orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìpohùnréré Ẹkún Fún Fáráò

1. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kejìlá, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

2. “Ọmọ ènìyàn, ṣe ìpohùnréré ẹkún nítorí Fáráò Ọba Éjíbítì kí o sì wí fún un:“ ‘Ìwọ dàbí kìnnìún láàárin àwọnorílẹ̀ èdè náà;ìwọ dàbí ohun abanilẹ́rù inú àwọn okun to ń lọkáàkiri inú àwọn odò rẹ,ìwọ fi ẹsẹ rẹ tẹ omiláti mú kí àwọn odò ní ẹrẹ̀.

3. “ ‘Èyí yìí ńi Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:“ ‘Pẹ̀lu ọ̀pọ̀ ìpéjọ ènìyànÈmi yóò da àwọ̀n mi bò ọ́wọn yóò sì fà ọ́ sókè nínú àwọ̀n mi.

4. Èmi yóò jù ọ́ sí orí ilẹ̀èmi yóò sì fà ọ́ sókè sí orí pápá gbangba.Èmi yóò jẹ́ kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ṣeàtìpó ní orí rẹ.Gbogbo àwọn ẹranko ayé yóò fiìwọra gbé ara wọn mù lórí rẹ.

5. Èmi yóò tan ẹran ara rẹ ká sóríàwọn òkè gígaìyókù ara rẹ ní wọn yóò fi kúnàwọn àárin àwọn òkè gíga

6. Ẹ̀jẹ̀ rẹ ti ń ṣàn ní èmi yóò sì fi rin ilẹ̀ náàgbogbo ọ̀nà sí orí àwọn òkè gíga,àwọn àlàfo jínjìn ní wọn yóò kún fún ẹran ara rẹ.

7. Nígbà tí mo bá fọ́n ọ jáde, èmi yóò pa ọ̀run déàwọn ìràwọ̀ wọn yóò sì ṣókùnkùn;èmi yóò sì fi ìkùukùu bo oòrùnòṣùpá kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀

8. Gbogbo ìmọ́lẹ̀ títàn ní ojú ọ̀runni èmi yóò mú ṣókùnkùn lórí rẹ;èmi yóò mú òkùnkùn wá sórí ilẹ rẹ,ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí

9. Èmi yóò da ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rúnígbà tí mo bá mú ìparun rẹ wání àárin àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọkò í tí ì mọ̀.

10. Èmi yóò mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn dẹ́rù bà ọ́,àwọn Ọba wọn yóò sì wárìrì fúnìbẹ̀rù pẹ̀lú ìpayà nítorí rẹ,nígbà tí mo bá ju idà mi ní iwájú wọnNí ọjọ́ ìṣubú rẹìkọ̀ọ̀kan nínú wọn yóò wárìrìní gbogbo ìgbà fún ẹ̀mí rẹ.

11. “ ‘Nítorí èyí yìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:“ ‘Idà Ọba Bábílónìyóò wá sí orí rẹ,

12. Èmi yóò mú kí ìjọ ènìyàn rẹ kí ótí ipa idà àwọn alàgbà ènìyàn ṣubúàwọn orílẹ̀ èdè aláìláàánú jùlọ.Wọn yóò tú ìgbéraga Éjíbítì ká,gbogbo ìjọ rẹ ní a óò dá ojú wọn bolẹ̀.

13. Gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ ni èmi yóòparun ní ẹgbẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omikì i ṣe ẹsẹ̀ ènìyàn ní yóò tẹ ibẹ̀ẹsẹ̀ ẹran ọ̀sìn kì yóò sì mú kí ibẹ̀ ni arọ̀fọ̀.

