orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Oúnjẹ Láti Ọ̀run.

1. Ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ọ̀nà wọn pọ̀n kúrò ni Élímù, wọ́n dé sí ijù Sínì tí ó wà láàrin Élímù àti Ṣínáì, ni ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kejì tí wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì.

2. Ní ijù náà ni ìjọ àwọn ènìyàn ti kùn sí Mósè àti Árónì.

3. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí fún wọn pé, “Àwa ìbá ti ọwọ́ Olúwa kú ni Éjíbítì! Níbi tí àwa ti jókòó ti ìkòkò ẹran ti a sì ń jẹ ohun gbogbo tí a fẹ́ ni àjẹyó, ṣùgbọ́n ẹ̀yin mú wa wá sí inú ijù yìí láti fi ebi pa wá tí a ó fi kú.”

4. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Èmi yóò rọ òjò oúnjẹ láti ọ̀run wá fún yín. Àwọn ènìyàn yóò sì máa jáde lọ ni ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láti kó ìwọ̀nba oúnjẹ ti ó tó fún oúnjẹ òòjọ́ wọn. Ní ọ̀nà yìí ni, èmi yóò fi dán wọn wò láti mọ bóyá wọn yóò máa tẹ̀lé ìlànà mi.

5. Ní ọjọ́ kẹfà, ki wọn kó ìlọ́po méjì èyí ti wọn ń ko ni ojoojúmọ́ tẹ́lẹ̀.”

6. Mósè àti Árónì sọ fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Ní ìrọ̀lẹ́, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ni ó mú un yín jáde láti Éjíbítì wá.

7. Ní òwúrọ̀, ẹ̀yin yóò ri ògo Olúwa, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn tí ẹ kùn sí i. Ta ni àwa ti ẹ̀yin yóò máa kùn sí wa?”

8. Mósè tún wí pé, “Ẹ̀yin yóò mọ pé Olúwa ni, nígbà ti ó bá fún un yín ni ẹran ni ìrọ̀lẹ̀ àti gbogbo oúnjẹ ti ẹ̀yin ń fẹ́ ni òwúrọ̀, nítorí kíkún ti ẹ̀yin ń kùn sí i. Ta ni àwa? Ẹ̀yin kò kùn sí àwa, Olúwa ni ẹ̀yin kùn sí i.”

9. Nígbà náà ni Mósè sọ fún Árónì pe, “Sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pe, ‘Ẹ wá sí iwájú Olúwa, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn yín.’ ”

10. Ó sì ṣe bí Árónì ti ń bá gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, wọn si bojúwo ìhà ijù, sì kíyèsi ògo Olúwa si farahàn ni àwọ̀-sánmọ̀.

11. Olúwa sọ fún Mósè pé,

12. “Èmi ti gbọ́ kíkun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Sọ fun wọn, ‘Ní àṣálẹ́, ẹ̀yin yóò jẹ ẹran, àti ni òwúrọ̀ ni ẹ̀yin yóò jẹ oúnjẹ. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”

13. Ní àṣálẹ́ ọjọ́ náà ni àwọn àparò fò dé, wọ́n sì bo àgọ́ mọ́lẹ̀, ní òwúrọ̀ ìrì sì sẹ̀ yí gbogbo àgọ́ náà ká.

14. Nígbà tí ìrì tí ó sẹ̀ bo ilẹ̀ ti lọ, kíyèsí i, ohun tí ó dì, tí ó sì ń yooru bí i yìnyín wà lórí ilẹ̀.

15. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i, wọ́n bi ara wọn léèrè pé, “Kí ni èyí?” Nítorí pé wọn kò mọ ohun tí i se.Mósè sì wí fún wọn pé, “Èyí ni oúnjẹ tí Olúwa fi fún un yín láti jẹ.

16. Èyí ni ohun tí Olúwa ti pàṣẹ: ‘Kí olúklùkù máa kó èyí ti ó tó fún un láti jẹ. Ẹ mú òṣùnwọ̀n ómérì kan (bí i líta méjì) fún ẹnikọ̀ọ̀kan ti ó wà nínú àgọ́ yín.’ ”

17. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe bí a ti sọ fún wọn; àwọn kan kó púpọ̀, àwọn kan kó kékeré.

