orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kìn-ín-ní Dáríúsì ará Médíà, mo dúró láti tìí lẹ́yìn àti láti dáàbò bòó.)

Àwọn Ọba Gúṣù Àti Àríwá

2. “Ní ìsinsìnyí, mo sọ òtítọ́ fún ọ ọba mẹ́ta yóò dìde sí i ní Páṣíà, àti ẹ̀kẹrin tí yóò jẹ́ ọlọ́rọ̀ ju gbogbo wọn lọ. Tí ó bá ti di alágbára nípa ọrọ̀ rẹ̀, yóò sì ru gbogbo wọn sókè lòdì sí ìjọba Gíríkì.

3. Nígbà náà ni ọba alágbára kan yóò fara hàn, yóò ṣe àkóso pẹ̀lú agbára ńlá, yóò sì ṣe bí ó ti wù ú.

4. Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá fi ara hàn tán, ìjọba rẹ̀ yóò fọ́, yóò sì pín sí mẹ́rin ní origun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, ìjọba náà kò sì sọ́wọ́ àwọn ìran rẹ̀ tàbí kí ó ní agbára tí ó ń lò tẹ́lẹ̀, nítorí, a ó fa ìjọba rẹ̀ tu a ó sì fi fún àwọn mìíràn.

5. “Ọba ìhà Gúṣù yóò di alágbára ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn aláṣẹ rẹ̀ yóò di alágbára jùú lọ, yóò sì ṣe àkóso ìjọba rẹ̀ pẹ̀lú agbára ńlá.

6. Lẹ́yìn ọdún púpọ̀ wọn yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà, ọmọbìnrin ọba gúṣù yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ọba àríwá láti bá a dá májẹ̀mú àlàáfíà, ṣùgbọ́n òun kì yóò lè di agbára apá a rẹ̀ mú, bẹ́ẹ̀ ni òun kì yóò lè dá dúró, ṣùgbọ́n a ó tẹrí i rẹ̀ ba àti àwọn tí ó mú un wá, àti ọmọ tí ó bí, àti ẹni tí ó ń mu lọ́kàn le ní gbogbo àkókò wọ̀nyí.

7. “Ọ̀kan lára àwọn ìdílé e rẹ̀, ọmọbìnrin ọba Gúṣù yóò dìde láti gba ipò o rẹ̀. Yóò sì kọ lu ogun ọba àríwá, yóò sì wọ́ odi alágbára; yóò bá wọn jà yóò sì borí.

8. Yóò gba òrìṣà wọn, ère dídá àti ohun èlò oníye lórí ti fàdákà àti ti wúrà, yóò sì kó wọn lọ sí Éjíbítì. Fún ọdún díẹ̀ yóò fi ọba àríwá lọ́rùn sílẹ̀.

9. Nigbà náà, ni ọba àríwá yóò gbógun ti ilẹ̀ ọba, Gúṣù, ṣùgbọ́n yóò padà sí orílẹ̀ èdè Òun fúnra rẹ̀

10. Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò múra ogun wọn yóò kó ogun ńlá jọ, èyí tí a ó gbá lọ bí àgbàrá omi ńlá, yóò sì gbá a lọ títí dé ìlú olódi rẹ̀.

11. “Nígbà náà ni ọba Gúṣù yóò jáde pẹ̀lú ìbínú, yóò sì bá ọba àríwá jà, ẹni tí yóò kó ọmọ ogun púpọ̀ jọ, ṣùgbọ́n ọba Gúṣù yóò borí i wọn.

12. Nígbà tí a bá kó ogun náà lọ, ọba Gúṣù yóò kún fún agbára, yóò sì pa ẹgbẹgbẹ̀rún ní ìpakúpa ṣíbẹ̀ kì yóò ṣẹ́gun.

13. Nítorí ọba àríwá yóò lọ kó ogun mìíràn jọ, tí ó pọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, yóò jáde pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun tí ó ti dira ogun fún dáradára.

14. “Ní àkókò ìgbà náà, ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò dìde sí ọba Gúṣù. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò ṣọ̀tẹ̀ ní ìmúṣẹ ìran náà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí.

15. Nígbà náà ni ọba àríwá yóò wá yóò sì gbé ogun tìí, yóò sì kó ìlú olódi. Ogun ọba Gúṣù kò ní ní agbára láti kọjú ìjà sí i; Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọ̀wọ́ ogun tó dára jù kò ní ní agbára láti dúró.