14. Lẹ́yìn náà èmi yóò mú kí omi rẹ̀ tòròkí àwọn odò rẹ̀ kí o ṣàn bí epo,ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

15. Nígbà tí mo bá sọ Éjíbítì di ahoro,tí mo sì kó gbogbo ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀ náà kúrò.Nígbà tí mo bá gé àwọn olùgbé ibẹ̀ lulẹ̀,nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’

16. “Èyí yìí ni ẹkún tí a óò sun fún un. Àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀ èdè yóò sun ún; nítorí Éjíbítì àti gbogbo ìjọ rẹ, wọn yóò sun ún, ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”

17. Ní ọjọ́ kẹẹdógún oṣù, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mí wá:

18. “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún ìjọ Éjíbítì kí o sì ránsẹ́ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ àti òun àti àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀ èdè alágbára, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ìsàlẹ̀, kòtò.

19. Sọ fún wọn, ‘Ǹjẹ ìwọ ní ojú rere jù àwọn tí o kù lọ? Lọ sí ìsàlẹ̀ kí a sì tẹ́ ọ sí àárin àwọn aláìkọlà náà.’

20. Wọn yóò ṣubú láàárin àwọn tí a fi idà pa. A fa idà yọ; jẹ́ kí a wọ́ Éjíbítì kúrò pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀.

21. Láti inú isà òkú alágbára tí í ṣe aṣáájú yóò sọ nípa Éjíbítì àti àwọn àlejò rẹ̀, ‘Wọn ti wá sí ìsàlẹ̀, wọn sì sùn pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.’

22. “Ásíríà wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo jagun jagun rẹ̀; àwọn isà òkú àwọn tí a ti pa sì yí i ká, gbogbo àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú.

23. Isà òkú wọn wà ní ibi tí ó jìnlẹ̀ gan an nínú kòtò. Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè ní a pa, tí ó ti ipa idà ṣubú.

24. “Élámù wà níbẹ̀, o yí isà òkú rẹ̀ ká pẹ̀lú gbogbo ijọ rẹ̀. Gbogbo wọn ni a pa, àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú. Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè lọ sí ìsàlẹ̀ láìkọlà sí abẹ́ ilẹ̀. Wọ́n gba ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò.

25. A ṣe ibùsùn fún un láàárin àwọn tí a pa, pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀ tí ó yí isà òkú ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, tí a fi idà pa. Nítorí pé a tan ẹ̀rù wọn ká ilẹ̀ alààyè, wọn ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò; a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a pa.

26. “Méṣékì àti Túbálì wà níbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọ wọn yí isà òkú wọn ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, wọ́n fi idà pa wọ́n nítorí ẹ̀rù ti wọn tàn ká ilẹ̀ alààyè.

27. Ṣé wọn kò sùn pẹ̀lú àwọn ọ̀gágun aláìkọlà tí ó ti ṣubú, tí o lọ sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú ohun ìjà, tí a sì fi idà wọn sí ìgbérí wọn? Ìjìyà fún ẹ̀sẹ̀ wọn sinmi ní orí egungun wọn, ẹ̀rù àwọn ọ̀gágun ti wà káàkiri ilẹ̀ alààyè.

28. “Ìwọ náà, Fáráò, ní yóò ṣẹ, ti yóò dùbúlẹ̀ láàárin aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.

29. “Édómù wà níbẹ̀, àwọn Ọba rẹ̀ àti gbogbo ọmọbìnrin Ọba; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní agbára, a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa. Wọn dùbúlẹ̀ pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn ti o lọ sínú kòtò.

30. “Gbogbo àwọn ọmọ aládé ilẹ̀ àríwá àti gbogbo àwọn ará Sídónì wà níbẹ̀; wọn lọ sí ìsàlẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí a pa ní ìtìjú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ṣe okùnfà ẹ̀rù pẹ̀lú agbára wọn. Wọn sùn ní àìkọlà pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa, wọn sì ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò.

31. “Fáráò, òun àti gbogbo jagunjagun rẹ̀ óò rí wọn, a yóò sì tù ú nínú nítorí gbogbo ìjọ rẹ̀ tí a fi idà pa, ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

32. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè, Fáráò àti gbogbo ìjọ rẹ̀ ni a óò tẹ́ sí àárin aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”