orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àgọ́ Náà.

1. “Ṣe àgọ́ náà pẹ̀lú aṣọ títa mẹ́wàá, aṣọ ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ àti àsọ aláró, ti elésèé àlùkò, àti ti òdòdó, pẹ̀lú àwọn kérúbù ni kí ó ṣe iṣẹ́ ọlọ́nà sí wọn.

2. Gbogbo aṣọ títa náà ni kí ó jẹ́ déédé ìgbọ̀nwọ́ mèjídínlọ́gbọ̀n ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ni fífẹ̀.

3. Asọ títa márùn ún ni kí o papọ̀ mọ́ ara wọn, kí o sì ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú márùn-ún tókù.

4. Ìwọ yóò siṣe ojábó aṣọ aláró sí aṣọ títọ́ kan láti ìsẹ́tí rẹ̀ wá nibi ìsopọ̀, àti bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìwọ yóò ṣe ni etí ìkangun aṣọ títa kejì, ni ibi ìsopọ̀ kejì.

5. Ṣe àádọ́ta (50) ọ̀jábó sí aṣọ títa kan, àádọ́ta ojábó (30) ni kí ó ṣe sí etí aṣọ títa ni ìbò mìíràn, pẹ̀lú ọ̀jábó ní ọ̀kánkán ara wọn.

6. Nígbà náà ṣe àádọ́ta (50) ìkọ́ yóòkù kí o sì lò wọ́n láti fi fa àwọn aṣọ títa náà papọ̀, nítorí náà àgọ́ náà yóò jẹ́ ọ̀kan.

7. “Ṣe aṣọ títa irun ewúrẹ́ láti fi ṣe ibò sórí àgọ́ náà—kí ó jẹ́ mọ́kànlá papọ̀.

8. Gbogbo aṣọ títa mọ̀kánlà náà gbọdọ̀ jẹ́ déédé-ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀wọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀.

9. Aṣọ títa márùn ún ni kí ó papọ̀ mọ́ ara wọn sí apá kan àti mẹ́fà tókù sí apá ọ̀tọ̀. Yí aṣọ títa kẹfà po sí méjì níwájú àgọ́ náà.

10. Ṣe àádọ́ta ọ̀jábó sí etí òpin aṣọ títa ni apá kan, kí o sì tún ṣe é sí etí òpin aṣọ títa sí apá kejì.

11. Nígbà náà ṣe àádọ́ta ìkọ́ idẹ kí o sì kó wọn sínú ọ̀jábó láti fi ṣo àgọ́ náà pọ̀ kí ó lè jẹ́ ọ̀kan.

12. Àti ìyóòkù tí ó kù nínú aṣọ títa àgọ́ náà, ìdajì aṣọ títa tí ó kù, yóò rọ̀ sórí ẹ̀yìn àgọ́ náà.

13. Asọ títa àgọ́ náà yóò jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan gígùn ní ìhà méjèèjì; Èyí tí ó kù yóò rọ̀ sórí ìhà àgọ́ náà láti fi bò ó.

14. Ṣe ìbòrí awọ àgbò tí a ṣe ní pupa fún àgọ́ náà, kí ó sì se awọ ewúrẹ́ sórí rẹ̀.

15. “Ṣe pálọ̀ àgọ́ náà pẹ̀lú igi kasia kí ó dúró dáadáa.

16. Kí pákó kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀.

17. Pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì ni kí ó kọjú sí ara wọn. Ṣe gbogbo àwọn pákó àgọ́ náà bí èyí.

18. Ṣe ogún (20) pákó sí ìlà gúsù àgọ́ náà

19. Ṣe ogójì (40) ihà ìtẹ̀bọ̀ fàdákà kí ó lọ sí ìṣàlẹ̀ wọn, méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kan ní ìṣàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan.

20. Àti ìhà kejì, ni ìhà àríwá àgọ́ náà, ṣe ogún pákó ṣíbẹ̀

21. àti ogójì (40) ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà méjì ní abẹ́ pákó kọ̀ọ̀kan.

22. Ṣe pákó mẹ́fà sí ni ìhà opin ìwọ̀ òòrùn àgọ́ náà,

23. kí o sì se pákó méjì fún igun ní ìhà ẹ̀yìn.

24. Ní igún méjèèjì yìí, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ méjì láti ìdí dé orí rẹ̀, a ó sì so wọ́n pọ̀ sí òrùka kan: méjèèjì yóò sì rí bẹ́ẹ̀.

25. Bẹ́ẹ̀ ni pákó mẹ́jọ yóò wà, àti ihò itẹ̀bọ̀ mẹ́rìndínlógún (16) fàdákà yóò wà, méjì ní ìṣàlẹ̀ pákó kọ̀ọ̀kan.

26. “Bákan náà ṣe ọ̀pá ìdábùú igi kaṣíà márùn ún fún pákó ìhà kan àgọ́ náà,

27. Márùn-ún fún àwọn ìhà kejì, àti márùn-ún fún pákó ni ìhà ìwọ̀ oòrùn ní ìhà ẹ̀yìn àgọ́ náà.

28. Ọ̀pá ìdábùú àárin ni agbede-méjì gbọdọ̀ tàn láti òpin dé òpin pákó náà.

29. Bo àwọn pákó náà pẹ̀lú wúrà, kí o sì ṣe òrùka wúrà kí ó lè di ọ̀pá ìdábùú mu. Kí o sì tún bo ọ̀pá ìdábùú náà pẹ̀lú wúrà.

30. “Gbé àgọ́ náà ró gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a fi hàn ọ́ lórí òkè.

31. “Ìwọ yóò si ṣe aṣọ ìgélé aláró àti elése àlùkò, àti òdòdó, àti ògbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tíí ṣe ọlọ́nà, pẹ̀lú ti àwọn kérúbu ni kí á ṣe é.

32. Ìwọ yóò sì fi rọ̀ sára òpó tí ó di igi kaṣíà mẹ́rin ró tí a fi wúrà bò, tí ó dúró lórí ìhò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin.

33. Ṣo aṣọ títa náà sí ìṣàlẹ̀ àwọn ìkọ́, kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí sí ẹ̀gbẹ́ aṣọ títa náà. Aṣọ títa náà yóò pínyà ibi mímọ́ kúrò ní ibi mímọ́ tí ó ga jùlọ.

34. Fi ìtẹ́ àánú bo àpótí ẹ̀rí náà ni ibi mímọ́ tí ó ga jùlọ.

35. Gbé tábìlì náà sí ìta aṣọ títa náà sí ìhà gúsù àgọ́ náà, kí o sì gbé ọ̀pá fitílà sí ọ̀kánkán rẹ̀ ní ìhà àríwá.

36. “Fún ti ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà, ìwọ yóò ṣe aṣọ títa aláró, elésèé àlùkò, ti òdódó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe.

37. Ṣe ìkọ́ wúrà fún aṣọ títa yìí, kí o sì bò ó pẹ̀lú òpó igi kasíà márùn ún pẹ̀lú wúrà. Kí o sì dà ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà márùn ún fún wọn.