16. Ẹni tí ó gbógun tìí yóò máa ṣe bí ó ti wù ú, kò sì sí ẹni tí yóò le è dojú kọ ọ́. Yóò sì fún ara rẹ̀ ní ibùjókòó ní ilẹ̀ tí ó dára, yóò sì ní agbára láti bàá jẹ́.

17. Yóò pinnu láti wá pẹ̀lú agbára ìjọba rẹ̀, yóò sì ní májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú ọba Gúṣù yóò sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ fún-un láti fẹ́ ẹ ní ìyàwó nítorí kí ó lè gba ìjọba, ṣùgbọ́n ète rẹ̀ yìí kì yóò ṣiṣẹ tàbí se ìrànlọ́wọ́ fún-un.

18. Nígbà náà ni yóò yí ara padà sí ilẹ̀ etí òkun, yóò mú ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n aláṣẹ kan yóò mú òpin bá àfojúdi rẹ̀, yóò sì yí àfojúdi rẹ̀ padà sí orí i rẹ̀.

19. Lẹ́yìn èyí, yóò sì yí padà sí ìlú olódi ti orílẹ̀-èdè òun fún ra rẹ̀, ṣùgbọ́n yóò kọsẹ̀ yóò sì burú, a kì yóò sì ríi mọ́.

20. “Arọ́pò rẹ̀ yóò rán agbowó orí kan jáde láti fi ìdí ipò ọlá ọba múlẹ̀ ṣùgbọ́n ní ìwọ̀n ọdún díẹ̀, a ó pa á run, kì yóò jẹ́ nípa ìbínú tàbí nínú ogun.

21. “Ẹni tí kò níláárí kan yóò rọ́pò rẹ̀, ẹni tí a kò tí ì fi ọlá ọba fún rí. Yóò sì gbógun sí ìjọba nígbà tí ọkàn àwọn ènìyàn balẹ̀ láìbẹ̀rù, yóò sì gbà á pẹ̀lú àrékérekè.

22. Nígbà náà, ni a ó gbà ogunlọ́gọ̀ ogun kúrò níwájú u rẹ̀, pẹ̀lú òun àti ọmọ aládé ti májẹ̀mu náà ni a ó parun.

23. Lẹ́yìn tí ó wá ṣe ìpinnu pẹ̀lú u rẹ̀, yóò hùwà ẹ̀tàn, pẹ̀lú iwọ̀nba ènìyàn kékeré ni yóò gba ìjọba.

24. Nígbà tí àwọn agbègbè tí ó lọ́rọ̀ gidigidi wà láìbẹ̀rù ni yóò gbógun tì wọ́n, yóò ṣe ohun tí baba rẹ̀ tàbí baba ńlá rẹ̀ kò ṣe rí, yóò pín ìkógún ẹrù àti ọrọ̀ fún àwọn ọmọ lẹ́yìn in rẹ̀. Yóò pète àti bi àwọn ìlú olódi ṣubú, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀ ni.

25. “Pẹ̀lú ogun púpọ̀, yóò sì ru agbára rẹ̀ àti ìgboyà rẹ̀ ṣókè sí ọba Gúṣù. Ọba Gúṣù yóò dìde ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun tí ó lágbára gidigidi, ṣùgbọ́n kò ní leè dúró, nítorí ọ̀tẹ̀ tí ó gbérò sí i.

26. Àwọn tí ó jẹ nínú oúnjẹ ọba yóò gbìyànjú láti parun: a ó gbá ogun rẹ̀ dànú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò ṣubú sí ogun.

27. Àwọn ọba méjèèjì, ọkàn wọn tẹ̀ sí búburú, wọn yóò jókòó lórí tábìlì kan, wọn yóò máa parọ́ sí ara wọn, ṣùgbọ́n kò ní yọrí sí nǹkan kan nítorí òpin yóò wá ní àsìkò tí a yàn.

28. Ọba àríwá yóò padà sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ yóò lòdì sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì ṣiṣẹ́ lòdì sí i, yóò sì padà sí orílẹ̀-èdè oun fúnra rẹ̀.

29. “Ní àsìkò tí a yàn, yóò gbógun sí Gúṣù lẹ́ẹ̀ kan sí i, ṣùgbọ́n ní ìgbà yí àyọrísí yóò yàtọ̀ sí ti ìṣáájú.

