in sára àwọn òkúta wàláà náà.

17. Nígbà tí Jóṣúà gbọ́ ariwo àwọn ènìyàn tí wọ́n ń kígbe, ó sọ fún Mósè pé, “Ariwo ogun wà nínú àgọ́.”

18. Mósè dáhùn pé:“Kì í ṣe ariwo fún ìṣẹ́gun,kì í ṣe ariwo fún aṣẹ́gun;ohùn àwọn tí ń kọrin ni mo gbọ́.”

19. Nígbà tí Mósè dé àgọ́, ó sì rí ẹgbọrọ màlúù náà àti ijó, ìbínú rẹ gbóná, ó sì ju pálí ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́ẹ́wẹ́ ní ìṣàlẹ̀ òkè náà.

20. Ó sì gbé ẹgbọrọ màlúù tí wọ́n ṣe, ó sì fi iná jó wọn; ó sì lọ̀ wọ́n kúnná, ó dà á sínú omi, ó sì mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mu ún,

21. Mósè sọ fún Árónì pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe sí ọ, tí ìwọ ṣe mú wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí?”

22. Árónì dáhùn wí pé, “Má ṣe bínú Olúwa mi. Ìwọ mọ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe burú tó.

23. Wọ́n sọ fún mi pé, ‘Ṣe òrìsà fún wa, tí yóò máa ṣáájú wa. Bí ó ṣe ti Mósè ẹni tí ó mú wa jáde láti Éjíbítì wá àwa kò mọ ohun tí ó sẹlẹ̀ sí i.’

24. Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní òrùka wúrà, kí ó bọ́ ọ wá.’ Nígbà náà ni wọ́n fún mi ní wúrà, mo sì jù ú sínú iná, a sì fi ṣe ẹgbọrọ màlúù yìí!”

25. Mósè rí i pé àwọn ènìyàn náà kòṣe e ṣàkóso àti pé Árónì ti sọ wọ́n di aláìlákóṣo láàrin àwọn ọ̀ta tí ó dìde sí wọn.

26. Bẹ́ẹ̀ ni ó dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́, ó sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà fún Olúwa, kí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ará Léfì sì péjọ yí i ká.

27. Nígbà náà ni ó sọ fún wọn pé, “Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run Isirẹ́lì, wí pé: ‘Kí olúkúlùkù ọkùnrin kí ó kọ idà rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Ẹ lọ padà, kí ẹ jà láti àgọ́ kan dé òmíràn, olúkúlùkù kí ó pa arákùnrin rẹ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti aládúgbò rẹ.’ ”

28. Àwọn ará Léfì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mósè ṣe pàṣẹ, àti ní ọjọ́ náà àwọn tí ó kù tó ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ènìyàn.

29. Nígbà náà ni Mósè wí pé, “Ẹ ti ya ara yín sọ́tọ̀ fún Olúwa lónìí, nítorí ìwọ ti dìde sí àwọn ọmọ rẹ àti arákùnrin rẹ, ó sì ti bùkún fún ọ lónìí.”

30. Ní ọjọ́ kejì Mósè sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ̀yin ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó pọ̀. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi yóò gòkè lọ bá Olúwa; bóyá èmi lè se ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.”

31. Bẹ́ẹ̀ ni Mósè padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, “Yé, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí àwọn ènìyàn ti dá yìí! Wọ́n ti ṣe òrìsà wúrà fún ara wọn.

32. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jìn wọ́n ṣùgbọ́n tí kò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, pa oruko mi rẹ́ kúrò nínú ìwé tí ìwọ ti kọ.”

33. Olúwa dá Mósè lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi, èmi yóò pa á rẹ́ kúrò nínú ìwé mi.

34. Ǹjẹ́ nísinsin yìí lọ, máa darí àwọn ènìyàn yìí lọ sí ibi ti mo sọ, angẹ́lì mi yóò sì máa lọ ṣáájú yín. Ìgbà ń bọ̀ fún mi tì èmi yóò ṣe ìbẹ̀wò, èmi yóò fi yà jẹ wọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

35. Olúwa sì yọ àwọn ènìyàn náà lẹ́nu, pẹ̀lú arun nítorí ohun tí wọ́n se ni ti ẹgbọrọ màlúù tí Árónì ṣe.