orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìsọtẹ́lẹ̀ Sí Àwọn Òkè Ísírẹ́lì

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé:

2. “Ọmọ ènìyàn, dojú kọ àwọn òkè Ísírẹ́lì; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ lòdì sí wọn

3. wí pé: ‘Ẹ̀yin òkè Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run. Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí sí ẹ̀yin òkè ńlá àti àwọn òkè kékèké sí àwọn odò ṣíṣàn àti sí àfonífojì, n ó mú idà wa sórí yín, n ó sì pa ibi gíga yín run.

4. N ó wó pẹpẹ yín lulẹ̀, n ó sì fọ́ pẹpẹ tùràrí yín túútúú; èmi ó sì pa àwọn ènìyàn yín síwájú àwọn òrìṣà wọn.

5. N ó tẹ́ òkú àwọn ará Ísírẹ́lì síwájú òrìsà wọn n ó sì fọ́n egungun wọn yí pẹpẹ wọn ká.

6. Gbogbo ibi tí ẹ ń gbé àti àwọn ibi gíga yín ni yóò di píparun, gbogbo pẹpẹ yín ni yóò di ahoro, àwọn òrìṣà yín yóò di fífọ́ túútúú, àwọn pẹpẹ tùràrí yín ni a ó gé lulẹ̀, gbogbo iṣẹ́ yín yóò parẹ́.

7. Àwọn ènìyàn yín yóò ṣubú láàrin yín, ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.

8. “ ‘Ṣùgbọ́n n ó dá àwọn kan sí nítorí pé díẹ̀ nínú yín ni yóò bọ́ lọ́wọ́ idà, nígbà tí a bá fọ́n yín ká sí gbogbo ilẹ̀ àti orílẹ̀ èdè.

9. Àwọn ti ó bọ́ nínú yin yóò sì ránti mi láàrin àwọn orílẹ́-èdè níbi tí wọn o dì wọ́n ní ìgbèkùn lọ, nítorí ti mo ti tọ́ ọkàn àgbèrè wọn ti o ti lọ kúrò, lọ́dọ̀ mi àti pẹ̀lú ojú wọn, ti n sàgbérè lọ sọ́dọ̀ òrìsà wọn, wọn o si sú ara wọn nítorí ìwà ibi ti wọn ti hù nínú gbogbo ìríra wọn.

10. Wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa; àti pé kì í ṣe lásán ni mo ń lérí pé n ó mú ìdààmú bá wọn.

11. “ ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí: Pàtẹ́wọ́ kí o tún fẹsẹ̀ janlẹ̀, kí o wá kígbe síta pé, “Ó ṣe!” ilé Ísírẹ́lì yóò ṣubú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn nítorí gbogbo ìwà ìríra búburú tí wọ́n hù. Wọn yóò ṣubú nípa idà àti ìyàn.

12. Ẹni tó wà lókèèrè yóò kú pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn, àti ẹni tó wà nítòsí yóò ṣubú pẹ̀lú idà, ìyàn ni yóò pa ẹni tó bá ṣẹ́kù sílẹ̀. Báyìí ni n ó ṣe mú ìbínú gbígbóná mi wá sórí wọn.

13. Wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, nígbà tí òkú àwọn ènìyàn wọn bá wà níbẹ̀ láàrin òrìṣà wọn yí pẹpẹ wọn ká, lórí àwọn òkè gíga gbogbo, àti lórí góńgó òkè àti lábẹ́ igi tútù àti lábẹ́ igi óákù-níbi tí wọ́n ti ń fi tùràrí dídùn rúbọ̀ sí gbogbo òrìṣà wọn.

14. Èmi yóò na ọwọ́ mi jáde sí wọn láti mú kí ilẹ̀ náà ṣòfò kí ó sì dahoro dé aṣálẹ̀ ìhà Díbílà-ní gbogbo ibùgbé wọn. Nígbà náà ni wọn ó mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”