orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Jérúsálẹ́mù, Àjàrà Tí Kò Wúlò

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé:

2. “Ọmọ ènìyàn, báwo ni igi àjàrà ṣe dára ju igi mìíràn lọ tàbí jù ẹ̀ka àjàrà tó wà láàrin igi yòókù nínú igbó?

3. Ǹjẹ́ a wa lè mú igi lára rẹ̀ ṣe nǹkan ti o wúlò bí? Tàbí kí ènìyàn fi ṣe èèkàn tí yóò fi nǹkan kọ́?

4. Lẹ́yìn èyí, ṣe a jù ú sínú iná gẹ́gẹ́ bí epo ìdáná, gbogbo igun rẹ̀ jóná pẹ̀lú àárin rẹ, ṣé o wà le wúlò fún nǹkan kan mọ́?

5. Tí kò bá wúlò fún nǹkankan nígbà tó wà lódidi, báwo ni yóò ṣe wá wúlò nígbà tíná ti jó o, tó sì dúdú nítorí èéfín?

6. “Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Bí mo ṣe sọ igi àjàrà tó wà láàrin àwọn igi inú igbó yóòkù di igi ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò ṣe ṣe gbogbo ènìyàn tó ń gbé Jérúsálẹ́mù.

7. Èmi yóò dojúkọ wọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ti jáde kúrò nínú iná kan síbẹ̀ iná mìíràn yóò pàpà jó wọn. Nígbà tí mo bá sì dojúkọ wọ́n, ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.

8. Èmi yóò sọ ilé náà di ahoro nítorí ìwà àìsòótọ́ wọn, ni Olúwa Ọlọ́run wí.”