orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Asọ Àlùfáà

1. Nínú aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò àti ti òdòdó ni wọ́n fi ṣe aṣọ híhun fún àwọn òsìsẹ́ ní ibi mímọ́. Ó sì tún dá aṣọ mímọ́ fún Árónì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

Ẹ̀wù Èfòdì.

2. Ó ṣe ẹ̀wù èfòdì wúrà, ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára.

3. Ó sì lu wúrà náà di ewé fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì tún gé e láti fi ṣe iṣẹ́ sí aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó, àti sínú ọ̀gbọ̀ dáradára ni ti iṣẹ́ ọgbọ́n iṣẹ́ ọnà.

4. Ó ṣe aṣọ èjìká fún ẹ̀wù èfòdì náà, èyí tí ó so mọ igun rẹ̀ méjèèjì, nítorí kí ó lè so pọ̀.

5. Ọnà ìgbànú híhun rẹ̀ rí bí i ti rẹ̀ ó rí bákan náà pẹ̀lú ẹ̀wù èfòdì ó sì sé e pẹ̀lú wúrà, àti pẹ̀lú aṣọ aláró, elésèé àlùkò, òdòdó àti pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pà sẹ fún Mósè.

6. Ó ṣìṣe òkúta óníkísì tí a tò sí ojú ìdè wúrà, tí a sì fín wọn gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

7. Ó sì so wọ́n mọ́ asọ èjìká ẹ̀wù èfòdì náà bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Isirẹli, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pà sẹ fún Mósè.

Igbáàyà.

8. Ó ṣe iṣẹ́ ọnà sí igbáyà náà iṣẹ́ ọgbọ́n ọlọ́nà. Ó ṣe é bí, ẹ̀wù èfòdì: ti wúrà ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára.

9. Igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé ìwọ̀n ṣẹ̀ǹtímítà méjìlélógún ni gígùn rẹ̀, fífẹ̀ rẹ̀ náà sì jẹ́ ìwọ̀n sẹ̀ǹtímítà méjìlélógún ó sì jẹ́ ìsẹ́po méjì.

10. Ó sì to ìpele òkúta mẹ́rin oníyebíye sí i. Ní ipele kìn-in-ní ní rúbì wà, tapásì àti bérílù;

11. ní ipele kejì, túríkúóṣè, sáfírù àti émérálídì;

12. ní ipele kẹta, Jásínítì, ágátè àti amétístì;

13. ní ipele kẹ́rin, kárísólítì, oníkísì, àti jásípérì. Ó sì tò wọ́n ní ojú ìdè wúrà ní títò wọn.

14. Wọ́n jẹ́ òkúta méjìlá ọkan fún orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan, a fín ọ̀kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ ẹnikọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjèèjìlá.

15. Fún igbáyà náà, wọ́n ṣe ẹ̀wọ̀n iṣẹ́ kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bi okùn.

16. Wọ́n sì ṣe ojú ìdè wúrà méjì àti òrùka wúrà méjì, wọ́n sì so àwọn òkúta náà mọ́ igun méjèèjì igbáàyà náà.

17. Wọ́n sì so ẹ̀wọ̀n wúrà méjèèjì náà mọ́ àwọn òrùkà náà ni igun igbáàyà náà,

18. àti ní àwọn òpin ẹ̀wọ̀n tókù ni wọ́n fi mọ ojú ìdè méjèèjì, wọ́n so wọ́n mọ́ aṣọ èjìká ẹ̀wù èfòdì náà ní iwájú.

19. Wọ́n ṣe òrùka wúrà méjì, wọ́n sì so wọ́n mọ́ igun méjèèjì igbáyà náà ní etí tí ó wà ní inú lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀wù èfòdì náà.

20. Wọ́n sì tún ṣe òrùka wúrà méjì sí i, wọ́n sì so wọ́n mọ́ ìdí aṣọ èjìká ní iwájú ẹ̀wù èfòdì náà tí ó sún mọ́ ibi tí a ṣe lọ́sọ̀ọ́ ní òkè ìgbànú ẹ̀wù èfòdí náà.

