orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Gbígbé Àgọ́ Ró.

1. Olúwa sì wí fún Mósè pé:

2. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní. Oṣù kìn-ín-ní ni kí ó gbé Àgọ́ náà, àgọ́ àjọ náà ró.

3. Gbé àpótí ẹ̀rí sí inú rẹ̀, kí ó sì bo àpótí náà pẹ̀lú aṣọ títa.

4. Gbé tábìlì náà wọ ilé, kí o sì tò àwọn ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀ lé e lórí. Nígbà náà gbé ọ̀pá fìtílà wọlé, kí o sì to àwọn fìtílà rẹ̀.

5. Gbé pẹpẹ wúrà ti tùràrí sí iwájú àpótí ẹ̀rí, kí o sì fi aṣọ títa ẹnu ọ̀nà sí ara àgọ́ náà.

6. “Gbé pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun sí iwájú ẹnu ọ̀nà Àgọ́ náà, Àgọ́ àjọ;

7. gbé agbada sí àárin àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, kí o sì fi omi sí inú rẹ̀.

8. Gbé àgbàlá ró yìí ka, kí ó sì fi aṣọ títa sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà.

9. “Mú òróró ìtasórí, kí ó sì ta á sára Àgọ́ náà àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀: yà pẹpẹ sí mímọ́ àti gbogbo ọ̀sọ́ rẹ̀, yóò sì jẹ́ mímọ́.

10. Ta òróró sára pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ya pẹpẹ náà sí mímọ́, yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ.

11. Ta òróró sára agbada náà àti ẹsẹ̀ rẹ, kí o sì yà wọ́n sí mímọ́.

12. “Mú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì wẹ̀ wọ́n pẹ̀lú omi.

13. Nígbà náà wọ Árónì ní aṣọ mímọ́, ta òróró sí i ní orí, kí o sì yà á sí mímọ́, nítorí kí ó lè máa sìn mi bí àlùfáà.

14. Mú àwọn ọmọ rẹ̀ kí o sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n.

15. Ta òróró sí wọn ní orí gẹ́gẹ́ bí o ti ta òróró sí baba wọn ńi orí, nítorí kì wọn lè máa sìn mi bí àlùfáà. Ìtasórí wọn yóò jẹ́ iṣẹ́ àlùfáà ti yóò máa lò fún gbogbo ìrandíran tó ń bọ̀.”

16. Mósè ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

17. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé Àgọ́ náà ró ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ìn-ní ní ọdún kejì.

18. Nígbà tí Mósè gbé Àgọ́ náà ró ó fi ihò ìtẹ̀bọ̀ sí ààyè rẹ̀, ó to pákó rẹ̀, ó fi ọ̀pá rẹ̀ bọ̀ ọ́, ó sì gbé àwọn òpó rẹ̀ ró.

19. Ó na aṣọ àgọ́ náà sórí Àgọ́, ó sì fi ìbòrí bo orí Àgọ́ náà, bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún un.

20. Ó mu ẹ̀rí, ó sì fi sínú àpótí, ó so àwọn òpó mọ́ àpótí náà, ó sì fi àánú bo orí rẹ.

21. Ó sì gbé àpótí náà wá sínú àgọ́; ó sì sọ aṣọ títa, ó sì ta á bo àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

22. Mósè gbé tábìlì sínú àgọ́ àjọ sí ìhà àríwá àgọ́ náà lẹ́yìn aṣọ títa,

23. ó sì to àkàrà sórí rẹ̀ níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

24. Ó gbé ọ̀pá fìtílà sínú àgọ́ àjọ ní òkánkán tábìlì ní ìhà gúsù Àgọ́ náà.

25. Ó sì tan àwọn fítìlà náà níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

26. Mósè gbé pẹpẹ wúrà sínú Àgọ́ àjọ níwájú aṣọ títa

27. ó sì jó tùràrí dídùn lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

28. Ó sì ta aṣọ títa sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ náà.

29. Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà Àgọ́, àgọ́ àjọ, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ́ (ọkà), gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

30. Ó gbé agbada sí àárin àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, ó sì pọn omi sínú rẹ̀ fún wíwẹ̀,

31. Mósè, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lò ó láti fi wẹ ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ wọn.

32. Wọ́n máa ń wẹ̀ nígbàkugbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ tàbí tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

33. Mósè sì gbé àgbàlá tí ó yí Àgọ́ náà kà ró àti pẹpẹ, ó sì ta aṣọ títa ti ẹnu ọ̀nà sí àgbàlá náà. Bẹ́ẹ̀ Mósè ṣe parí iṣẹ náà

Ògo Olúwa

34. Nígbà náà ni àwọ̀ọsánmọ̀ bo àgọ́ àjọ, ògo Olúwa bo Àgọ́ náà.

35. Mósè kò sì lè wọ inú Àgọ́ àjọ, nítorí àwọ́ọ́sánmọ̀ wà lórí rẹ, ògo Olúwa sì ti kún inú Àgọ́ náà.

36. Ní gbogbo ìrìnàjò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbàkugbà tí a ba ti fa ikuuku àwọ̀ọsánmọ̀ náà sókè kúrò lórí Àgọ́, wọ́n máa ń jáde lọ;

37. ṣùgbọ́n tí àwọ̀ọsánmọ̀ kò bá gòkè wọn kò ní jáde títí di ọjọ́ tí ó bá gòkè.

38. Nítorí náà àwọ̀ọsánmọ̀ Olúwa wà lórí Àgọ́ ní ọ̀sán, iná sì wà nínú àwọ̀ọsánmọ̀ ní òru, ní ojú gbogbo ilé Ísírẹ́lì ní gbogbo ìrìnàjò wọn.