orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Dáníẹ́lì Lá Àlá Ẹranko Mẹ́rin

1. Ní ọdún àkọ́kọ́ Beliṣáṣárì ọba Bábílónì, Dáníẹ́lì lá àlá kan, ìran náà sì wá sí ọkàn an rẹ̀ bí ó ṣe ṣùn sórí ibùṣùn un rẹ̀, ó sì kọ àlá náà sílẹ̀.

2. Dáníẹ́lì sọ pé, “Nínú ìran mi lóru mo wò ó, mo sì rí afẹ́fẹ́ ọ̀run mẹ́rin tí ó ń ru omi òkun ńlá sókè.

3. Ẹranko ńlá mẹ́rin tí ó yàtọ̀ sí ara wọn, jáde láti inú òkun náà.

4. “Ẹranko kìn-ín-ní dàbí i kìnnìún, ó sì ní ìyẹ́-apá a idì: mo sì wò títí a fi fa ìyẹ́-apá rẹ̀ naa tu, a sì gbé e sókè kúrò ní ilẹ̀, a mú kí ó fi ẹsẹ̀ dúró bí ènìyàn, a sì fi àyà ènìyàn fún un.

5. “Mo sì tún rí ẹranko kejì, ó rí bí irú ẹranko ńlá kan tí ó ń gbé ilẹ̀ òtútù; bíárì. Ó gbé ara sókè ní apá kan, ó sì ní egungun ìhà mẹ́ta láàrin ẹ̀yìn in rẹ̀, wọ́n sì sọ fún un pé, ‘Dìde kí o sì jẹ ẹran tó pọ̀!’

6. “Lẹ́yìn ìgbà náà, mo tún rí ẹranko kẹta ó rí bí àmọ̀tẹ́kùn. Ẹranko náà ní ìyẹ́ bí i ti ẹyẹ ní ẹ̀yìn, ó sì ní orí mẹ́rin, a sì fún un ní agbára láti ṣe ìjọba.

7. “Lẹ́yìn èyí, nínú ìran mi lóru mo tún rí ẹranko kẹrin, ó dẹ́rù ba ni, ó dáyà fo ni, ó sì lágbára gidigidi. Ó ní eyín irin títóbi; ó ń rùn, ó sì ń pa ohun alààyè tí ó ṣẹ́ kù jẹ, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tó kù mọ́lẹ̀. Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko ti ìṣáájú, ó sì ní ìwo mẹ́wàá.

8. “Bí mo ṣe ń ronú nípa ìwo náà, nígbà náà ni mo rí ìwo mìíràn, tí ó kéré tí ó jáde wá ní àárin wọn; mẹ́ta lára àwọn ìwo ti àkọ́kọ́ sì fà tu níwájú u rẹ̀. Ìwo yìí ní ojú bí i ojú ènìyàn àti ẹnu tí ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga.

Ìdájọ́ Níwájú Ẹni Ìgbàanì

9. “Bí mo ṣe ń wò,“a gbé ìtẹ́ ọba sí ìkàlẹ̀ẹni ìgbàanì orí ìtẹ́ rẹ̀Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwúIrun orí i rẹ̀ funfun bí òwúÌtẹ́ ọba rẹ̀ rí bí ọwọ́ iná.Àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ ń jó bí i iná.

10. Odò iná ń ṣànó ń jáde ní iwájú u rẹ̀Àwọn ẹgbẹ̀rún lọ́ná ẹgbẹ̀rún ń foríbalẹ̀ fún un;Ọ̀nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rúnmẹ́wàá sì dúró níwájú u rẹ̀.Àwọn onídàájọ́ jókòóa sì sí àwọn ìwé sílẹ̀.

11. “Nígbà náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ní wò, nítorí àwọn ọ̀rọ̀ ìgbéraga tí ìwo náà ń sọ, mo wò títí a fi pa ẹranko náà, a sì pa á run, a sì jù ú sínú iná tí ń jó.

12. A sì gba ìjọba lọ́wọ́ àwọn ẹranko yóòkù, ṣùgbọ́n a fún wọn láàyè láti wà fún ìgbà díẹ̀.

13. “Nínú ìran mi ní òru mo wò, mo rí ẹnìkan tí ó dúró sí iwájú u mi, ó rí bí ọmọ ènìyàn, ó ń bọ̀ wá nínú àwọ̀ọsánmọ̀ ọ̀run, ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ ẹni ìgbàanì, a sì mú u wá sí iwájú rẹ̀.