21. Wọn ṣo àwọn òrùka igbáàyà mọ́ àwọn òrùka ẹ̀wù èfòdì ọ̀já aṣọ aláró, kí a pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, nítorí kí igbáàyà náà má ṣe tú kúrò lára ẹ̀wù èfòdì náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

Àwọn Asọ Àlùfáà Mìíràn.

22. Ó sì ṣe ọ̀já àmùrè ẹ̀wù èfòdì gbogbo rẹ̀ jẹ́ aṣọ aláró iṣẹ́ alásọ híhun

23. Pẹ̀lú ihò ní àárin ọ̀já àmùrè náà gẹ́gẹ́ bí i ojú kọ́là, àti ìgbànú yí ihò yìí ká, nítorí kí ó má ba à ya.

24. Ó sì ṣe pomégíránátè ti aṣọ aláró, elésèé àlùkò, òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára yí ìsẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká.

25. Ó sì ṣe ago kìkì wúrà, ó sì ṣo wọ́n mọ́ àyìká ìsẹ́tí àárin pomégíránátè náà.

26. Aago àti pomégíránátè kọjú sí àyíká ìsẹ́ti ọ̀já àmùrè láti máa wọ̀ ọ́ fún iṣẹ́ àlùfáà, bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

27. Fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ, wọ́n ṣe àwọ̀tẹ́lẹ̀ ti ọ̀gbọ̀ dáradára tí iṣẹ́ alásọ híhun.

28. Àti fìlà ọ̀gbọ̀ dáradára, ìgbàrí ọ̀gbọ̀ àti aṣọ abẹ́ ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára.

29. Ọ̀já náà jẹ́ ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, aṣọ aláró, elésèé àlùkò àti òdòdó iṣẹ́ alábẹ́rẹ́ bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mósè.

30. Ó ṣe àwo, adé mímọ́, láti ara kìkì wúrà, wọ́n sì kọ̀wé sí i, gẹ́gẹ́ bí i ìkọ̀wé lórí èdìdì: “MÍMỌ́ SÍ Olúwa.”

31. Wọ́n sì so ọ̀já aláró mọ́ ọn láti ṣo ó mọ́ fìlà náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

Mósè Bẹ Àgọ́ náà wò.

32. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo iṣẹ́ àgọ́ náà, ti àgọ́ àjọ parí. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàsẹ fún Mósè.

33. Wọ́n sì mú tabánákù náà tọ Mósè wá: àgọ́ náà àti gbogbo ohun ọ̀sọ́ rẹ̀, ìkọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, òpó rẹ̀ àti àwọn ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀;

34. ìbòrí awọ àgbò tí a kùn ní pupa, ìbòrí awọ àti ìji àsọ títa;

35. àpótí ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn òpó rẹ̀ àti ìbòrí àánú;

36. tábìlì pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn;

37. ọ̀pá fìtílà kìkì wúrà pẹ̀lú ipele fìtílà rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, àti òróró fún títanná rẹ̀;

38. pẹpẹ wúrà àti òróró ìtasórí, tùràrí dídùn, àti aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà.

39. Pẹpẹ idẹ pẹ̀lú idẹ ọlọ, àwọn òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀; agbada pẹ̀lú ẹṣẹ̀ rẹ̀;

40. aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú àwọn òpó rẹ̀ àti àgbàlá, àti aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá; ọ̀já àmùrè àti èèkàn àgọ́ fún àgbàlá náà; gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ fún àgọ́, àgọ́ àjọ náà;

41. aṣọ híhun tí wọ́n ń wọ̀ fún iṣẹ́ ibi mímọ́, aṣọ mímọ́ fún Árónì àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ àlùfáà.

42. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣe gbogbo iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti páṣẹ fún Mósè.

43. Mósè bẹ iṣẹ́ náà wò, ó sì rí i wí pé wọ́n ti ṣe é gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pà ṣẹ. Nítorí náà Mósè sì bùkún fún wọn.