orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìyàsímímọ́ Àwọn Àlùfáà.

1. “Èyí ni ohun tí ìwọ yóò ṣe láti yà wọ́n sí mímọ́, nítorí kí wọn lè máa àti láti máa sìn se àlùfáà fún mi: Mú ọ̀dọ́ akọ màlúù kan àti àgbò méjì tí kò ní àbùkù.

2. Láti ara ìyẹ̀fun aláìwú dídùn, ṣe àkàrà àti àkàrà tí a pò pẹ̀lú òróró, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláìwú tí a da òróró sí.

3. Ìwọ yóò sì kó wọn sínú àpẹ̀rẹ̀ kan, ìwọ yóò sì mú wọn wà nínú apẹ̀rẹ̀ náà—papọ̀ pẹ̀lú akọ màlúù àti àgbò méjì náà.

4. Nígbà náà ni ìwò yóò mú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, ìwọ yóò sì fi omi wẹ̀ wọ́n.

5. Ìwọ yóò sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ Árónì, àti aṣọ ìgúnwà éfódì, àti éfódì, àti ìgbàyà, kí ó sì fi onírúurú-ọnà ọ̀já ẹ̀wù èfòdì dìí.

6. Ìwọ yóò sì fí fìlà dé e ní orí, ìwọ yóò sì se adé mímọ́ sára fìlà náà.

7. Nígbà náà ni ìwọ yóò sì mú òrórò ìtasórí, ìwọ yóò sì yà á sí mímọ́ nípa dída òróró sí i ní orí.

8. Ìwọ yóò sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ ìwọ yóò sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n

9. ìwọ yóò sì fi fìlà dé wọn ni orí. Nígbà náà fi ọ̀já àmùrè di Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀. Iṣẹ́ àlùfáà yóò máa jẹ́ ti wọn ní ìlànà títí ayé. Báyìí ni ìwọ yóò sì ya Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́.

10. “Ìwọ yóò sì mú akọ màlúù wá ṣíwájú àgọ́ àjọ, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì fi ọwọ́ lé wọn ní orí.

11. Ìwọ yóò sì pa àwọn akọ màlúù náà níwájú Olúwa ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ.

12. Ìwọ yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ìka rẹ tọ́ ọ sára ìwo pẹpẹ náà, kí o sì da gbogbo ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ náà.

13. Kí o mú gbogbo ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀ àti ìwé méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ.

14. Ṣùgbọ́n fi iná sun ẹran akọ màlúù, awọ rẹ̀ àti ìgbẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn òde. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.

15. “Ìwọ yóò sì mú àgbò kan, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì fi ọwọ́ wọn lé àgbò náà lórí.

16. Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò wọ́n-ọn sí pẹpẹ ni gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

17. Ìwọ yóò sì gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, ìwọ yóò sì fọ inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tò wọ́n pẹ̀lú orí rẹ̀ lé ara wọn.

18. Nígbà náà ni ìwọ yóò sun àgbò náà lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ni sí Olúwa, olóòórùn dídùn ni, ẹbọ ti a fi iná se sí Olúwa ni.

19. “Ìwọ yóò mú àgbò kejì, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò fi ọwọ́ wọn lé àgbò náà lórí.

20. Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn. Ìwọ yóò sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sí pẹpẹ lórí àti ní gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

21. Ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ àti nínú òróró ìtasórí, ìwọ yóò sì wọ́n-ọn sára Árónì àti sára aṣọ rẹ̀, sára àwọn ọmọ rẹ àti sára aṣọ wọn. Nígbà náà ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti aṣọ wọn yóò di mímọ́.

22. “Ìwọ yóò mú lára ọ̀rá àgbò náà, ìrù tí ó lọ́ràá, ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí ti ó bo ẹ̀dọ̀, iwe méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn àti itan ọ̀tún. (Èyí ni àgbò fún ìyàsímímọ́).

23. Láti inú apẹ̀rẹ̀ ìṣù àkàrà aláìwú, èyí tí ó wà níwájú Olúwa, mú ìṣù kan, àkàrà tí a fi òróró dín àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan.

24. Ìwọ yóò fi gbogbo rẹ̀ lé Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa.

25. Nígbà náà ni ìwọ yóò sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ pẹ̀lú ẹbọ sísun fún òórùn dídùn níwájú Olúwa, ẹbọ ti a fi iná sun sí Olúwa.

26. Ìwọ yóò sì mú igẹ̀ àgbò ìyàsímímọ́ Árónì, ìwọ yóò si fín-in ni ẹbọ fínfín níwájú Olúwa; ìpín tìrẹ ni èyí.