14. A sì fi ìjọba, ògo àti agbára ilẹ̀ ọba fún un; gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ èdè àti èdè gbogbo wọn wólẹ̀ fún un. Ìjọba rẹ̀, ìjọba ayérayé ni, èyí tí kò le è kọjá, ìjọba rẹ̀ kò sì le è díbàjẹ́ láéláé.

15. “Ọkàn èmi Dáníẹ́lì, dàrú, ìran tí ó wá sọ́kàn mi dẹ́rù bà mí.

16. Mo lọ bá ọ̀kan nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀, mo sì bi í léèrè òtítọ́ ìtúmọ̀ nǹkan wọ̀nyí.“Ó sọ fún mi, ó sì túmọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún mi:

17. ‘Àwọn ẹranko ńlá mẹ́rin yìí, ni ìjọba mẹ́rin tí yóò dìde ní ayé.

18. Ṣùgbọ́n, ẹni mímọ́ ti ọ̀gá ògo ni yóò gba ìjọba náà, yóò sì jogún un rẹ títí láé àti títí láéláé.’

19. “Nígbà náà, ni mo fẹ́ mọ ìtúmọ̀ òtítọ̀ ẹranko kẹrin, tí ó yàtọ̀ sí àwọn yóòkù, èyí tí ó dẹ́rù ba ni gidigidi, tí ó ní eyín irin àti èékánná idẹ, ẹranko tí ó ń run tí ó sì ń pajẹ, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tó kù mọ́lẹ̀.

20. Bẹ́ẹ̀ ni mo sì fẹ́ mọ̀ nípa ìwo mẹ́wàá orí i rẹ̀ àti nípa ìwo yóòkù tí ó jáde, nínú èyí tí mẹ́ta lára wọn ṣubú, ìwo tí ó ní ojú, tí ẹnu rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ìgbératga.

21. Bí mo ṣe ń wò, ìwo yìí ń bá àwọn ènìyàn mímọ́ jagun, ó sì borí i wọn,

22. títí ẹni ìgbàanì fi dé, ó sì ṣe ìdájọ́ ìdáláre fún àwọn ẹni mímọ́ ọ̀gá ògo, àsìkò náà sì dé nígbà tí àwọn ẹni mímọ́ náà jogun ìjọba.

23. “Ó ṣe àlàyé yìí fún mi pé: ‘Ẹranko kẹrin ni ìjọba kẹrin tí yóò wà ní ayé. Yóò yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ìjọba yóòkù yóò sì pa gbogbo ayé run, yóò tẹ̀ẹ́ mọ́lẹ̀, yóò sì fọ́ ọ́ sí wẹ́wẹ́.

24. Ìwo mẹ́wàá ni ọba mẹ́wàá tí yóò wá láti inú ìjọba yìí. Lẹ́yìn tí wọn ní ọba mìíràn yóò díde, ti yóò yàtọ̀ sí tí àwọn ti ìṣáájú, yóò sì borí ọba mẹ́ta.

25. Yóò sọ̀rọ̀ odi sí ọ̀gá ògo, yóò sì pọ́n ẹni mímọ́ lójú, yóò sì gbèrò láti yí ìgbà àti òfin padà. A ó fi àwọn ẹni mímọ́ lé e lọ́wọ́ fún ìgbà díẹ̀, ní ọdún méjì àti ààbọ̀.

26. “ ‘Ṣùgbọ́n àwọn onídàájọ́ yóò jókòó, nígbà náà ni a ó gba agbára rẹ̀, a ó sì pa á rùn pátapáta títí ayé.

27. Nígbà náà, ni a ó gba ìjọba, agbára àti títóbi ìjọba rẹ̀ ní abẹ́ gbogbo ọ̀run, a ó sì fi fún àwọn ẹni mímọ́, àwọn ènìyàn ọ̀gá ògo. Ìjọba rẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba títí ayé, gbogbo aláṣẹ ni yóò máa ṣe ìgbọràn sí i, wọn yóò sì máa sìn ín.’

28. “Báyìí ni àlá náà ṣe parí, ọkàn èmi Dáníẹ́lì sì dàrú gidigidi, nítorí èrò ọkàn mi yìí, ojú mi sì yípadà ṣùgbọ́n mo pa ọ̀ràn náà mọ́ ní ọkàn mi.”