18. Nígbà ti wọn fi òṣùwọ̀n ómérì wọ̀n-ọ́n-nì, ẹni ti ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù. Ẹnìkọ̀ọ̀kan kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un.

19. Mósè sì wí fún wọ́n pé, “Kí ẹnikẹ́ni ó má ṣe kó pamọ́ lára rẹ̀ di òwurọ̀ ọjọ́ kejì.”

20. Ṣùgbọ́n, àwọn kan nínú wọn kò fetí sí Mósè; Wọ́n kó lára rẹ̀ pamọ́ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ohun ti wọ́n kó pamọ́ kún fún ìdin, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rùn. Nítorí náà Mósè bínú sí wọn.

21. Ní òwúrọ̀, ni ojoojúmọ́ ni ẹnìkọ̀ọ̀kan ń lọ kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un láti jẹ, bí òòrùn bá sì mú, a sì yọ́.

22. Ní ọjọ́ kẹfà, wọ́n kó ìlọ́po méjì èyí ti wọn ń kó tẹ́lẹ̀: òṣùnwọn ómérì méjì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan; àwọn olórí ìjọ ènìyàn sì wá, wọ́n sì sọ èyí fún Mósè.

23. Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: ‘Ọ̀la jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ìsinmi mímọ́ fún Olúwa. Ẹ yan èyí ti ẹ̀yin ní yan, kí ẹ sì bọ èyí ti ẹ̀yin ní bọ̀. Ẹ tọ́jú èyí ti ó kù sílẹ̀, kí ẹ pa á mọ́ di òwúrọ̀.’ ”

24. Wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ di òwúrọ̀ bí Mósè ti pàṣẹ; kò sì rùn bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní ìdin.

25. Mósè sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ ẹ́ ní òní nítorí òní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi Olúwa. Ẹ̀yin kò ni rí i ni orí ilẹ̀ ní ọjọ́ òní.

26. Ní ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi kó o, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ keje ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí i fún un yín ni ọjọ́ náà.”

27. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ àwọn ènìyàn kan jáde lọ ní ọjọ́ keje láti kó o, ṣùgbọ́n wọn kò ri nǹkan kan kó.

28. Olúwa sì sọ fún Mósè pé, “Yóò ti pẹ́ tó ti ẹ ó kọ̀ láti pa àṣẹ mi àti ìlànà mi mọ́?

29. Wò ó? Olúwa ti fún un yín ni ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà, ni ọjọ́ kẹfà, ó fún un yín ni ounjẹ ọjọ́ méjì; kí ẹnìkọọkan dúró ni ibi tí ó gbé wà; kí ẹ má ṣe kúrò ni ibi tí ẹ wà ni ọjọ́ keje.”

30. Nítorí náà, àwọn ènìyàn sinmi ní ọjọ́ keje.

31. Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì sì pe oúnjẹ náà ní Mánà. Ó funfun bí irúgbìn kóríáńdà, ó sì dùn bí burẹ́dì fẹlẹfẹlẹ ti a fi oyin ṣe.

32. Mósè wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: ‘Ẹ mú òṣùnwọ̀n ómérì mánà kí ẹ sì pa á mọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀, kí wọn kí ó lè rí oúnjẹ ti èmi fi fún un yín jẹ ní ijù, nígbà tí mo mú un yín jáde ni ilẹ̀ Éjíbítì.’ ”

33. Nígbà náà ni Mósè sọ fún Árónì pe, “Mú ìkòkò kan, kí o sì kó mánà tí ó kún òṣùnwọ̀n ómérì kan sí inú rẹ̀, kí o sì gbé e kalẹ̀ ni iwájú Olúwa láti tọ́jú rẹ̀ pamọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀.”

34. Bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè, Árónì gbé mánà sí iwájú ẹ̀rí láti pa á mọ́.

35. Àwọn ará Ísírẹ́lì jẹ mánà fún ogójì ọdún títí wọ́n fi dé ilẹ̀ Kénánì ni ibi ti èso ti wà fún wọn láti jẹ; Wọ́n jẹ mánà títí tí wọ́n fi dé ilẹ̀ agbégbé Kénánì.

36. (Ọ̀sùnwọn ómérì kan sì jẹ́ ìdákan nínú ìdá-mẹ́wàá éfà.)