27. “Ìwọ yóò sì yà igẹ̀ ẹbọ fínfìn náà sí mímọ́, àti ìtan ẹbọ àgbésọ-sókè, tí pa fi tí a sì gbésọ-sókè nínú àgbò ìyàsímímọ̀ náà, àní nínú èyí tíí ṣe Árónì àti nínú èyí tí ì ṣe tí àwọn ọmọ rẹ̀.

28. Èyí ni yóò sì máa se ìpín ti Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà gbogbo. Nítorí ẹbọ à-gbé-sọ-sókè ni ẹbọ tí yóò sìṣe èyí ni ẹbọ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò máa se sí Olúwa láti inú ẹbọ àlàáfíà wọn.

29. “Asọ mímọ́ Árónì yóò jẹ́ ti irú àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí kí a lè máa fi òróró yàn wọ́n kí a sì lè máa yà wọ́n sì mímọ́.

30. Ọmọ rẹ̀ tí ó bá jẹ àlùfáà ní ipò rẹ̀, tí ó bá wọ̀ yóò máa sì wá sí àgọ́ àjọ láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́, yóò sì máa wọ̀ wọ́n ní ọjọ́ méje.

31. “Ìwọ yóò sì mú àgbò fún ìyàsímímọ́, ìwọ yóò sì bọ ẹran wá ní ibi mímọ́ kan.

32. Ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ ni Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò ti jẹ ẹran àgbò náà àti àkàrà náà tí ó wà nínú apẹ̀rẹ̀.

33. Wọn yóò sì jẹ nǹkan wọ̀nyí èyí tí a fi se ètùtù náà fún ìyàsímímọ́ àti ìsọdimímọ́ wọn. Ṣùgbọ́n kò ní sí ẹlòmíràn ti yóò le è jẹ wọ́n, nítorí pé mímọ́ ni.

34. Bí ohun kan nínú ẹran àgbò ìyàsímímọ́ tàbí nínú àkàrà náà bá kù di òwúrọ̀, nígbà náà ni kí ìwọ fi iná sun wọn. A kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́, nítorí mímọ́ ni.

35. “Bàyìí ni ìwọ yóò sìṣe fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ bí ohun gbogbo ti mo paláṣẹ fún ọ, ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi yà wọ́n sí mímọ́.

36. Ìwọ yóò sì máa pa akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ní ojoojúmọ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù. Ìwọ yóò sì wẹ pẹpẹ mọ́ nípa ṣíṣe ètùtù fún-un, ìwọ yóò sì ta òróró sí i láti sọ ọ́ dí mímọ́.

37. Ní ọjọ́ méje ni ìwọ yóò ṣe ètùtù sí pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì sọ ọ́ di mímọ́. Nígbà náà ni pẹpẹ náà yóò jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohúnkóhun tí ó bá fi ọwọ́ kàn-án yóò jẹ́ mímọ́.

38. “Èyí ni ìwọ yóò máa fi rúbọ ní orí pẹpẹ náà: Òdọ́ àgùntàn méjì ọlọ́dún kan ni ojoojúmọ́ láéláé.

39. Odọ àgùntàn kan ni ìwọ yóò fi rúbọ ní òwúrọ̀ àti ọ̀dọ́ Àgùntàn èkejì ní àṣálẹ̀.

40. Pẹ̀lú ọ̀dọ́ àgùntàn ti àkọ́kọ́ rúbọ ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n fulawa dídára tí a fi ìdámẹ́rin hínì òróró lára ólífì tí a gún, àti ìdámẹ́rin hínì wáìnì bí ẹbọ mímu.

41. Ọ̀dọ́ àgùntàn kejì ni kí ìwọ ki o pa rúbọ ní àṣálẹ̀ ìwọ yóò sì ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu bí ti òwúrọ̀ fún òórun dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe ni sí Olúwa.

42. “Fún ìrandíran tó ń bọ̀, ni ẹ ó máa ṣe ẹbọ sísun nígbà gbogbo ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ níwájú Olúwa. Níbẹ̀ èmi yóò pàdé yín, èmi yóò sì bá a yín sọ̀rò;

43. níbẹ̀ sì tún ni èmi yóò pàdé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, a ó sì fi ògo mi ya àgọ́ náà sí mímọ́.

44. “Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ya àgọ́ àjọ náà sí mímọ́ àti pẹpẹ náà, èmi yóò sì ya Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ bí àlùfáà fún mi.

45. Nígbà náà ni èmi yóò máa gbé láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èmi yóò sì máa ṣe Ọlọ́run wọn.

46. Wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, nítorí kí èmi lè máa gbé àárin wọn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.