orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìpohùnréré Ẹkún Fún Éjíbítì

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá: wí pé:

2. “Ọmọ ènìyàn, ṣọtẹ́lẹ̀ kí o sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Pohùnréré ẹkún kí o sì wí pé,“Ó ṣe fún ọjọ́ náà!”

3. Nítorí ọjọ́ náà sún mọ́ tòsíàní ọjọ́ Olúwa sún mọ́ tòsíỌjọ́ tí ọjọ́ ìkùukùu ṣú dúdú,àsìkò ìparun fún àwọn aláìkọlà

4. Idà yóò wá sórí Éjíbítììrora ńlá yóò sì wá sórí KúṣìNígbà tí àwọn tí a pa yóò subú ní Éjíbítìwọn yóò kò ọrọ̀ rẹ̀ lọìpìlẹ̀ rẹ̀ yóò sì wó lulẹ̀.

5. Kúṣì àti Pútì, Lídíà àti gbogbo Árábù, Líbíyà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ ìlérí yóò ṣubú nípa idà papọ̀ pẹ̀lú Éjíbítì.

6. “ ‘Èyí yìí ní Olúwa wí:“ ‘Àwọn alejò Éjíbítì yóò ṣubúagbára ìgbéraga rẹ yóò kùnàláti Mígídólì títí dé Ásúwánìwọn yóò ti ipa idà ṣubú láàárin rẹ;ní Olúwa Ọlọ́run wí:

7. Wọn yóò sì wàlára àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro,ìlú rẹ yóò sì wàní ara àwọn ìlú tí ó di ahoro.

8. Lẹ́yìn náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa,nígbà tí mo bá gbé iná kalẹ̀ ní Ijíbítìtí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá parun.

9. “ ‘Ní ọjọ́ náà oníṣẹ́ yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde nínú ọkọ̀ ojú omi láti dẹ́rùbà Kúsì kúrò nínú ìtẹ́lọ́rùn rẹ̀. Ìrora yóò wá sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ ìparun Éjíbítì: Kíyèsí i, ó dé.

10. “ ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Èmi yóò mú òpin bá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọnènìyàn Éjíbítì láti ọwọ́ Nébukadinésárì ọba Bábílónì.

11. Òun àti àwọn ológun rẹ̀ẹ́rù àwọn orílẹ̀-èdèní a o mú wá láti pa ilẹ náà run.Wọn yóò fa idà wọn yọ sí Éjíbítìilẹ̀ náà yóò sì kún fún àwọn tí a pa.

12. Èmi yóò mú kí àwọn odò Náílì gbẹÈmi yóò sì ta ilẹ náà fún àwọn ènìyàn búburú:láti ọwọ́ àwọn àjòjì ènìyànÈmi yóò jẹ́ kí ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tí ó wá nínú rẹ ṣòfò.Èmi Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

13. “ ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Èmi yóò pa àwọn òrìṣà runÈmi yóò sì mú kí òpin dé báère òrìṣà gbígbẹ́ ni Nófìkò ní sí ọmọ aládé mọ́ ní Éjíbítì,Èmi yóò mú kí ìbẹ̀rù gba gbogbo ilẹ̀ náà.

14. Èmi yóò sì mú kí Pátírọ́sì di ahoroèmi yóò fi ina sí Sóánìèmi yóò sì fi ìyà jẹ Tébésì

15. Èmi yóò tú ìbínú mi jáde sórí Pélúsíómùìlú odi Éjíbítìèmi yóò sì ké àkójọpọ̀ Jépésì kúrò

16. Èmi yóò ti iná bọ ÉjíbítìPélúsíómù yóò japoró ní ìroraÈfúùfù yóò jà ní TébésìMémìfísì yóò wà ìpọ́njú ní ìgbà gbogbo

17. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ní Hẹ́lópónísè àti Búbásítìyóò ti ipa idà subúwọn yóò sì kó àwọn ìlú wọn ní ìgbèkùn

18. Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tápárebìnígbà tí mo bá já àjàgà Éjíbítì kúrò;níbẹ̀ agbára iyì rẹ̀ yóò dópinwọn yóò fi ìkùukùu bò óàwọn abúlé rẹ ní wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.

19. Nítorí náà Èmi yóò mú ki ìjìyà wá sórí Éjíbítì,wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”

20. Ní ọjọ́ keje osù kìn-ín-ní ọdún kọkànlá ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

21. “Ọmọ ènìyàn, Èmi ti ṣe apa Fáráò Ọba Éjíbítì. A kò ì tí ì di apá náà papọ̀ láti mu kí ó san, a ko sì ti di i si àárin igi pẹlẹbẹ kí o lè ni agbára tó láti di idà mú.

22. Nítorí náà, báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi lòdì sí Fáráò Ọba Éjíbítì. Èmi yóò sẹ́ apá rẹ̀ méjèèjì, èyí tí ó dára àti èyí tí a ti ṣẹ́ pẹ̀lú, yóò sì mú kí idà bọ́ sọnù ní ọwọ́ rẹ̀.

23. Èmi yóò sì fọ́n àwọn ènìyàn Éjíbítì ká sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì tú wọn ká gbogbo ilẹ̀.

24. Èmi yóò mú kí apá Ọba Bábílónì ní agbára, èmi yóò sì fi idà mi sí ọwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò ṣẹ́ apá Fáráò, yóò sì kérora níwájú rẹ̀ bí ọkùnrin tí a ṣá ní àṣápa.

25. Èmi yóò mú kí apá Ọba Bábílónì lé, ṣùgbọ́n apá Fáráò yóò sì rọ. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá mú idà mi sí ọwọ́ Ọba Bábílónì yóò sì fí idà náà kọlu Éjíbítì.

26. Èmi yóò fọ́n àwọn ara Éjíbítì ká sí àárin orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí àárin orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí gbogbo ilẹ̀. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”