orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìpohùn-Réré Ẹkún Fún Tírè

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:

2. “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún fún Tírè.

3. Sọ fún Tírè, tí a tẹ̀dó sí ẹnu bodè òkun, oníṣòwò àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù. ‘Èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Ìwọ Tírè wí pé“Ẹwá mi pé.”

4. Ààlà rẹ wà ní àárin òkun;àwọn ọ̀mọ̀lé rẹ ti mú ẹwà rẹ pé.

5. Wọn ti fi pákó firi ti Sénárìkan gbogbo ọkọ̀ rẹ,wọ́n ti mú kédárì ti Lébánónì wáláti fi ṣe òpó ọkọ̀ fún ọ.

6. Nínú igi Oákù ti Báṣánìní wọn ti fi gbẹ́ ìtukọ̀ òbèlè rẹ̀;ìjókòó rẹ ni wọn fi eyín erin ṣe pẹ̀lúigi bókísì láti erékùsù Kítímù wá

7. Asọ funfun dáradára tí a fi abẹ́rẹ́ṣiṣẹ́ ọ̀nà sí lára láti Éjíbítì wáni èyí tí ìwọ ta láti se okun ọkọ̀aṣọ aláró àti elésèé àlùkòláti erékùṣù ti Èlíṣàni èyí tí a fi bò ó

8. Àwọn ará ìlú Sídónì àti Árífádì ni àwọn ìtukọ̀ rẹ̀àwọn ọlọ́gbọ́n ẹ̀rọ rẹ, ìwọ Tírè,tí wọ́n wà nínú rẹ ni àwọn àtukọ̀ rẹ.

9. Àwọn àgbà Gíbálì,àti àwọn ọlọ́gbọ́n ibẹ̀,wà nínú ọkọ̀ bí òṣìṣẹ́ atukọ̀ rẹ,gbogbo ọkọ̀ ojú òkunàti àwọn atukọ̀-òkunwá pẹ̀lú rẹ láti dòwò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.

10. “ ‘Àwọn ènìyàn Páṣíà, Lídíà àti Pútìwà nínú jagunjagun rẹàwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ.Wọ́n gbé àpáta àti àsíborí wọn rósára ògiri rẹ,wọn fi ẹwà rẹ hàn.

11. Àwọn ènìyàn Árífádì àti Hélékìwà lórí odi rẹ yíká;àti àwọn akọni Gámádì,wà nínú ilé ìṣọ́ rẹ.Wọ́n fi àwọn asà wọn kọ ara odi rẹ;wọn ti mú ẹwà rẹ pé.

12. “ ‘Táṣíṣì ṣòwò pẹ̀lú rẹ torí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ tí ó ní; wọn ṣe ìpààrọ̀ fàdákà, irin tanúnganran àti òjé fún ọjà títà rẹ̀.

13. “ ‘Àwọn ará Gíríkì, Túbálì, Jáfánì àti Méṣékì, ṣòwò pẹ̀lú rẹ: wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàsípààrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ.

14. “ ‘Àwọn ti ilé Béti Tógárímà ṣe ìpààrọ̀ ẹṣin-ìṣiṣẹ́, ẹṣin-ogun àti ìbàákà ṣòwò ní ọjà rẹ.

15. “ ‘Àwọn ènìyàn Ródísì ni àwọn oníṣòwò rẹ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù ni wọ́n jẹ́ onibárà rẹ̀; wọ́n mú eyín-erin àti igi ébónì san owó rẹ.

16. “ ‘Árámù ṣòwò pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ òwò rẹ̀; wọn ṣe ìpààrọ̀ òkúta iyebíye, òwú elésèé àlùkò, iṣẹ́ ọ̀nà tí a fi abẹ́rẹ́ ṣe, asọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ìlẹ̀kẹ̀ iyùn pupa fún ọjà títà rẹ.

17. “ ‘Júdà àti Ísírẹ́lì, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Mínnítì, àkàrà àdídùn; pannági, oyin, epo àti ìpara olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ.

18. “ ‘Dámásíkù, ni oníṣòwò rẹ, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọjà tí ó ṣe àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀; ní ti ọtí wáìnì tí Helíbónì, àti irun àgùntàn funfun.

