orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ògo Kúrò Nínú Tẹ́ḿpìlì

1. Mo sì wò ó, mo rí ohun kan tó dàbí òkúta sáfírè nínú òfuurufú tó wà lókè orí kérúbù, ìrísí ohun yìí sì dàbí ìtẹ́.

2. Olúwa sì sọ fún ọkùnrin tó wọ aṣọ funfun pé, “Lọ sí àárin àwọn kẹ̀kẹ́ tó wà lábẹ́ kérúbù. Bu ẹyin iná tó kúnwọ́ rẹ láàrin kérúbù, kí o sì fọ́n-ọn sórí ìlú náà.” Ó sì lọ lóju mi.

3. Àwọn kérúbù dúró sí apá gúúsù tẹ́ḿpìlì nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ìkùukùu sì bo inú àgbàlá.

4. Ògo Olúwa sì kúrò lórí àwọn kérúbù, ó bọ́ sí ibi ìloro tẹ́ḿpìlì. Ìkùukùu sì bo inú tẹ́ḿpìlì, àgbàlá sì kún fún ìmọ́lẹ̀ àti ògo Olúwa.

5. A sì gbọ́ ariwo ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí títí dé àgbàlá tó wà níta gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí Ọlọ́run Olódùmáre bá ń sọ̀rọ̀.

6. Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún ọkùnrin aláṣọ funfun yìí pé, “Mú iná láàrin àwọn kẹ̀kẹ́, láàrin àwọn kérúbù,” ó sì lọ dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ náà.

7. Ọ̀kan nínú àwọn kérúbù sì nawọ́ síbi iná tó wà láàrin kérúbù yóòkù. Ó mú lára rẹ, ó fi sínú ọwọ́ ọkùnrin aláṣọ funfun, òun náà gbàá, ó sì jáde lọ.

8. (Ohun tó dàbí ọwọ́ ènìyàn wà lábẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí).

9. Mo sì rí i pé kẹ̀kẹ́ mẹ́rin wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kérúbù yìí, kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kérúbù kọ̀ọ̀kan; àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ń tàn yanran bí àpapọ̀ àwọ̀ ewéko àti pupa rẹ́súrẹ́sú.

10. Ní ti ìrísí wọn, gbogbo wọn jọra wọn; ọ̀kọ̀ọ̀kan rí bí ìgbà tí kẹ̀kẹ́ kan wà nínú kẹ̀kẹ́ mìíràn.

11. Nígbà tí wọ́n ń lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀kan nínú ọ̀nà mẹ́rin tí àwọn kérúbù dojú kọ; àwọn kẹ̀kẹ́ náà kò yípadà bí àwọn kérúbù ti ń lọ. Àwọn kérúbù ń lọ síbi tí orí dojú kọ láì yà.

12. Gbogbo ara wọn àti ẹ̀yìn, ọwọ́ àti ìyẹ́ wọn àwọn kẹ̀kẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọn ló ní ojú tó yí wọn ká.

13. Mo gbọ́ tí wọ́n pe àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ni “kẹ̀kẹ́ ìpòòyì.”

14. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kérúbù yìí ni ojú mẹ́rin: ojú èkínní jẹ́ ojú kérúbù, ojú kejì jẹ́ ti ènìyàn, ojú kẹta jẹ́ ti kìnnìún nígbà tí ojú kẹrin jẹ́ ti ẹyẹ idì.

15. A gbé àwọn kérúbù sókè. Èyí ni àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo rí létí odò Kébárì.

16. Bí àwọn kérúbù yìí bá ń lọ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹgbẹ́ wọn náà yóò lọ; bẹ́ẹ̀ ni bí àwọn kérúbù bá tú ìyẹ́ wọn ká láti dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí kò ní kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.

17. Bí àwọn kérúbù bá dúró díẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́; bí àwọn kérúbù bá dìde àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dìde, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú wọn.

18. Ògo Olúwa kúrò níbi ìloro tẹ́ḿpìlì ó sì dúró sórí àwọn kérúbù.

19. Àwọn kérúbù gbé ìyẹ́ wọn sókè, wọ́n sì fò kúrò nílẹ̀ lójú mi, wọ́n sì lọ pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ wọn lẹ́ẹ̀kan náà. Wọ́n dúró níbi ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà ìlà-oòrùn ilé Olúwa, ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì wà lórí wọn.

20. Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀dá alààyè tí mo rí lábẹ́ Ọlọ́run Ísírẹ́lì létí odò Kébárì, mo sì mọ̀ pé kérúbù ni wọ́n.

21. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ mẹ́rin, lábẹ́ ìyẹ́ wọn ni ohun tó jọ ọwọ́ ènìyàn wà.

22. Àfiwé ojú àti ìrísí wọn rí bákan náà pẹ̀lú àwọn tí mo rí létí odò kébárì. Olúkúlùkù wọn sì ń lọ sí ọ̀kánkán tààrà.