orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Abọ̀rìṣà Gba Ìdálẹ́bì

1. Díẹ̀ nínú àwọn alàgbà Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ mi, wọ́n sì jókòó níwájú mi,

2. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

3. “Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin wọnyìí ti gbé òrìṣà kalẹ̀ sínú ọkàn wọn, wọ́n sì gbé àwọn ohun tó lè mú wọn ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ síwájú wọn. Ṣé ó tún yẹ kí n gbà wọ́n láàyè láti wádìí lọ́dọ̀ mi rárá bi? Nítorí náà, sọ fún wọn pé:

4. ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Ísírẹ́lì tó ó gbé òrìṣà sí ọkàn wọn, tó tún gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ ṣíwájú rẹ̀, bá wá sọ́dọ̀ wòlíì, Èmi Olúwa fúnra mi ni n ó dá a lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà ìbọ̀rìṣà rẹ.

5. N ó ṣe èyí láti gba ọkàn àwọn ará Ísírẹ́lì tó ti tẹ̀lé òrìṣà wọn lọ padà sí ọ̀dọ̀ mi.’

6. “Nítorí náà sọ fún ilé Ísírẹ́lì, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí: Ẹ ronú pìwàdà! Ẹ yípadà kúrò lọ́dọ̀ òrìṣà yín kí ẹ̀yin sì kọ gbogbo ìwà ìríra yín sílẹ̀!

7. “ ‘Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Ísírẹ́lì tàbí àlejò tó ń gbé ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, bá ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi, tó gbé òrìṣà rẹ̀ sọ́kàn rẹ̀, tó tún gbé ohun tó ń mú ni ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ ṣíwájú rẹ, lẹ́yìn èyí tó tún lọ sọ́dọ̀ wòlíì láti béèrè nǹkan lọ́wọ́ mi! Èmi Olúwa fúnra ara mi ní ń o dá a lóhùn.

8. N ó lodi si írú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ lọ́nà òdì, n ó sì sọ ọ́ di àánú àti òwe. Èmi yóò sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn mi. Nígbà náà, ẹ ó mọ̀ pé èmi ni Olúwa.

9. “ ‘Bí wọ́n bá sì tan wòlíì náà láti sọtẹ́lẹ̀, Èmi Olúwa ló tan wòlíì náà, Èmi yóò nawọ́ sí i, èmi yóò sì pa á run kúrò láàrin àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.

10. Wọn yóò ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn—ìjìyà kan náà là ó fún wòlíì àti ẹni tó lọ béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀.

11. Kí ilé Ísírẹ́lì má baà sìnà kúrò lọ́dọ̀ mi tàbí kí wọ́n má baà sọra wọn di aláìmọ́ torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n kí wọ́n le jẹ́ ènìyàn mi, kí Èmi náà sì le jẹ́ Ọlọ́run wọn, ni Olúwa Ọlọ́run wí.’ ”

Àwọn Aláìsòdodo Gba Ìdájọ́

12. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

13. “Ọmọ ènìyàn bí orílẹ̀ èdè kan bá ṣẹ́ mí nípa ìwà àìṣòdodo, èmi yóò nawọ́ mi jáde sí wọn, láti gé ìpèsè oúnjẹ wọn, n ó rán ìyàn sí wọn, èmi yóò sì pa ènìyàn àti ẹranko inú rẹ̀,

14. bí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí—Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù-tilẹ̀ wà nínú rẹ, ará wọn nìkan ni wọ́n lé gbà sílẹ̀ pẹ̀lú ìwà òdodo wọn, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

15. “Tàbí bí mo bá jẹ́ kí ẹranko búburú gba orílẹ̀ èdè náà kọjá tí wọn fi sílẹ̀ láìní ọmọ tí wọ́n sì sọ di ahoro, tó bẹ́ẹ̀ tí kò sẹ́ni tó le gba ibẹ̀ kọjá torí ẹranko búburú yìí,

16. bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí wà níbẹ̀ bí mo ti wà láàyè ní Olúwa Ọlọ́run wí, wọn kò lé gba àwọn ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin wọn là, ilẹ̀ náà yóò di ahoro.

17. “Tàbí tí mo bá mú idà kọjá láàrin orílẹ̀ èdè náà tí mo wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí idà kọjá láàrin ilẹ̀ náà,’ tí mo sì tú ìbínú gbígbóná lé wọn lórí nípa ìtàjẹ́sílẹ̀, tí mo pa ènìyàn àti ẹranko inú rẹ.

18. Bí àwọn ọkúnrin mẹ́ta yìí tilẹ̀ wà nínú rẹ̀, Olúwa Ọlọ́run wí pé, Bí mo ti wà, wọn ki yóò gba ọmọkúnrin tàbí ọmọbìnrin là, ṣùgbọ́n àwọn tikara wọn nìkan ni a o gbàlà.

19. “Tàbí bí mo rán àjàkálẹ̀-àrùn si ilẹ̀ náà, ti mo si da ìrunu mi lé e lórí pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀, láti gé ènìyàn àti ẹranko kúrò nínú rẹ̀,

20. bo tilẹ̀ jẹ́ pé Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù wà nínú rẹ, bí mo ti wà láàyè ni Olúwa Ọlọ́run wí wọn kò le gba ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin wọn lá. Ara wọn nìkan ni ìwà òdodo wọn lè gbà là.

21. “Nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Báwo ni yóò ti burú tó nígbà tí mo bá rán ìdájọ́ kíkan mi mẹ́rin sórí Jérúsálẹ́mù-èyí ni idà àti ìyàn, ẹranko búburú àti àjàkálẹ̀-àrùn-láti pa àwọn ènìyàn àti ẹranko inú rẹ̀!

22. Síbẹ̀, yóò ṣẹ́kù àwọn díẹ̀-àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tí a ó kó jáde nínú rẹ̀. Wọn yóò wá bá yin, ẹ ó rí ìwà àti ìṣe wọn, nígbà náà ni ẹ ó rí ìtùnú nípa àjálù tí mo mú wá sórí Jérúsálẹ́mù—àní gbogbo àjálù ní mo ti mú wá sórí rẹ̀.

23. Nígbà tí ẹ bá rí ìwà àti ìṣe wọn, a ó tù yín nínú, nítorí pé ẹ ó mọ̀ pé n kò ṣe nǹkan kan láì nídìí, ni Olúwa Ọlọ́run wí.”