19. “ ‘Àwọn ará Dánì àti Gíríkì láti Úsálì ra ọjà títà rẹ; irin dídán, káṣíà ati kálámù ni àwọn ohun pàsípààrọ̀ ní ọjà rẹ.

20. “ ‘Dédánì ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn.

21. “ ‘Àwọn ará Árábù àti gbogbo àwọn ọmọ aládé Kédárì àwọn ni àwọn onibárà rẹ: ní ti ọ̀dọ́ àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbárà rẹ.

22. “ ‘Àwọn oníṣòwò ti Ṣébà àti Rámà, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọ́n ta onírúurú tùràrí olóòórùn dídùn dáradára ní ọjà rẹ, àti àwọn òkúta iyebíye àti wúrà.

23. “ ‘Áránì àti Kánnà àti Édénì, àwọn onísòwò Ṣébà, Ásúrù àti Kílímádì, ni àwọn oníṣòwò rẹ.

24. Wọ̀nyí ní onírúurú nǹkan: aṣọ aláró, àti oniṣẹ́-ọnà àti àpótí aṣọ oníyebíye, tí a fi okùn dì, tí a sì fi igi kédárì ṣe, nínú àwọn ilé-ìtajà rẹ.

25. “ ‘Àwọn ọkọ̀ Táṣíṣì ní èròní ọjà rẹa ti mú ọ gbilẹ̀a sì ti ṣe ọ́ lógoní àárin gbungbun òkun

26. Àwọn atukọ̀ rẹ ti mú ọwá sínú omi ńlá.Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn yóò fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ní àárin gbùngbùn òkun.

27. Ọrọ̀ rẹ, ọjà rẹ àti àwọn ohun títà rẹ,àwọn atọ́kọ̀ rẹ, òṣìṣẹ́ ìtukọ̀ rẹ.Àwọn oníbárà rẹ àti gbogbo àwọnjagunjagun rẹ, tí ó wà nínú rẹàti nínú gbogbo ẹgbẹ́ rẹtí ó wà ní àárin rẹyóò rì sínú àárin gbùngbùn òkunní ọjọ́ ìparun rẹ.

28. Ilẹ̀ etí òkun yóò mìnítorí ìró igbe àwọn atọ́kọ̀ rẹ.

29. Gbogbo àwọn alájẹ̀àwọn atukọ̀àti àwọn atọ́kọ̀ ojú òkun;yóò sọ̀ kálẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ wọn,wọn yóò dúró lórí ilẹ̀.

30. Wọn yóò jẹ́ kí a gbọ́ ohùn wọn lòdì sí ọwọn yóò sì sunkún kíkorò lé ọ lóríwọn yóò ku eruku lé orí ara wọnwọn yóò sì yí ara wọn nínú eérú.

31. Wọn yóò fá irun orí wọn nítorí rẹwọn yóò wọ aṣọ yíyawọn yóò pohùnréré ẹkún pẹ̀lúìkoro ọkàn nítorí rẹpẹ̀lú ohùn réré ẹkún kíkorò.

32. Àti nínú arò wọn ni wọn yóò sì pohùn réré ẹkún fún ọwọn yóò sì pohùnréré ẹkún sórí rẹ, wí pé:“Ta ni ó dàbí Tírèèyí tí ó parun ní àárin òkun?”

33. Nígbà tí ọjà títà rẹ ti òkun jáde wáìwọ tẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè lọ́rùnìwọ fi ọrọ̀ tí ó pọ̀ àti àwọn ọjà títà rẹsọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀.

34. Ní ìsinsìn yìí tí òkun fọ ọ túútúúnínú ibú omi;nítorí náà òwò rẹ àti gbogbo ẹgbẹ́ rẹní àárin rẹ,ni yóò ṣubú.

35. Ẹnu yóò ya gbogbo àwọn ti ń gbéní erékùṣù náà sí ọàwọn ọba wọn yóò sì dìjì,ìyọnu yóò sì yọ ní ojú wọn.

36. Àwọn oníṣòwò láàrin àwọn orílẹ̀ èdè dún bí ejò sí ọìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rùìwọ kì yóò sì sí mọ́ láéláé.’ ”