30. Nítorí pé, ọkọ̀ ojú omi àwọn ilẹ̀ etídò ìwọ̀-oòrùn yóò ta kòó, ọkàn rẹ̀ yóò sì pámi. Nígbà náà, ni yóò padà, yóò sì bínú sí májẹ̀mu mímọ́, yóò sì padà, yóò sì fi ojú rere hàn sí àwọn tí ó kọ májẹ̀mu mímọ́ náà.

31. “Agbára ọmọ ogun rẹ̀ yóò dìde láti ba ohun mímọ́ ilé olódi tẹ́ḿpìlì jẹ́, yóò sì pa ẹbọ ojoojúmọ́ rẹ́. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ìríra tí ó fa ìsọdahoro kalẹ̀.

32. Pẹ̀lú ẹ̀tàn ni yóò bá àwọn tí ó ba májẹ̀mú jẹ́, ṣùgbọ́n, àwọn tí ó mọ Ọlọ́run wọn yóò jẹ́ alágbára. Wọn yóò sì kọjú ìjà sí i.

33. “Àwọn tí ó mòye yóò máa kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀, wọn yóò máa ṣubú nípa idà tàbí kí a jó wọn tàbí ìgbèkùn tàbí nípa ìkógún.

34. Nígbà tí wọ́n bá ṣubú, wọn yóò rí ìrànlọ́wọ́ díẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣe aláìsòótọ́ yóò sì dara pọ̀ mọ́ wọn.

35. Lára àwọn tí ó mòye yóò kọsẹ̀, nítorí kí a baà tún wọn ṣe, wọ́n di mímọ́ àti aláìlábàwọ́n títí di ìgbà ìkẹyìn nítorí yóò sì wá ní àkókò tí a yàn.

Ọba tí ó gbé ara rẹ̀ ga

36. “Ọba yóò ṣe bí ó ti wù ú yóò sì gbé ara rẹ̀ ga, ju gbogbo òrìṣà lọ, yóò máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò-ṣe-é-gbọ́-létí sí Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run, a yóò sì máa yege títí àkókò ìbínú yóò fi parí, nítorí ohun tí a ti pinnu yóò ṣẹlẹ̀.

37. Òun kò ní ka òrìṣà àwọn baba rẹ̀ sí tàbí èyí tí àwọn fẹ́, òun kò ní ka ìkankan sí, ṣùgbọ́n yóò gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo wọn lọ.

38. Ṣùgbọ́n dípò wọn, yóò bu ọlá fún òrìṣà àwọn ìlú olódi: òrìṣà tí àwọn baba rẹ̀ kò mọ̀ ni yóò bu ọlá fún pẹ̀lú wúrà àti fàdákà, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti ẹ̀bùn tí ó lówó lórí.

39. Yóò kọ lu àwọn ìlú olódi tí ó lágbára pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ òrìṣà àjèjì, yóò sì bu ọlá ńlá fún ẹni tí ó jẹ́wọ́ rẹ̀. Yóò mú wọn ṣe alákòóso lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí èrè.

40. “Ní ìgbà ìkẹyìn, ọba Gúṣù yóò gbé ogun de sí i, ọba àríwá yóò sì jáde bí ìjì láti kọ lù ú pẹ̀lú u kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹlẹ́ṣin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ ojú omi. Yóò gbógun wọ orílẹ̀ èdè púpọ̀, yóò sì gbá wọn mọ́lẹ̀ bí ìkún omi.

41. Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì tún gbógun ti ilẹ̀ ológo náà pẹ̀lú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè yóò ṣubú, ṣùgbọ́n Édómù, Móábù àti àwọn olórí Ámónì yóò bọ́ lọ́wọ́ ọ rẹ̀.

42. Yóò lo agbára rẹ̀ lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè; Éjíbítì kì yóò là.

43. Yóò gba àkóso ìṣúra wúrà àti fàdákà àti gbogbo orò Éjíbítì, pẹ̀lú ti Líbíyà àti Núbíà nígbà tí ó mú wọn tẹríba.

44. Ṣùgbọ́n ìròyìn láti ìlà oòrùn àti láti ìwọ̀ oòrùn yóò mú ìdáríjì bá a, yóò sì fi ìbínú ńlá jáde lọ láti parun, àti láti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ run pátapáta.

45. Yóò sì pàgọ́ ọ rẹ̀ láàrin òkun kọjú sí àárin òkè mímọ́ ológo Síbẹ̀ yóò wá sí òpin rẹ̀, ẹnìkan kò ní ràn-án lọ́wọ́.