orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àsọtẹ́lẹ̀ Òdì Sí Ọba Tírè

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:

2. “Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tírè pé, ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè simiìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run;Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣàní àárin gbùngbùn òkun.”Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà,bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.

3. Ìwọ gbọ́n ju Dáníẹ́lì lọ bí?Ṣé kò sí àsírí kan tí ó pamọ́ fún ọ?

4. Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹàti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákànínú àwọn ilé ìṣúra rẹ.

5. Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,ọkàn rẹ gbé sókèNitorí ọrọ̀ rẹ.

6. “ ‘Nítorí náà èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n,pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run

7. Èmi yóò mú kí àwọn àjòjì dìde sí ọ,ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀ èdè;wọn yóò yọ idà wọn sí ọẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹwọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́.

8. Wọn yóò mú ọ sọ̀ kalẹ̀ wá sínú ihòìwọ yóò sì kú ikú gbígbónáàwọn tí a pa ní àárin òkun.

9. Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,”ní ojú àwọn tí ó pa ọ́?Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run,ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́

10. Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlàní ọwọ́ àwọn àjòjìÈmi ni ó ti sọ ọ́, ní Olúwa Ọlọ́run wí.’ ”

11. Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:

12. “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tírè kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Ìwọ jẹ́ àpẹrẹ ìjẹ́pípé náào kún fún ọgbọ́n,o sì pé ní ẹwà

13. Ìwọ ti wà ní Édẹ́nì, ọgbà Ọlọ́run;onírúurú òkúta iyebíye ni ìbora rẹ;sárídù, tópásì àti díámọ́ndì, bérílì oníkì,àti jásípérì, sáfírè, émérálídìàti káríbúnkílì, àti wúràìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dàláti ara wúrà,ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn.

14. A fi àmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù,torí èyí ni mo fi yàn ọ́.Ìwọ wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run;ìwọ rìn ni àárin òkúta amúbína,

15. Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹláti ọjọ́ tí a ti dá ọtítí a fi rí àìṣedéédéé ní inú rẹ.

16. Nípa ìtànkálẹ̀ òwò rẹìwọ kún fún ìwà ipá;ìwọ sì dẹ́sẹ̀Nítorí náà ni mo ṣe sọ ọ nùbí ohun àìlọ́wọ̀ kúrò lórí òkè Ọlọ́run.Èmi sì pa ọ run,ìwọ kérúbù, tí ó bọ́ kúrò ní àárin òkúta amúbínà

17. Ọkàn rẹ gbéraganítorí ẹwà rẹ.Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́nítorí dídára rẹ.Nítorí náà mo le ọ sórí ayé;mo sọ ọ di awò ojú níwájú àwọn ọba.

18. Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìsòótọ́ rẹìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́.Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá látiinú rẹ, yóò sì jó ọ run,èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́.

19. Gbogbo orílẹ̀ èdè tí ó mọ̀ ọ́ní ẹnu ń yà sí ọ;ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rùìwọ kì yóò sì sí mọ́ láéláé.’ ”

Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Sídónì

20. Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:

21. “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sídónì; kí o sì ṣọtẹ́lẹ̀ sí i

22. Kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sídónì,a ó sì ṣe mí lógo láàárin rẹ.Wọn yóò, mọ̀ pé èmi ní Olúwa,Nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹtí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ,

23. Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-àrùn sínú rẹèmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ ṣàn ní ìgboro rẹẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárin rẹpẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni Olúwa.

24. “ ‘Kì yóò sì sí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run.

25. “ ‘Èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: Nígbà tí èmi yóò bá ṣa àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jọ kúrò ní gbogbo orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti fọ́nká sí, tí a ó sì yà mí sí mímọ́ láàárin wọn lójú àwọn aláìkọlà; Nígbà náà ni wọn yóò gbé ní ilẹ̀ àwọn tìkalára wọn, èyí tí mo fún ìránṣẹ́ mi Jákọ́bù.

26. Wọn yóò sì máa gbé ní inú rẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì kọ́lé, wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà; nítòótọ́ wọn yóò wà ní ìbàlẹ̀ àyà, nígba tí èmi bá ti mú ìdájọ́ mi sẹ sí ara àwọn tí ń ṣáátá wọn ní gbogbo àyíká wọn; Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.’ ”